Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 2:4-16 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ọba bá bèèrè lọ́wọ́ mi pé, “Kí ni ohun tí o wá fẹ́?”Nítorí náà, mo gbadura sí Ọlọrun ọ̀run.

5. Mo bá sọ fún ọba pé, “Bí ó bá tẹ́ kabiyesi lọ́rùn, tí èmi iranṣẹ rẹ bá sì rí ojurere rẹ, rán mi lọ sí Juda, ní ìlú tí ibojì àwọn baba mi wà, kí n lọ tún ìlú náà kọ́.”

6. Ayaba wà ní ìjókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọba, ọba bá bèèrè lọ́wọ́ mi pé, “O óo lò tó ọjọ́ mélòó lọ́hùn-ún? Ìgbà wo ni o sì fẹ́ pada?” Inú ọba dùn láti rán mi lọ, èmi náà sì dá ìgbà fún un.

7. Mo fún ọba lésì pé, “Bí ó bá tẹ́ kabiyesi lọ́rùn bẹ́ẹ̀, kí kabiyesi kọ̀wé lé mi lọ́wọ́ kí n lọ fún àwọn gomina ìgbèríko òdìkejì odò, kí wọ́n lè jẹ́ kí n rékọjá lọ sí Juda,

8. kí ó kọ ìwé sí Asafu, olùṣọ́ igbó ọba, kí ó fún mi ní igi kí n fi ṣe odi ẹnu ọ̀nà tẹmpili, ati ti odi ìlú, ati èyí tí n óo fi kọ́ ilé tí n óo máa gbé.” Ọba ṣe gbogbo ohun tí mo bèèrè fún mi, nítorí pé Ọlọrun lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ mi.

9. Mo bá tọ àwọn gomina ìgbèríko òdìkejì odò lọ mo fún wọn ní lẹta tí ọba kọ. Ọba rán àwọn olórí ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin tẹ̀lé mi.

10. Ṣugbọn nígbà tí Sanbalati ará Horoni ati Tobaya iranṣẹ ọba, ará Amoni gbọ́, inú bí wọn pé ẹnìkan lè máa wá alaafia àwọn ọmọ Israẹli.

11. Mo bá wá sí Jerusalẹmu mo sì wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹta.

12. Mo gbéra ní alẹ́ èmi ati àwọn eniyan díẹ̀, ṣugbọn n kò sọ ohun tí Ọlọrun mi fi sí mi lọ́kàn láti ṣe ní Jerusalẹmu fún ẹnikẹ́ni. Kò sí ẹranko kankan pẹlu mi àfi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí mo gùn.

13. Mo gbéra lóru, mo gba Ẹnubodè Àfonífojì. Mo jáde sí kànga Diragoni, mo gba ibẹ̀ lọ sí Ẹnubodè Ààtàn. Bí mo ti ń lọ, mò ń wo àwọn ògiri Jerusalẹmu tí wọ́n ti wó lulẹ̀ ati àwọn ẹnu ọ̀nà tí wọ́n ti jó níná.

14. Lẹ́yìn náà, mo lọ sí Ẹnubodè Orísun ati ibi Adágún ọba, ṣugbọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí mo gùn kò rí ọ̀nà kọjá.

15. Lóru náà ni mo gba àfonífojì Kidironi gòkè lọ, mo sì ṣe àyẹ̀wò odi náà yíká, lẹ́yìn náà, mo pẹ̀yìndà mo sì gba Ẹnubodè Àfonífojì wọlé pada.

16. Àwọn ìjòyè náà kò sì mọ ibi tí mo lọ tabi ohun tí mo lọ ṣe, n kò sì tíì sọ nǹkankan fún àwọn Juu, ẹlẹgbẹ́ mi: àwọn alufaa, ati àwọn ọlọ́lá, tabi àwọn ìjòyè ati àwọn yòókù tí wọn yóo jọ ṣe iṣẹ́ náà.

Ka pipe ipin Nehemaya 2