Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 6:26-41 BIBELI MIMỌ (BM)

26. “Nígbà tí òjò bá kọ̀ tí kò rọ̀, nítorí pé àwọn eniyan rẹ ṣẹ̀, bí wọ́n bá kọjú sí ilé yìí, tí wọ́n sì gbadura, tí wọ́n jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí pé o ti jẹ wọ́n níyà,

27. jọ̀wọ́, gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì dáríjì àwọn eniyan Israẹli, àwọn iranṣẹ rẹ. Tọ́ wọn sí ọ̀nà tí wọn yóo máa tọ̀, kí o sì jẹ́ kí òjò rọ̀ sí ilẹ̀ tí o fún àwọn eniyan rẹ gẹ́gẹ́ bí ìní wọn.

28. “Nígbàkúùgbà tí ìyàn bá mú ní ilẹ̀ yìí, tabi tí àjàkálẹ̀ àrùn bá bẹ́ sílẹ̀, tabi ọ̀gbẹlẹ̀, tabi ìrẹ̀dànù ohun ọ̀gbìn, tabi eṣú, tabi kòkòrò tíí máa jẹ ohun ọ̀gbìn; tabi tí àwọn ọ̀tá bá gbógun ti èyíkéyìí ninu àwọn ìlú wọn, irú ìyọnu tabi àìsàn yòówù tí ó lè jẹ́,

29. gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan, tabi ti gbogbo Israẹli, eniyan rẹ, lẹ́yìn tí olukuluku ti mọ ìṣòro ati ìbànújẹ́ rẹ̀, bí wọ́n bá gbé ọwọ́ adura wọn sókè sí ìhà ilé yìí,

30. jọ̀wọ́, gbọ́ láti ilé rẹ ní ọ̀run, dáríjì wọ́n, kí o sì ṣe ẹ̀tọ́ fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ̀, nítorí ìwọ nìkan ni o mọ ọkàn ọmọ eniyan.

31. Kí àwọn eniyan rẹ lè máa bẹ̀rù rẹ, kí wọ́n sì máa rìn ní ọ̀nà rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn lórí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba wa.

32. “Bákan náà, nígbà tí àwọn àjèjì, tí kì í ṣe ara àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, bá ti ọ̀nà jíjìn wá, láti gbadura sí ìhà ilé yìí, nítorí orúkọ ńlá rẹ, ati iṣẹ́ ńlá, ati agbára rẹ,

33. gbọ́ láti ibùgbé rẹ lọ́run; kí o sì ṣe gbogbo ohun tí àjèjì náà bá ń tọrọ lọ́dọ̀ rẹ, kí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà láyé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọ́n sì máa bẹ̀rù rẹ, bí àwọn eniyan rẹ tí ń ṣe, kí wọ́n lè mọ̀ pé ilé ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ, ni ilé tí mo kọ́ yìí.

34. “Nígbà tí àwọn eniyan rẹ bá lọ sójú ogun, níbikíbi tí o bá rán wọn, láti lọ bá àwọn ọ̀tá wọn jà, tí wọ́n bá kọjú sí ìhà ìlú tí o ti yàn yìí ati sí ìhà ilé tí mo kọ́ fún ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ yìí,

35. gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run, kí o sì jà fún wọn.

36. “Bí wọ́n bá ṣẹ̀ ọ́ (nítorí pé kò sí ẹni tí kì í ṣẹ̀), tí inú bá bí ọ sí wọn, tí o sì mú kí àwọn ọ̀tá wọn ṣẹgun wọn, tí wọ́n sì kó wọn lẹ́rú lọ sí ọ̀nà jíjìn tabi nítòsí,

37. sibẹ, tí wọ́n bá ranti, tí wọ́n sì ronupiwada ní ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ, tí wọ́n bá bẹ̀bẹ̀ tí wọ́n sọ pé, ‘àwọn ti ṣẹ̀, àwọn ti hu ìwà tí kò tọ́, àwọn sì ti ṣe burúkú,’

38. tí wọ́n bá ronupiwada tọkàntọkàn ninu ìgbèkùn níbi tí a kó wọn lẹ́rú lọ, tí wọ́n gbadura sí ìhà ilẹ̀ tí o fún àwọn baba wọn, ati sí ìlú tí o ti yàn, ati sí ilé tí mo kọ́ fún ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ,

39. gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn láti ibùgbé rẹ lọ́run, jà fún àwọn eniyan rẹ, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n bá ṣẹ̀ ọ́ jì wọ́n.

40. “Nisinsinyii, Ọlọrun mi, bojúwò wá kí o sì tẹ́tí sí adura tí wọ́n bá gbà níhìn-ín.

41. Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun, dìde, lọ sí ibùjókòó rẹ, ìwọ ati àpótí ẹ̀rí agbára rẹ. Gbé ìgbàlà rẹ wọ àwọn alufaa rẹ bí ẹ̀wù, kí o sì jẹ́ kí àwọn eniyan mímọ́ rẹ yọ̀ ninu ire rẹ.

Ka pipe ipin Kronika Keji 6