orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 32 BIBELI MIMỌ (BM)

Ọ̀rọ̀ Elihu

1. Àwọn ọkunrin mẹtẹẹta náà kò dá Jobu lóhùn mọ́, nítorí pé ó jẹ́ olódodo lójú ara rẹ̀.

2. Elihu, ọmọ Barakeli, ará Busi, ní ìdílé Ramu bá bínú sí Jobu, nítorí pé ó dá ara rẹ̀ láre dípò Ọlọrun.

3. Ó bínú sí àwọn ọ̀rẹ́ Jobu mẹtẹẹta pẹlu, nítorí pé wọn kò mọ èsì tí wọ́n lè fún Jobu mọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n dá a lẹ́bi.

4. Elihu ti fẹ́ bá Jobu sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣugbọn ó dákẹ́, nítorí àwọn àgbà tí wọ́n jù ú lọ ni wọ́n ń sọ̀rọ̀.

5. Ṣugbọn nígbà tí Elihu rí i pé àwọn mẹtẹẹta kò lè fún Jobu lésì mọ́, inú bí i.

6. Ó ní,“Àgbàlagbà ni yín, ọmọde sì ni mí,nítorí náà ni ojú fi ń tì mí,tí ẹ̀rù sì ń bà mí láti sọ èrò ọkàn mi.

7. Mo ní kí ẹ̀yin àgbà sọ̀rọ̀,kí ọ̀rọ̀ yín sì fa ọgbọ́n yọ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí yín.

8. Ṣugbọn ẹ̀mí tí ó wà ninu eniyan,tíí ṣe èémí Olodumare,ni ó ń fún eniyan ní ìmọ̀.

9. Kì í ṣe àwọn àgbà nìkan ni wọ́n gbọ́n,tabi pé arúgbó nìkan ni ó mọ òye ohun tó tọ́, tó yẹ.

10. Nítorí náà, ‘Ẹ fetí sílẹ̀,kí èmi náà lè sọ èrò ọkàn mi.’

11. “Mo farabalẹ̀ nígbà tí ẹ̀yin ń sọ̀rọ̀,mo fetí sí ọ̀rọ̀ ọgbọ́n yín,nígbà tí ẹ̀ ń ronú ohun tí ẹ fẹ́ sọ,

12. Mo farabalẹ̀ fun yín,ṣugbọn kò sí ẹnikẹ́ni ninu yín tí ó lè ko Jobu lójú,kí ó sì fi àṣìṣe rẹ̀ hàn án,tabi kí ó fún un lésì àwọn àwíjàre rẹ̀.

13. Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má baà wí pé, ‘A ti di ọlọ́gbọ́n,Ọlọrun ló lè ṣe ìdájọ́ rẹ̀, kì í ṣe eniyan.’

14. Èmi kọ́ ni Jobu ń bá wí, ẹ̀yin ni,n kò sì ní dá a lóhùn bí ẹ ṣe dá a lóhùn.

15. “Ọkàn wọn dàrú, wọn kò sì lè fèsì mọ́,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ohun kan láti sọ.

16. Ṣé kí n dúró,nítorí pé wọ́n dúró láìfèsì?

17. Èmi náà óo fèsì lé e,n óo sì sọ èrò ọkàn tèmi.

18. Mo ní ọ̀rọ̀ pupọ láti sọ,Ṣugbọn ẹ̀mí tí ó wà ninu mi ló ń kó mi ní ìjánu.

19. Ọ̀rọ̀ kún inú mi bí ọtí inú ìgò,ó fẹ́ ru síta bí ọtí inú ìgò aláwọ.

20. Mo níláti sọ̀rọ̀ kí ara lè rọ̀ mí,mo gbọdọ̀ la ẹnu mi kí n sì dáhùn.

21. N kò ní ṣe ojuṣaaju ẹnikẹ́ni,bẹ́ẹ̀ ni n kò sì ní gbèjà eniyan.

22. Nítorí n kò mọ bí wọ́n ṣe ń pọ́n eniyan,kí Ẹlẹ́dàá mi má baà pa mí run ní kíá.