Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 33:2-13 BIBELI MIMỌ (BM)

2. OLUWA wá láti orí òkè Sinai,ó yọ gẹ́gẹ́ bí oòrùn láti Edomu,ó ràn sórí àwọn eniyan rẹ̀ láti òkè Parani.Ó wá láti ọ̀dọ̀ ẹgbaarun àwọn ẹni mímọ́,ó gbé iná tí ń jò lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀.

3. Ọlọrun fẹ́ràn àwọn eniyan rẹ̀,gbogbo àwọn tí a yà sọ́tọ̀ fún un wà lọ́wọ́ rẹ̀,nítorí náà ni wọ́n ṣe ń tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀,tí wọ́n sì ń gba àṣẹ lọ́dọ̀ rẹ̀,

4. nígbà tí Mose bá fún wa ní òfin,tí ó jẹ́ ohun ìní gbogbo eniyan Israẹli.

5. Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe di ọba ní Jeṣuruni,nígbà tí gbogbo àwọn olórí péjọ,àní, gbogbo àwọn olórí ninu ẹ̀yà Israẹli.

6. Mose súre fún ẹ̀yà Reubẹni, ó ní:“Ẹ̀yà Reubẹni yóo máa wà ni, kò ní parun,àwọn eniyan rẹ̀ kò ní dínkù.”

7. Ó súre fún ẹ̀yà Juda pé:“OLUWA, gbọ́ igbe ẹ̀yà Juda,nígbà tí wọ́n bá pè fún ìrànwọ́,sì kó wọn pada sọ́dọ̀ àwọn eniyan wọn.Fi ọwọ́ ara rẹ jà fún wọn,sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí àwọn ọ̀tá wọn.”

8. Ó súre fún ẹ̀yà Lefi pé:“OLUWA, fún Lefi, ẹni tíí ṣe olódodo, ní Tumimu ati Urimu rẹ;Lefi, tí o dánwò ní Masa,tí o sì bá jà níbi odò tí ó wà ní Meriba;

9. àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn kò ka òbí àwọn sí, ju ìwọ OLUWA lọ;wọ́n kọ àwọn arakunrin wọn sílẹ̀,wọ́n sì ṣá àwọn ọmọ wọn tì.Nítorí pé wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ,wọ́n sì ń pa majẹmu rẹ mọ́.

10. Wọn óo kọ́ ilé Jakọbu ní ìlànà rẹ,wọn óo sì kọ́ àwọn ọmọ Israẹli ní òfin rẹ.Àwọn ni wọn óo máa sun turari níbi ẹbọ rẹ,wọn óo sì máa rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ rẹ.

11. OLUWA, bukun àwọn ohun ìní wọn,sì jẹ́ kí iṣẹ́ ọwọ́ wọn jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lójú rẹ,Fọ́ egungun itan àwọn ọ̀tá wọn,tẹ̀ wọ́n ní àtẹ̀rẹ́,kí àwọn tí wọ́n bá kórìíra wọn má sì lè gbérí mọ́.”

12. Ó súre fún ẹ̀yà Bẹnjamini pé:“Bẹnjamini, ẹ̀yà tí OLUWA fẹ́ràn tí ó sì ń dáàbò bò,OLUWA ń ṣọ́ wọn nígbà gbogbo,ó sì ń gbé ààrin wọn.”

13. Ó súre fún ẹ̀yà Josẹfu pé:“Kí OLUWA rọ òjò ibukun sórí ilẹ̀ wọn,kí ó sì bu omi rin ín láti abẹ́ ilẹ̀ wá.

Ka pipe ipin Diutaronomi 33