Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 3:8-20 BIBELI MIMỌ (BM)

8. “A gba ilẹ̀ náà lọ́wọ́ àwọn ọba Amori mejeeji tí wọ́n wà ní òkè odò Jọdani nígbà náà. Ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti àfonífojì Anoni títí dé òkè Herimoni.

9. (Herimoni Sirioni ni àwọn ará Sidoni ń pe òkè náà, ṣugbọn àwọn ará Amori ń pè é ní Seniri.)

10. A sì tún gba gbogbo àwọn ìlú wọn tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, gbogbo ilẹ̀ Gileadi ati gbogbo ilẹ̀ Baṣani títí dé Saleka ati Edirei, àwọn ìlú tí ó wà ninu ìjọba Ogu, ọba Baṣani.”

11. (Nítorí pé, Ogu, ọba Baṣani nìkan ni ó kù ninu ìran àwọn Refaimu. Irin ni wọ́n fi ṣe pósí rẹ̀, ó sì wà ní Raba, ní ilẹ̀ àwọn Amoni títí di òní olónìí. Igbọnwọ mẹsan-an ni gígùn pósí náà, ó sì fẹ̀ ní igbọnwọ mẹrin. Igbọnwọ tí ó péye ni wọ́n fi ṣe ìdíwọ̀n pósí náà.)

12. “Nígbà tí a gba ilẹ̀ náà nígbà náà, àwọn ọmọ Reubẹni ati àwọn ọmọ Gadi ni mo fún, ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Anoni ati ìdajì agbègbè olókè ti Gileadi, pẹlu gbogbo àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀.

13. Ìdajì tí ó kù lára ilẹ̀ àwọn ará Gileadi, ati gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Baṣani tíí ṣe ìjọba Ogu, ati gbogbo agbègbè Arigobu, ni mo fún ìdajì ẹ̀yà Manase.”(Gbogbo ilẹ̀ Baṣani ni wọ́n ń pè ní ilẹ̀ àwọn Refaimu.

14. Jairi láti inú ẹ̀yà Manase ni ó gba gbogbo agbègbè Arigobu tí à ń pè ní Baṣani, títí dé etí ààlà ilẹ̀ àwọn Geṣuri, ati ti àwọn Maakati. Ó sọ àwọn ìlú náà ní orúkọ ara rẹ̀; ó pè wọ́n ní Hafoti Jairi. Orúkọ náà ni wọ́n ń jẹ́ títí di òní olónìí.)

15. Makiri, láti inú ẹ̀yà Manase ni mo fún ní ilẹ̀ Gileadi.

16. Àwọn ọmọ Reubẹni ati àwọn ọmọ Gadi ni mo sì fún ní agbègbè Gileadi títí dé àfonífojì Anoni, ààrin gbùngbùn àfonífojì náà ni ààlà ilẹ̀ wọn, títí lọ kan odò Jaboku, tíí ṣe ààlà àwọn ará Amoni;

17. ati ilẹ̀ Araba títí kan odò Jọdani. Láti Kinereti títí dé Òkun Araba tí wọn ń pè ní Òkun Iyọ̀, ní ẹsẹ̀ òkè Pisiga ní apá ìlà oòrùn.

18. “Mo pàṣẹ fun yín nígbà náà, mo ní, ‘OLUWA Ọlọrun yín ti fi ilẹ̀ yìí fun yín bíi ohun ìní; gbogbo àwọn akọni ninu àwọn ọkunrin yín yóo kọjá lọ pẹlu ihamọra ogun ṣiwaju àwọn ọmọ Israẹli, arakunrin yín.

19. Ṣugbọn àwọn aya yín ati àwọn ọmọ yín kéékèèké ati àwọn ẹran ọ̀sìn yín (mo mọ̀ pé wọ́n ti di pupọ nisinsinyii) yóo wà ninu àwọn ìlú tí mo ti fun yín

20. títí tí OLUWA yóo fi fún àwọn arakunrin yín ní ìsinmi bí ó ti fún yín, tí àwọn náà yóo wà lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun wọn ní òdìkejì odò Jọdani. Nígbà náà ni olukuluku yín yóo to pada sórí ilẹ̀ tí mo ti fun yín.’

Ka pipe ipin Diutaronomi 3