Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 3:15-27 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Makiri, láti inú ẹ̀yà Manase ni mo fún ní ilẹ̀ Gileadi.

16. Àwọn ọmọ Reubẹni ati àwọn ọmọ Gadi ni mo sì fún ní agbègbè Gileadi títí dé àfonífojì Anoni, ààrin gbùngbùn àfonífojì náà ni ààlà ilẹ̀ wọn, títí lọ kan odò Jaboku, tíí ṣe ààlà àwọn ará Amoni;

17. ati ilẹ̀ Araba títí kan odò Jọdani. Láti Kinereti títí dé Òkun Araba tí wọn ń pè ní Òkun Iyọ̀, ní ẹsẹ̀ òkè Pisiga ní apá ìlà oòrùn.

18. “Mo pàṣẹ fun yín nígbà náà, mo ní, ‘OLUWA Ọlọrun yín ti fi ilẹ̀ yìí fun yín bíi ohun ìní; gbogbo àwọn akọni ninu àwọn ọkunrin yín yóo kọjá lọ pẹlu ihamọra ogun ṣiwaju àwọn ọmọ Israẹli, arakunrin yín.

19. Ṣugbọn àwọn aya yín ati àwọn ọmọ yín kéékèèké ati àwọn ẹran ọ̀sìn yín (mo mọ̀ pé wọ́n ti di pupọ nisinsinyii) yóo wà ninu àwọn ìlú tí mo ti fun yín

20. títí tí OLUWA yóo fi fún àwọn arakunrin yín ní ìsinmi bí ó ti fún yín, tí àwọn náà yóo wà lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun wọn ní òdìkejì odò Jọdani. Nígbà náà ni olukuluku yín yóo to pada sórí ilẹ̀ tí mo ti fun yín.’

21. “Mo sọ fún Joṣua nígbà náà pé; ‘Ṣé ìwọ náà ti fi ojú ara rẹ rí ohun tí OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe sí àwọn ọba meji wọnyi? Bẹ́ẹ̀ gan-an ni OLUWA yóo ṣe sí ìjọba yòókù tí ẹ óo gbà.

22. Ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn rárá, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ni ó ń jà fun yín.’

23. “Mo bẹ OLUWA nígbà náà, mo ní,

24. ‘OLUWA Ọlọrun, o ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fi títóbi ati agbára rẹ han èmi iranṣẹ rẹ ni; nítorí pé, oriṣa wo ló wà, lọ́run tabi láyé yìí tí ó lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu bíi tìrẹ?

25. Mo bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí n kọjá sí òdìkejì Jọdani kí n sì rí ilẹ̀ dáradára náà, agbègbè olókè dáradára nnì ati Lẹbanoni.’

26. “Ṣugbọn OLUWA bínú sí mi nítorí yín, kò sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi. OLUWA dá mi lóhùn, ó ní, ‘Ó tó gẹ́ẹ́, má ṣe bá mi sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ mọ́.

27. Gun orí òkè Pisiga lọ, gbé ojú sókè, kí o sì wo apá ìwọ̀ oòrùn, ati apá àríwá, ati apá gúsù, ati apá ìlà oòrùn. Ojú ni o óo fi rí i, nítorí pé, o kò ní kọjá odò Jọdani yìí sí òdìkejì.

Ka pipe ipin Diutaronomi 3