Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 12:7-22 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ibẹ̀ ni ẹ̀yin ati gbogbo ìdílé yín yóo ti jẹun níwájú OLUWA Ọlọrun yín, inú yín yóo sì dùn nítorí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín tí OLUWA ti fi ibukun sí.

8. “Ẹ kò gbọdọ̀ máa ṣe bí a ti ń ṣe níbí lónìí, tí olukuluku ń ṣe èyí tí ó dára lójú ara rẹ̀.

9. Nítorí pé ẹ kò tíì dé ibi ìsinmi ati ilẹ̀ ìní tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fun yín.

10. Ṣugbọn nígbà tí ẹ bá rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani, tí ẹ sì ń gbé ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fun yín, nígbà tí ó bá sì fun yín ní ìsinmi, tí ẹ bá bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá tí ó yí yín ká, tí ẹ sì wà ní àìléwu,

11. ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn láti fi ibùgbé rẹ̀ sí nígbà náà, ni kí ẹ kó gbogbo àwọn nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín wa, ẹbọ sísun yín ati àwọn ẹbọ mìíràn, ìdámẹ́wàá yín, ati ọrẹ, ati gbogbo ẹ̀jẹ́ yín tí ẹ bá jẹ́ fún OLUWA.

12. Ẹ óo sì máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín, ati ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin, ati àwọn iranṣẹkunrin yín, ati àwọn iranṣẹbinrin yín, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà láàrin ìlú yín, nítorí pé wọn kò ní ìpín ninu ilẹ̀ yín.

13. Ẹ ṣọ́ra, ẹ má máa rú ẹbọ sísun yín níbikíbi tí ẹ bá ti rí.

14. Ṣugbọn ibi tí OLUWA yín bá yàn láàrin ẹ̀yà yín, ni kí ẹ ti máa rú ẹbọ sísun yín, kí ẹ sì máa ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fun yín níbẹ̀.

15. “Ṣugbọn ẹ lè pa iye ẹran tí ó bá wù yín, kí ẹ sì jẹ ẹ́ níbikíbi tí ẹ bá ń gbé, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun yín bá ti bukun yín tó. Ẹni tí ó mọ́, ati ẹni tí kò mọ́ lè jẹ ninu ẹran náà bí ìgbà tí eniyan ń jẹ ẹran ẹtu tabi ti àgbọ̀nrín.

16. Ẹ̀jẹ̀ wọn nìkan ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ, dídà ni kí ẹ dà á sílẹ̀ bí ẹni da omi.

17. Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ninu ohun tí o bá jẹ́ ìdámẹ́wàá yín ninu ìlú yín, kì báà ṣe ìdámẹ́wàá ọkà yín, tabi ti ọtí waini, tabi ti òróró, tabi ti àkọ́bí mààlúù, tabi ti ewúrẹ́, tabi ti aguntan, tabi ohunkohun tí ẹ bá fi san ẹ̀jẹ́ fún OLUWA, tabi ọrẹ àtinúwá yín tabi ọrẹ àkànṣe yín.

18. Níwájú OLUWA Ọlọrun yín, níbikíbi tí ó bá yàn, ni kí ẹ ti jẹ ẹ́; ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín, lọkunrin ati lobinrin, ati àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin yín, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n bá wà ninu ìlú yín. Kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín ninu ohun gbogbo tí ẹ bá ń ṣe.

19. Kí ẹ rí i dájú pé, ẹ kò gbàgbé àwọn ọmọ Lefi níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá wà lórí ilẹ̀ yín.

20. “Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá mú kí ilẹ̀ yín pọ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín, tí ẹran bá wù yín jẹ, ẹ lè jẹ ẹran dé ibi tí ó bá wù yín.

21. Bí ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun bá jìnnà pupọ sí yín, ẹ mú mààlúù tabi aguntan láti inú agbo ẹran tí OLUWA fi fun yín, kí ẹ pa á bí mo ti pa á láṣẹ fun yín, kí ẹ sì jẹ ohunkohun tí ọkàn yín bá fẹ́ láti jẹ láàrin àwọn ìlú yín.

22. Ati ẹni tí ó mọ́ ati ẹni tí kò mọ́ ni ó lè jẹ ninu ẹran náà bí ìgbà tí eniyan ń jẹ ẹran ẹtu tabi ti àgbọ̀nrín.

Ka pipe ipin Diutaronomi 12