Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 11:19-30 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Kí ẹ fi kọ́ àwọn ọmọ yín dáradára, ẹ máa fi ṣe ọ̀rọ̀ sọ nígbà tí ẹ bá jókòó ninu ilé yín ati ìgbà tí ẹ bá ń rìn lọ lójú ọ̀nà, ati ìgbà tí ẹ bá dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn yín ati nígbà tí ẹ bá dìde.

20. Ẹ kọ ọ́ sí ara òpó ìlẹ̀kùn ilé yín ati sí ara ẹnu ọ̀nà àbájáde ilé yín.

21. Kí ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun búra fún àwọn baba yín, pé òun yóo fún wọn títí lae, níwọ̀n ìgbà tí ojú ọ̀run bá wà lókè.

22. “Tí ẹ bá ṣọ́ra, tí ẹ sì pa gbogbo òfin tí mo fun yín mọ́, tí ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ̀ ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀, tí ẹ sì súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí,

23. OLUWA yóo lé àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi jáde fun yín, ẹ óo sì gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n pọ̀ jù yín lọ, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ.

24. Gbogbo ibi tí ẹsẹ̀ yín bá tẹ̀, ẹ̀yin ni ẹ óo ni ín. Ilẹ̀ yín yóo bẹ̀rẹ̀ láti aṣálẹ̀ Lẹbanoni, ati láti odò Yufurate títí dé Òkun tí ó wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn.

25. Kò ní sí ẹnikẹ́ni tí yóo lè dojú kọ yín, OLUWA Ọlọrun yín yóo mú kí ẹ̀rù yín máa ba gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ tí ẹ óo máa rìn kọjá, jìnnìjìnnì yín yóo sì máa bò wọ́n, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti ṣe ìlérí fun yín.

26. “Ẹ wò ó, mo gbé ibukun ati ègún kalẹ̀ níwájú yín lónìí.

27. Ibukun ni fun yín bí ẹ bá tẹ̀lé òfin OLUWA Ọlọrun yín, tí mo fun yín lónìí yìí.

28. Ṣugbọn ègún ni fun yín bí ẹ kò bá tẹ̀lé òfin OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ bá yà kúrò lójú ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fun yín lónìí, tí ẹ bá ń sin àwọn oriṣa tí ẹ kò mọ̀ rí.

29. Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá mú yín dé ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ, tí ẹ óo sì gbà, ẹ kéde ibukun náà lórí òkè Gerisimu, kí ẹ sì kéde ègún náà lórí òkè Ebali.

30. Òkè Gerisimu ati òkè Ebali wà ní òdìkejì Jọdani, ní ojú ọ̀nà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, ní ilẹ̀ àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé Araba, ní òdìkejì Giligali, lẹ́bàá igi Oaku More.

Ka pipe ipin Diutaronomi 11