Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 21:32-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Nítorí Jòhánù tọ́ yin wá láti fi ọ̀nà òdodo hàn yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbà á gbọ́, ṣùgbọ́n àwọn agbowó-òde àti àwọn panṣágà ronúpìwàdà, bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ rí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ wọ̀nyí, ẹ kọ̀ láti ronúpìwàdà, ẹ kò gbà á gbọ́.”

33. “Ẹ gbọ́ òwe mìíràn: Baálé ilé kan tí ó gbin àjàrà, ó ṣe ọgbà yìí ká, ó wá ibi ifúntí sínú rẹ̀, ó kọ́ ilé-ìsọ́. Ó sì fi oko náà ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn àgbẹ̀ kan, ó sì lọ sí ìrìnàjò.

34. Nígbà ti àkókò ìkórè súnmọ́, ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí àwọn àgbẹ̀ náà láti gba èyí ti ó jẹ tirẹ̀ wá.

35. “Ṣùgbọ́n àwọn olágbàtọ́jú sì mú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọn lu ẹnì kínní, wọn pa èkèjì, wọ́n si sọ ẹ̀kẹ́ta ní òkúta.

36. Lẹ́ẹ̀kejì, ó rán àwọn ìránṣẹ́ tí ó pọ̀ ju ti ìṣaájú sí wọn. Wọ́n sì tún ṣe bí ti àkọ́kọ́ sí àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.

37. Níkẹyìn, baálé ilé yìí rán ọmọ rẹ̀ pàápàá sí wọn. Ó wí pé, ‘Wọn yóò bu ọlá fún ọmọ mi.’

38. “Ṣùgbọ́n bí àwọn alágbàtọ́jú wọ̀nyí ti rí ọmọ náà lókèèrè, wọ́n wí fún ara wọn pé, ‘Èyí ni àrólé náà. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí a sì jogún rẹ̀.’

39. Wọ́n sì wọ́ ọ jáde kúrò nínú ọgbà, wọ́n sì pa á.

40. “Nítorí náà kí ni ẹ ní èrò wí pé olóko náa yóò ṣe pẹ̀lú àwọn alágbàtọ́jú wọ̀nyí nígbà tí ó bá padà dé?”

Ka pipe ipin Mátíù 21