orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Jésù Rán Àwọn Méjìlá Jáde

1. Jésù sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí ọ̀dọ̀; ó fún wọn ní àṣẹ láti lé ẹ̀mí àìmọ́ jáde àti láti ṣe ìwòsàn àrùn àti àìsàn gbogbo.

2. Orúkọ àwọn àpósítélì méjèèjìlá náà ni wọ̀nyí: ẹni àkọ́kọ́ ni Símónì ẹni ti a ń pè ni Pétérù àti arákùnrin rẹ̀ Ańdérù, Jákọ́bù ọmọ Sébédè àti arákùnrin rẹ̀ Jòhánù.

3. Fílípì àti Bátólómíù; Tómásì àti Mátíù agbowó òde; Jákọ́bù ọmọ Álíféù àti Tádéù;

4. Símónì ọmọ ẹgbẹ́ Sílíọ́tì, Júdásì Ísíkáríọ́tù, ẹni tí ó da Jésù.

5. Jésù ran àwọn méjèèjìla yìí jáde, pẹ̀lú àṣẹ báyìí pé: “Ẹ má ṣe lọ sì àárín àwọn aláìkọlà tàbí wọ̀ èyíkèyìí ìlú àwọn ará Samáríà

6. Ẹ kúkú tọ̀ àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tí ó nù lọ.

7. Bí ẹ̀yin ti ń lọ, ẹ máa wàásù yìí wí pé: ‘Ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.’

8. Ẹ máa ṣe ìwòṣan fún àwọn aláìsàn, ẹ si jí àwọn okú dìde, ẹ sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, kí ẹ sì máa lé àwọn ẹ̀mí-èṣù jáde. Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbàá, ọ̀fẹ́ ni kú ẹ fi fún ni.

9. Ẹ má ṣe mú wúrà tàbí fàdákà tàbí idẹ sínú àpò ìgbànú yín;

10. Ẹ má ṣe mú àpo fún ìrìnàjò yín, kí ẹ má ṣe mú ẹ̀wù méjì, tàbí bàtà, tàbí ọ̀pá; oúnjẹ oníṣẹ́ yẹ fún un.

11. “Ìlúkílùú tàbí ìletòkíletò tí ẹ̀yin bá wọ̀, ẹ wá ẹni ti ó bá yẹ níbẹ̀ rí, níbẹ̀ ni kí ẹ sì gbé nínú ilé rẹ̀ títítí ẹ̀yin yóò fi kúrò níbẹ̀.

12. Nígbà tí ẹ̀yin bá sì wọ ilé kan, ẹ kí i wọn.

13. Bí ilé náa bá sì yẹ, kí àlàáfíà yín kí ó bà sórí rẹ̀; ṣùgbọ́n bí kò bá yẹ, kí àlàáfíà yín kí ó padà sọ́dọ̀ yín.

14. Bí ẹnikẹ́ni tí kò bá sì gbà yín, tàbí tí kò gba ọ̀rọ̀ yín, ẹ gbọn eruku ẹ̀ṣẹ̀ yín sílẹ̀ tí ẹ bá ń kúrò ní ilé tàbí ìlú náà.

15. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, yóò sàn fún ìlú Sódómù àti Gòmórà ní ọjọ́ ìdájọ́ ju àwọn ìlú náà lọ.

16. Mò ń rán yín lọ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn sáàrin ìkookò. Nítorí náà, kí ẹ ní ìṣọ́ra bí ejò, kí ẹ sì ṣe onírẹ̀lẹ̀ bí àdàbà.

17. “Ẹ ṣọ́ra lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn nítorí wọn yóò fi yín le àwọn ìgbìmọ̀ ìgbéríko lọ́wọ́ wọn yóò sì nà yín nínú sínágọ́gù.

18. Nítorí orúkọ mi, a ó mú yín lọ ṣíwájú àwọn baálẹ̀ àti àwọn ọba, bí ẹlẹ́rìí sí wọn àti àwọn aláìkọlà.

19. Nígbà tí wọ́n bá mú yín, ẹ má ṣe ṣàníyàn ohun tí ẹ ó sọ tàbí bí ẹ ó ṣe sọ ọ́. Ní ojú kan náà ni a ó fi ohun tí ẹ̀yin yóò sọ fún yín,

20. Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ó sọ ọ́, bí kò ṣe Ẹ̀mí Baba yín tí ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ yín.

21. “Ọmọ-ìyá méjì yóò ṣe ikú pa ara wọ́n. Baba yóò fi àwọn ọmọ rẹ̀ fún ikú pa. Àwọn ọmọ yóò sọ̀tẹ̀ sí òbí wọn, wọn yóò sì mú kí a pa wọ́n.”

22. Gbogbo ènìyàn yóò sì kórìíra yín nítorí mi, ṣùgbọ́n gbogbo ẹni tí ó bá dúró ṣinṣin dé òpin ni a ó gbàlà.

23. Nígbà tí wọn bá ṣe inúnibíni sì i yín ní ìlú kan, ẹ sá lọ sì ìlú kejì. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹ̀yin kò tì í le la gbogbo ìlú Ísírẹ́lì já tán kí Ọmọ Ènìyàn tó dé.

24. “Akẹ́kọ̀ọ́ kì í ju olùkọ́ rẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ-ọ̀dọ̀ kì í ju ọ̀gá rẹ̀ lọ.

25. Ó tọ́ fún akẹ́kọ̀ọ́ láti dà bí olùkọ́ rẹ̀ àti fún ọmọ-ọ̀dọ̀ láti rí bí ọ̀gá rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá pe baálé ilé ní Béélísébúbù, mélòó mélòó ni ti àwọn ènìyàn ilé rẹ̀!

26. “Nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí kò sí ohun to bò tí kò níí fara hàn, tàbí ohun tó wà ní ìkọ̀kọ̀ tí a kò ní mọ̀ ni gbangba.

27. Ohun tí mo bá wí fún yín ní òkùnkùn, òun ni kí ẹ sọ ní ìmọ́lẹ̀. Èyí tí mo sọ kẹ́lẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sì etí yín ni kí ẹ kéde rẹ́ lórí òrùlé.

28. Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó le pa ara nìkan; ṣùgbọ́n tí wọn kò lé pa ẹ̀mí. Ẹ bẹ̀rù Ẹni tí ó le pa Ẹ̀mí àti ara run ní ọ̀run apáàdì.

29. Ológoṣẹ́ méjì kọ́ ni à ń tà ní owó idẹ wẹ́wẹ́ kan? Ṣíbẹ̀ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò ṣubú lulẹ̀ lẹ́yìn Baba yin.

30. Àti pé gbogbo irun orí yín ni a ti kà pé.

31. Nítorí náà, ẹ má ṣe fòyà; ẹ̀yin ní iye lórí ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.

32. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú ènìyàn, òun náà ni èmi yóò jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú Baba mi ní ọ̀run.

33. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sẹ́ mí ní níwájú àwọn ènìyàn, òun náà ni èmi náà yóò sọ wí pé n kò mọ̀ níwájú Baba mi ní ọ̀run.

34. “Ẹ má ṣe rò pé mo mú àlàáfíà wá sí ayé, Èmi kò mú àlàáfíà wá bí kò ṣe idà.

35. Nítorí èmi wá láti“ ‘ọmọkùnrin ní ipa sí bàbá rẹ̀,ọmọbìnrin ní ipa sí ìyá rẹ̀,àti aya ọmọ sí ìyakọ rẹ̀…

36. Ará ilé ènìyàn ni yóò sì máa ṣe ọ̀tá rẹ̀.’

37. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ràn bàbá rẹ̀ tàbí ìyá rẹ̀ jù mí lọ kò yẹ ní tèmi, ẹnikẹ́ni tí ó ba fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ̀ obìnrin jù mí lọ kò yẹ ní tèmi;

38. Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbé àgbélébùú rẹ̀ kí ó tẹ̀ lé mi kò yẹ ní tèmi.

39. Ẹni tí ó bá rí ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nú nítorí tèmi ni yóò rí i.

40. “Ẹni tí ó bá gbà yín, ó gbà mí, ẹni tí ó bá sì gbà mí gba ẹni tí ó rán mi.

41. Ẹni tí ó ba gba wòlíì, nítorí pé ó jẹ́ wòlíì yóò jẹ èrè wòlíì, ẹni tí ó bá sì gba olódodo nítorí ti ó jẹ́ ènìyàn olódodo, yóò jẹ èrè olódodo.

42. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ago omi tútú fún ọ̀kan nínú àwọn onírẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí mu nítorí tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi, ọ̀títọ́ ni mo wí fún yín, kò ní pàdánù èrè rẹ̀.”