orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Bíbéèrè Fún Àmì

1. Àwọn Farisí àti àwọn Sadusí wá láti dán Jésù wò. Wọ́n ní kí ó fi àmì ńlá kan hàn àwọn ní ojú ọ̀run.

2. Ó dá wọn lóhùn pé, “Nígbà tí ó bá di àṣálẹ́, ẹ ó sọ pé, ‘Ìbá dára kí ojú ọ̀run pọ́n.’

3. Ní òwúrọ̀, ‘Èyin yóò wí pé ọjọ́ kì yóò dára lónìí, nítorí ti ojú ọ̀run pọ́n, ó sì ṣú dẹ̀dẹ̀,’ ẹ̀yin àgàbàgebè, ẹ̀yin le sọ àmì ojú ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò le mọ àmì àwọn àkókò wọ̀nyí.

4. Ìran búburú aláìgbàgbọ́ yìí ń béèrè àmì àjèjì mélòó kàn ni ojú sánmọ̀, ṣùgbọ́n a kí yóò fún ẹnìkan kan ní àmì bí kò ṣe àmì Jónà.” Nígbà náà ni Jésù fi wọ́n sílẹ̀, ó sì bá tirẹ̀ lọ.

(Ìwúkàrà) Yíìsìtì Farisí àti Sadusí

5. Nígbà tí wọ́n dé apá kejì adágún, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sàkíyèsí pé wọ́n ti gbàgbé láti mú àkàrà kankan lọ́wọ́.

6. Jésù sì kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ kíyè sára, ẹ sì ṣọ́ra, ní ti ìwúkàrà àwọn Farisí àti àwọn Sadusí.”

7. Wọ́n ń sọ eléyìí ni àárin ara wọn nítorí pé wọ́n ti gbàgbé láti mú àkàrà lọ́wọ́.

8. Nígbà tí ó gbọ́ ohun ti wọ́n ń sọ, Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré, èé ṣe tí ẹ̀yin ń dààmú ara yín pé ẹ̀yin kò mú oúnjẹ lọ́wọ́?

9. Tàbí ọ̀rọ̀ kò yé yín di ìsinsìn yìí? Ẹ̀yin kò rántí pé mo bọ́ ẹgbẹẹ́dọ́gbọ́n (5,000) ènìyàn pẹ̀lú ìsù búrẹ́dì márùn-ún àti iye agbọ̀n tí ẹ kó jọ bí àjẹkù?

10. Ẹ kò sì tún rántí ìsù méje tí mo fi bọ́ ẹgbààjì (4,000) ènìyàn àti iye àjẹkù tí ẹ kó jọ?

11. È é ha ṣe tí kò fi yé yín pé èmi kò sọ̀rọ̀ nípa ti búrẹ́dì? Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo wí fún yín, ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí àti ti Sadusí.”

12. Nígbà náà ni ó ṣẹ̀sẹ̀ wá yé wọn pé, kì í ṣe nípa ti ìwúkàrà ní ó sọ wí pé kí wọ́n kíyè sára, bí kò se tí ẹ̀kọ́ àwọn Farisí àti Sadusí.

Pétérù jẹ́wọ́ Kírísítì

13. Nígbà tí Jésù sì dé Kesaríà-Fílípì, ó bi àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi Ọmọ ènìyàn pè?”

14. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn kan ni Jòhánù onítẹ̀bọ́mì ni, àwọn mìíràn wí pé, Èlíjà ni, àwọn mìíràn wí pé, Jeremáyà ni, tàbí ọ̀kan nínú àwọn wòlíì.”

15. “Ṣùgbọ́n ìwọ ń kọ” Ó bi í léèrè pé, “Ta ni ìwọ rò pé mo jẹ́?”

16. Símónì Pétérù dáhùn pé, “Ìwọ ni Kírísítì náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè”

17. Jésù sì wí fún un pé, “Alábùnkún-fún ni ìwọ Símónì ọmọ Jónà, nítorí ènìyàn kọ́ ló fi èyí hàn bí kò se Baba mi tí ó ń bẹ ní ọ̀run.

18. Èmi wí fún ọ, ìwọ ni Pétérù àti pé orí àpáta yìí ni èmi yóò kọ́ ìjọ mi lé, àti ẹnu-ọ̀nà ipò-òkú kì yóò lè borí rẹ̀.

19. Èmi yóò fún ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba Ọ̀run; Ohun tí ìwọ bá dè ní ayé, òun ni a ó dè ní ọ̀run. Ohunkóhùn tí ìwọ bá sì tú ní ayé yìí, a ó sì tú ní ọ̀run.”

20. Nígbà náà kìlọ̀ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni pé Òun ni Kírísítì náà.

Jésù ṣọ Ṣọtẹ́lẹ̀ Nípa Ikú Ara rẹ̀

21. Láti ìgbà yìí lọ, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí iṣàlàyé fún àwọn ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀ kedere nípa lílọ sí Jerúsálémù láti jẹ ọ̀pọ̀ ìyà lọ́wọ́ àwọn, olórí àwọn àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin, pé wọn yóò pa òun, àti pé òun yóò jí dìde sí ààyè ní ọjọ́ kẹ́ta.

22. Pétérù mú Jésù sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bá a wí pé, “Kí a má rí i Olúwa. Èyí kì yóò ṣẹlẹ̀ sí Ọ.”

23. Jésù pa ojú dà, ó sì wí fún Pétérú pé, “Kúrò lẹ́yìn mi, Sàtáni! Ohun ìkọ̀ṣẹ̀ ni ìwọ jẹ́ fún mi; ìwọ kò ro ohun tí i se ti Ọlọ́run, bí kò se èyí ti se ti ènìyàn.”

24. Nígbà náà ni Jésù wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó sì gbé àgbélébùú rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn.

25. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóò sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi, yóò rí i.

26. Èrè kí ni ó jẹ́ fún ènìyàn bí ó bá jèrè gbogbo ayé yìí, tí ó sì sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù? Tàbí kí ni ènìyàn yóò fi dípò ẹ̀mí rẹ̀?

27. Nítorí Ọmọ ènìyàn yóò wá nínú ogo baba rẹ pẹ̀lú àwọn ańgẹ́lì rẹ̀, nígbà náà ni yóò sì san án fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.

28. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín. Ẹlòmíràn wà nínú àwọn tí ó níhìn-ín yìí, tí kì yóò ri ikú títí wọn ó fi rí ọmọ-ènìyàn tí yóò máa bà ní ìjọba rẹ̀.”