orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìṣípayá Pọ́ọ̀lù Àti Ẹ̀gún Tí Ń Bẹ Lára Rẹ̀

1. Èmi kò lè sàì sògo bí kò tilẹ̀ ve àǹfààní, nítorí èmi ó wà sọ nípa ìran àti ìṣípayá ti Olúwa fihàn mí.

2. Èmi mọ ọkùnrin kan nínú Kírísítì ní ọdún mẹ́rìnlá sẹ́yin, yálà nínú ara ni, èmi kò mọ̀; tàbí kúrò nínú ara, èmi kò mọ̀; Ọlọ́run mọ̀: a gbé irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ lọ sí ọ̀run kẹta.

3. Bẹ́ẹ̀ ni èmi mọ irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀, yálà ní ara ni, tàbí kúrò nínú ara ni, èmi kò mọ̀: Ọlọ́run mọ̀.

4. Pé a gbé e lọ sókè sí Párádísè, tí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tí a kò sì lè sọ, tí kò tọ́ fún ènìyàn láti máa sọ.

5. Nípa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni èmi ó máa ṣògo: ṣùgbọ́n nípa ti èmi tìkáraami èmi kì yóò ṣògo, bí kò ṣe nínú àìlera mi.

6. Nítorí pé bi èmi tilẹ̀ ń fẹ́ máa ṣògo, èmi kì yóò jẹ́ òmùgọ̀; nítorí pé èmi yóò sọ òtítọ́: ṣùgbọ́n mo kọ̀, kí ẹnikẹ́ni máa bà à fi mí pè ju ohun tí ó rí tí èmi jẹ́ lọ, tàbí ju èyí tí ó gbọ́ lẹ́nu mi.

7. Àti nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsípayá, kí èmi má ba à gbé ara mi ga rékọjá, a sì ti fi ẹ̀gún kan sí mi lára, ìránṣẹ́ Sátanì láti pọ́n mi lójú, kí èmi má bá a gbéraga rékọjá.

8. Nítorí nǹkan yìí ni mo ṣe bẹ Olúwa nígbà mẹ́ta pé, kí ó lé e kúrò lára mi.

9. Òun sì wí fún mi pé, “Oore ọ̀fẹ́ mi tó fún ọ: nítorí pé a sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.” Nítorí náà tayọ̀tayọ̀ ni èmi ó kúkú máa fí ṣògo nínú àìlera mi, kí agbára Kírísítì lè máa gbé inú mi.

10. Nítorí náà èmi ní inú dídùn nínú àìlera gbogbo, nínú ẹ̀gàn gbogbo, nínú àìní gbogbo, nínú inúníbíni gbogbo, nínú wàhálà gbogbo nítorí Kírísítì. Nítorí nígbà tí mo bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.

Àníyàn Pọ́ọ̀lù Nípa Àwọn Ará Kọ́ríńtì

11. Mo di òmùgọ̀ nípa ṣíṣògo; ẹ̀yin ní ó fí ipá mú mi ṣe é: nítorí tí ó tọ́ tí ẹ bá yìn mí: nítorí tí èmi kò rẹ̀yìn lóhunkóhun sí àwọn àgbà Àpósítélì bí èmi kò tilẹ̀ jámọ́ nǹkan kan.

12. Ohun kan tí ó ṣe àmì àpósítélì, iṣẹ́ ìyanu and iṣẹ́ agbára ní won ṣe ní àárin yín pẹ̀lú sùúrù tó ga.

13. Nítorí nínú kín ni ohun tí ẹ̀yin ṣe rẹ̀yìn sí ìjọ mìíràn, bí kò ṣe ní ti pé èmi fúnra mi kó jẹ́ oníyọnú fún yín? Ẹ dárí àṣìṣe yìí jì mí.

14. Kíyèsí i, ìgbà kẹta yìí ni mo múra tan láti tọ̀ yín wá: èmi kì yóò sì jẹ́ oníyọnu fún yín nítorí tí èmi kò wá nǹkan yín, bí kò ṣe ẹ̀yin fúnra yín; nítorí tí kò tọ́ fún àwọn ọmọ láti máa to ìṣúra jọ fún àwọn òbí wọn, bí kò se àwọn òbí fún àwọn ọmọ wọn.

15. Èmi ó sì fi ayọ̀ ná ohun gbogbo tí mo bá ní, èmi ó sì ná ara mi fún ọkàn yín nítòótọ́; bí mo bá fẹ́ yín lọ́pọ̀lọpọ̀, ó há tọ́ kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn mi díẹ̀ bí?

16. Ṣùgbọ́n ó dára bẹ́ẹ̀ tí èmi kò dẹ́rúbà yín: ṣùgbọ́n bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn, èmi ń fí ọwọ́ ẹ̀rọ̀ mú yín.

17. Èmi há rẹ́ yín jẹ nípa ẹnikẹ́ni nínú àwọn tí mo rán sí yín bi?

18. Mo bẹ Títù, mo sì rán arákùnrin kan pẹ̀lú rẹ̀; Títù há rẹ́ yín jẹ bí? Nípa ẹ̀mi kan náà kọ́ àwa rìn bí? Ọ̀nà kan náà kọ́ àwa tọ̀ bí?

19. Ẹ̀yin há rò pé àwa ń sọ nǹkan wọ̀nyí láti gbèjà ara wa níwájú yín bí? Ní iwájú Ọlọ́run ni àwa ń ṣọrọ nínú Kírísítì; ṣùgbọ́n àwa ń ṣe ohun gbogbo, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, láti gbé yín ró ni.

20. Nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé, nígbà tí mo bá dé, èmi kì yóò bá yín gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí mo fẹ́, àti pé ẹ̀yin yóò sì rí mi gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí ẹ̀yin kò fẹ́: Kí ìjà, owú-jíjẹ, ìbínú, ìpínyà, ìsọ̀rọ̀-ẹni-lẹ́yìn, ìjírọ̀sọ̀, ìfẹẹ́gẹ̀, ìrúkèrúdò, má bà à wà.

21. Àti nígbà tí mo bá sì padà dé, kí Ọlọ́run mí má bà à rẹ̀ mí sílẹ̀ lójú yín, àti kí èmi má bà à sọkún nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó tí ṣẹ̀ náà tí kò sì ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ ìwà èérí, àgbérè, àti wọ̀bìà tí wọ́n ti hù.