orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Gẹ́gẹ́ bí alábáṣiṣẹ́ pọ̀ nínú Ọlọ́run, ǹjẹ́, àwa ń rọ̀ yín kí ẹ má ṣe gba oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run lásán.

2. Nítorí o wí pé,“Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà mi, èmi tí gbọ́ ohùn rẹ,àti ọjọ́ ìgbàlà, èmi sì ti ràn ọ́ lọ́wọ́.”Èmi wí fún ọ, nísínsín yìí ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, nísínsín yìí ní ni ọjọ́ ìgbàlà.

Àwọn Wàhálà Pọ́ọ̀lù

3. Àwa kò sì gbé ohun ìkọ̀sẹ̀ kankan si ọ̀nà ẹnikẹ́ni, ki iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa má ṣe di ìsọ̀rọ̀ òdì sí.

4. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, ni ọnà gbogbo, àwa ń fí ara wa hàn bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sùúrù, nínú ìpọ́njú, nínú àìní, nínú wàhálà,

5. nípa nínà, nínú túbú, nínú ìrúkèrúdò, nínú iṣẹ́ àṣekára, nínú àìṣan, nínú ìgbààwẹ̀.

6. Nínú ìwà mímọ̀, nínú ìmọ̀, nínú ìpamọ́ra, nínú ìṣeun, nínú Ẹ̀mi Mímọ̀, nínú ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn.

7. Nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́, nínú agbára Ọlọ́run, nínú ìhámọ́ra òdodo ní apá ọ̀tún àti ní apa òsì.

8. Nípa ọlá àti ẹ̀gàn, nípa ìyìn búburú àti ìyìn rere: bí ẹlẹ́tàn, ṣùgbọ́n a já sí ólóòótọ́,

9. bí ẹni tí a kò mọ̀, ṣùgbọ́n a mọ̀ wá dájúdájú; bí ẹni tí ń kú lọ, ṣùgbọ́n a si wà láàyè; bí ẹni tí a nà, ṣùgbọ́n a kò sì pa wá,

10. bí ẹni tí ó kún fún ìbànújẹ́, ṣùgbọ́n àwa ń yọ̀ nígbà gbogbo; bí talákà, ṣùgbọ́n àwa ń sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ dí ọlọ́rọ̀; bí ẹni tí kò ní nǹkan, ṣùgbọ́n àwa ni ohun gbogbo.

11. Ẹ̀yin ará Kọ́ríńtì, a ti bá yín sọ òtítọ́ ọ̀rọ̀, a ṣí ọkàn wa payá sí yín.

12. A kò ni yín lára nítorí wa, ṣùgbọ́n a ni yín lára nítorí ìfẹ́ ọkàn ẹ̀yin fúnra yín.

13. Ní sísán padà, ní ọ̀nà tí ó dára, (èmi ń sọ bí ẹni pé fún àwọn ọmọdé) ẹ̀yin náà, ẹ ṣí ọkàn yín payá pẹ̀lú.

Má Ṣe Dàpọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Aláìgbàgbọ́

14. Ẹ má ṣe fí àìdọ́gba dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́: nítorí idápọ̀ kín ni òdodo ní pẹ̀lú àìṣòdodo? Ìdápọ̀ kín ni ìmọ́lẹ̀ sì ní pẹ̀lú òkùnkùn?

15. Ìrẹ́pọ̀ kín ni Kírísítì ní pẹ̀lú Bélíàlì? Tàbí ìpín wó ni ẹni tí ó gbàgbọ́ ní pẹ̀lú aláìgbàgbọ́?

16. Ìrẹ́pọ̀ kín ni tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ní pẹ̀lú òrìṣà? Nítorí ẹ̀yin ní tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run alààyè; gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti wí pé, “Èmi á gbé inú wọn, èmi o sì máa rìn láàárin wọn; èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi.”

17. “Nítorí náà ẹ jáde kúrò láàárin wọn,kí ẹ sì yá ara yín si ọ̀tọ̀,ni Olúwa wí.Ki ẹ má ṣe fi ọwọ kan ohun àìmọ́;Èmi ó sì gbà yín.”

18. “Èmi o sì jẹ́ Baba fún yín,Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ọmọkùnrin mi àti ọmọbìnrin mi!ní Olúwa Olódùmarè wí.”