orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àwọn Ìkìlọ̀ ìkẹyìn

1. Èyí ni ó dí ìgbà kẹta tí èmi ń tọ̀ yín wá. Ní ẹnu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta ni a ó fí ìdí ọ̀rọ̀ gbogbo múlẹ̀.

2. Mo ti sọ fún yín ṣáájú, mo sì ń sọ fún yín tẹ́lẹ̀, bí ẹni pé mo wà pẹ̀lú yín nígbà kejì, àti bí èmi kò ti sí lọ́dọ̀ yín ní ìsinsin yìí, mo kọ̀wé sí àwọn tí ó ti ṣẹ̀ náà, àti sí gbogbo àwọn ẹlòmíran, pé bí mo bá tún padà wá, èmi kì yóò dá wọn sí.

3. Níwọ̀n bí ẹ̀yin tí ń wá àmì Kírísítì ti ń sọ̀rọ̀ nínú mi, ẹni tí kì í ṣe àìlera sí yin, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ agbára nínú yín.

4. Nítorí pé a kàn án mọ́ àgbélébùú nípa àìlera, ṣùgbọ́n òun wà láàyè nípa agbára Ọlọ́run. Nítorí àwa pẹ̀lú já sí aláìlera nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa yóò wà láàyè pẹ̀lú rẹ̀ nípa agbára Ọlọ́run sí yín.

5. Ẹ máa wádìí ara yín, bí ẹ̀yin bá wà nínú ìgbàgbọ́; ẹ máa dán ara yín wò. Tàbí ẹ̀yin fúnra yín kò mọ ara yín pé Jésù Kírísítì wá nínú yín? Àfi bí ẹ̀yin bá jẹ́ àwọn tí a tanù.

6. Ṣùgbọ́n mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, àwa kì í ṣe àwọn tí a tanù.

7. Ǹjẹ́ àwa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, kì í ṣe nítorí kí àwa lè farahàn bí àwọn ti ó tayọ̀, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè máa ṣe èyí tí ó dára bí àwa tilẹ̀ dàbí àwọn tí a tanù.

8. Nítorí àwa kò lè ṣe ohun kan lòdì sí òtítọ́, bí kò ṣe fún òtítọ́.

9. Nítorí àwa ń yọ̀, nígbà ti àwa jẹ́ aláìlera, tí ẹ̀yín sì jẹ́ alágbára; èyí ni àwa sì ń gbàdúrà fún pẹ̀lú, àní pípé yín.

10. Ìdí nìyí mo ṣe kọ̀wé àwọn nǹkan wọ̀nyí nígbà tí èmi kò sí lọ́dọ̀ yín, pé nígbà tí mo bá dé kí èmi má ba à lo ìkanra ní lílo àṣẹ, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Olúwa ti fifún mí, láti mú dàgbàsókè, kì í ṣe láti fà yín subú.

Ìkíni Ìgbẹ̀yìn

11. Ní àkótan, ará ó dì gbòóṣe, ẹ ṣe àtúnse ọ̀nà yín, ẹ tújúká, ẹ jẹ́ onínúkan, ẹ máa wà ní àlàáfíà, Ọlọ́run ìfẹ́ àti ti àlàáfíà yóò wà pẹ̀lú yín.

12. Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín.

13. Gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ kí yín.

14. Oore ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa, àti ìfẹ́ Ọlọ́run, àti ìdàpọ̀ ti Èmí Mímọ́, kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín. (Àmín).