orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Pétérù 5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Sí Àwọn Alàgbà Àti Àwọn Ọ̀dọ́kùnrin.

1. Àwọn alàgbà tí ń bẹ láàrin yín ni mo gbànímọ̀ràn, èmi ẹni tí ń ṣe alàgbà bí ẹ̀yin, àti ẹlẹ́rìí ìyà Kírísítì, àti alábàápín nínú ògo tí a ó fihàn:

2. Ẹ máa tọ́jú agbo Ọlọ́run tí ń bẹ láàrin yín, ẹ máa bojútó o, kì í ṣe àfipáse, bí kò se tìfẹ́tìfẹ́; kó má sì jẹ́ fún èrè ijẹkújẹ, bí kò ṣe pẹ̀lú ìyè inú tí ó múra tan.

3. Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe bí ẹni tí ń lo agbára lórí ìjọ, ṣùgbọ́n kí ẹ ṣe ara yín ní àpẹẹrẹ fún agbo.

4. Nígbà tí olórí Olùsọ́-àgùntàn bá sì fi ara hàn, ẹ̀yin ó gba adé ògo ti kì í ṣá.

5. Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ tẹriba fún àwọn alàgbà. Àní, gbogbo yín ẹ máa tẹriba fún ara yín kí ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ wọ ara yin ní aṣọ: nítorí“Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn agbéraga,ṣùgbọ́n ó ń fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.”

6. Nítorí náà, ẹ rẹ ara yin sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára Ọlọ́run, kí òun lè gbe yín ga lákòókò.

7. Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lé e; nítorí tí òun ń ṣe ìtọ́jú yín.

8. Ẹ máa wà ni àìrékọjá, ẹ máa ṣọ́ra; nítorí Èṣù ọ̀ta yín, bí kínnìún tí ń ke ramúramù, o ń rìn káàkiri, ó ń wa ẹni tí yóò pajẹ.

9. Ẹ kọ ojú ìjà sí i pẹ̀lú ìdúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́, bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé ìyà kan-náà ni àwọn ará yín tí ń bẹ nínú ayé ń jẹ.

10. Ọlọ́run oore-ọ̀fẹ́ gbogbo, tí ó ti pè yín sínú ògo rẹ̀ tí kò nípẹ̀kun nínú Kírísítì Jésù, nígbà tí ẹ̀yin bá ti jìyà díẹ̀, òun tìkararẹ̀, yóò sì ṣe yín ní àṣepé, yóò fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, yóò fún yín lágbára, yóò fi ìdí yín kalẹ̀.

11. Tírẹ̀ ni ògo àti agbára títí láé (Àmín)

Àwọn Ìkíni Ìgbẹ̀yìn

12. Nítorí Sílà, arákùnrin wa olóòtọ́ gẹ́gẹ́ bí mo ti kà á sí, ni mo kọ̀wé kúkurú sí i yín, tí mo ń gbà yín níyànjú, tí mo sì ń jẹ́rìí pé, èyí ni òtítọ́ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run: ẹ dúró ṣinṣin nínú rẹ̀.

13. Ìjọ tí ń bẹ ní Bábílónì, tí a yàn, pẹ̀lú kí yín, bẹ́ẹ̀ sì ni Máàkù ọmọ mi pẹ̀lú.

14. Ẹ fi ìfẹ́nukònú ìfẹ́ kí ara, yín (Àmín)