orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Pétérù 1 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Pétérù, Àpósítélì Jésù Kírísítì,Sí àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run, ti wọ́n ń ṣe àtìpó ní àgbáyé, ti wọn tú káàkiri sí Pọ́ńtù, Gálátíà, Kápádókíà, Ésíà, àti Bítíníà,

2. àwọn ẹni tí a ti yàn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Baba, nípa ìsọdimímọ́ Ẹ̀mí, sí ìgbọ́ràn àti ìbùwọ́n ẹ̀jẹ̀ Jésù Kírísítì:Kí oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà máa bí sì fún yín.

Ìyìn sí Ọlọ́run fún ìrètí tó wà láàyè

3. Ìyìn yẹ Ọlọ́run àti Baba Jésù Kírísítì Olúwa wa! Ẹni tí ó tún wa bí gẹ́gẹ́ bí àánú ńlárẹ̀ sínú ìrètí ààyè nípa àjíǹde Jésù Kírísítì kúrò nínú òkú,

4. àti sínú ogún àìdíbàjẹ́, àti àìlábàwọ́n, àti èyí tí kì í sá, tí a ti fi pamọ́ ni ọ̀run dè yin,

5. Ẹ̀yin tí a ń pamọ́ nípa agbára Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ si ìgbàlà, tí a múra láti fihàn ní ìgbà ìkẹyin.

6. Ẹ yọ̀ nínú èyí púpọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe nísinsin yìí fún ìgbà díẹ̀, níwọ̀nbí ó ti yẹ, a ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdánwò bá yín nínú jẹ́:

7. Àwọn wọ̀nyìí sì wáyé ìdánwò ìgbàgbọ́ yín tí ó ni iye lórí ju wúrà, ti ń ṣègbé lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iná ni a fi ń dán an wò, lè yọrísí ìyìn àti ògo àti ọlá ni ìgbà ìfarahàn Jésù Kírísítì.

8. Ẹni tí ẹ̀yin fẹ́ láìrí, ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ jé pé ẹ kò rí i nísinsin yìí ẹ̀yin sì ń yọ ayọ̀ tí a kò lè fi ẹnu sọ, tí ó sì kún fún ògo;

9. Ẹ̀yin sì ń gba ìlépa ìgbàgbọ́ yín, àní ìgbàlá ọkàn yín;

10. Ní ti ìgbàlà yìí, àwọn wòlíì tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa oore-ọ̀fẹ́ tí ó mú tọ̀ yín wá, wádìí jinlẹ̀ jinlẹ̀ pẹ̀lú ìbìkítà tí ó ga jùlọ.

11. Wọ́n ń wádìí ìgbà wo tàbí irú sáà wo ni Ẹ̀mí Kírísítì tí ó wà nínú wọn ń tọ́ka sí, nígbà tí ó jẹ́rìí ìyà Kírísítì àti ògo tí yóò tẹ̀lé e.

12. Àwọn ẹni tí a fihàn fún, pé kì í ṣe fún àwọn tìkárawọn bí kò se fún ẹ̀yin, nígba tí wọ́n sọ nípa àwọn ohun tí ẹ ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn tó ń wàásù ìyìnrere náà fún yín nípaṣẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a rán wá láti ọ̀run.

Ẹ Jẹ́ Mímọ́

13. Nítorí náà, ẹ múra ọkàn yín sílẹ̀, ẹ kó ara yín ní ìjánu, kí ẹ sì fi ìrètí yín ní kíkún sí ooe-ọ̀fẹ́, èyí tí a ń mu bọ̀ fún yin ni ìgbà ìfarahàn Jésù Kírísítì.

14. Bí àwọn ọmọ tí ń ń gbọ́ràn, láìdá ara yín pọ̀ mọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìmọ́ yín ti àtijọ.

15. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹni tí o pè yin ti jẹ mímọ́; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà jẹ mímọ́.

16. Nítorí a ti kọ ọ pé, “Ẹ jẹ́ mímọ́: nítorí tí Èmi jẹ mímọ́!”

17. Níwọ̀n bí ẹ̀yin ti ń képe Baba, ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ olúkúlùkù láìṣe ojúsáájú, ẹ máa lo ìgbà àtipó yin ni ìbẹ̀rù.

18. Níwọ̀nbí ẹ̀yin ti mọ̀ pé a kò fi ohun ìdíbàjẹ́ rà yín pàdà, bí fàdákà tàbí wúrà kúrò nínú ìwà asán yín, tí ẹ̀yin ti jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn baba yín.

19. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ iyebíye, bí i ti ọ̀dọ́-àgùntàn ti kò lábùkù, tí kò sì lábàwọ́n ani ẹ̀jẹ̀ Kírísítì.

20. Ẹni tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nítòótọ́ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, ṣùgbọ́n tí a fihàn ní ìgbà ìkẹ́yìn wọ̀nyí nítorí yín,

21. Àní ẹ̀yin tí o tipasẹ̀ rẹ̀ gba Ọlọ́run gbọ́, ẹni ti ó jí i dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì fi ògo fún un; kí ìgbàgbọ́ àti ìrétí yín lè wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

22. Níwọ̀n bí ẹ̀yin ti wẹ ọkàn yin mọ́ nípa ìgbọ́ràn yín sí òtítọ́ sí ìfẹ́ ará ti kò ní ẹ̀tàn, ẹ fẹ́ ọmọnikejì yín gidigidi láti ọkàn wá.

23. Bí a ti tún yín bí, kì í ṣe láti inú ìdíbàjẹ́ wá, bí kò ṣe èyí ti kì í díbàjẹ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń bẹ láàyè tí ó sì dúró.

24. Nítorí pé,“Gbogbo ènìyàn dàbí kóríko,àti gbogbo ògo rẹ̀ bi ìtànná koríko.Koríko á máa gbẹ ìtànná a sì máa rẹ̀ dànù,

25. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa dúró títí láé.”Ọ̀rọ̀ náà yìí sì ni ìyìn rere tí a wàásù fún yín.