orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Pétérù 2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nítorí náà, ẹ fi àrankan gbogbo sílẹ̀ ni apákan, àti ẹ̀tàn gbogbo, àti àgàbàgebè, àti ìlára, àti sísọ ọ̀rọ̀ buburú gbogbo.

2. Bí ọmọ ọwọ́ titun, kí ẹ máa fẹ́ wàrà ti Ẹ̀mí, èyí tí kò lẹ́tàn, kí ẹ̀yín lè máa tipasẹ̀ rẹ̀ dàgbà sí ìgbàlà.

3. nísinsìnyìí tí ẹ̀yín ti tọ́ ọ wò pé rere ni Olúwa

Àpáta Ìyè Àti Ènìyàn Tí A Yàn

4. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti tọ̀ ọ́ wá, òkúta ààyè náà, èyí ti àwọn ènìyàn kọ̀ sílẹ̀ ṣùgbọ́n tí Ọlọ́run yàn, òkúta iyebíye.

5. Ẹ̀yin pẹ̀lú, bí òkúta ààyè, ni a kọ́ ní ilé ẹ̀mí, àlùfáà mímọ́, láti máa rú ẹbọ ẹ̀mí, tí i ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípa Jésù Kírísítì.

6. Nítorí nínú ìwé mímọ́, ó wí pe:“Kìyèsi i, mo fi pàtàkì òkúta ìgún-ilẹ̀ àṣàyàn,iyebíye, lélẹ̀ ni Síónì:ẹni tí ó bá sì gbà á gbọ́ojú kì yóò tì í.”

7. Báyìí fún ẹ̀yin ti ẹ gbà á gbọ́, ó ṣe iyebíye; ṣùgbọ́n fún àwọn tí kò gbà á gbọ́,“Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀,òun ni ó di pàtàkì ìgún-ilé,”

8. àti pẹ̀lú,“Òkúta ìdìgbòlù,àti àpáta ìkọ̀sẹ̀.”Nítorí wọn kọsẹ̀ nípa ṣíṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, sínú èyí tí a gbé yàn wọ́n sí pẹ̀lú.

9. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni ìran tí a yàn Olu àlùfáà, Orílẹ̀ èdè mímọ́, ènìyàn ọ̀tọ̀ ki ẹ̀yin lè fi ọla ń lá ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn sínú ìmọ́lẹ̀ ìyanu rẹ̀ hàn:

10. Ẹ̀yin tí kì í ṣe ènìyàn nígbà kan rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ti di ènìyàn Ọlọ́run, ẹ̀yin tí kò rí àánú gbà rí, ṣùgbọ́n nísinsinyìí, ẹ ti rí àánú gbà.

11. Olùfẹ́ ọ̀wọ́n, mo bẹ̀ yín, bí àlejò àti èrò, láti fà sẹ́hìn kúrò nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, tí ń ba ọkàn jagun;

12. Kí ìwà yín láàrin àwọn aláìkọlà dára; pé, bí wọn ti ń sọ̀rọ̀ yín bí olùṣe búburú, nípa iṣẹ́ rere yín tí wọn ó máa kíyèsí, kí wọ́n lè máa yin Ọlọ́run lógo lọ́jọ́ ti òun ba bẹ̀ wá wò.

Ìbọ̀wọ̀ Fún Àwọn Òfin Àti Àwọn Aláṣẹ

13. Ẹ máa tẹríba fún gbogbo ìlànà ènìyàn nítorí ti Olúwa: ì bá à ṣe fún ọba, fún olórí.

14. Tàbí fún àwọn baálẹ̀, fún àwọn tí a rán láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ fún ìgbẹ̀san lára àwọn tí ń ṣe búburú, àti fún ìyìn àwọn tí ń ṣe rere.

15. Ìfẹ́ Ọlọ́run sá ni èyí pé, ní rere í ṣe, kí ẹ lè dẹ́kun ọ̀rọ̀ àìmọ̀kan òmùgọ̀ ènìyàn.

16. Ẹ máa gbé gẹ́gẹ́ bí ẹni òmìnira, ṣùgbọ́n ẹ maṣe lo òmìnira yín láti bo ibi mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n kí ẹ gbé gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run.

17. Ẹ bọ̀wọ̀ fún gbogbo ènìyàn, ẹ fẹ àwọn ará, ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ bọ̀wọ̀ fún ọba.

18. Ẹ̀yin ọmọ-ọdọ, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọ̀gá yín pẹ̀lú ìbẹ̀rù gbogbo, kì í ṣe fún àwọn ẹni rere àti oníwà tútù nìkan, ṣùgbọ́n fún àwọn òǹrorò pẹ̀lú.

19. Nítorí pé èyí ní ìgbóríyìn fún, bí ènìyàn bá fi oara da ìrora, ìjìyà lọ́nà àìtọ́, nítorí ọkàn rere sí Ọlọ́run.

20. Ṣùgbọ́n ògo kínni ó jẹ́, nígbà tí ẹ ba sẹ̀ tí a sì lù yín, bí ẹ bá fi sùúrù gbà á? Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá ń ṣe rere tí ẹ sì ń jìyà, bí ẹ bá fi sùúrù gbà á, èyí ní ìgbóríyìn-fún lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

21. Sí èyí ni a pè yín: nítorí Kírísítì pẹ̀lú jìyà fún-un yin, ó fi àpẹẹrẹ sílẹ̀ fún-un yín, kí ẹ̀yin lè máa tọ ipaṣẹ̀ rẹ̀:

22. “Òun kò dẹ́ṣẹ̀ kankan,bẹ́ẹ̀ sì ni, a kò rí ẹ̀tàn kan lẹ́nu rẹ̀”

23. Ẹni, nígbà tí a kẹ́gàn rẹ̀, tí kò sì padà kẹ́gàn; nígbà tí ó jìyà tí kò sì halẹ̀; ṣùgbọ́n ó fi ọ̀ràn rẹ̀ lé ẹni ti ń ṣe ìdájọ́ òdodo lọ́wọ́.

24. Ẹni tí òun tìkararẹ̀ fi ara rẹ̀ ru ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí igi, pé kí àwa lè di òkú sí ẹ̀ṣẹ̀ ki a sì di ààyè sí òdodo: nípa ìjìyà ẹni tí ó mú yín láradá.

25. Nítorí tí ẹ̀yin ń ṣáko lọ bí àgùntàn, ṣùgbọ́n nísinsinyìí ẹ̀yin ti padà sí ọ̀dọ̀ olùsọ́-àgùntàn àti bíṣọ́ọ̀bù ọkàn yín.