orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Pétérù 4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìgbé Ayé Fún Ọlọ́run

1. Ǹjẹ́ bí Kírísítì ti jìyà fún wa nípa ti ará, irú kan náà ni kí ẹ̀yin fi hámọ́ra; nítorí ẹni tí ó bá ti jìyà nípa ti ara, ó ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀;

2. Kí ẹ̀yin má ṣe fi ìgbà ayé yín ìyókù wà nínú ara mọ́ sí ìfẹ́kúfẹ ènìyàn bí kò ṣe sí ìfẹ́ Ọlọ́run.

3. Nítorí ìgbà tí ó ti kọjá ti tó fún ṣíṣe ìfẹ́ àwọn aláìkọlà, rìnrìn nínú ìwà wọ̀bìà, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ọtí àmupara, ìréde òru, kíkó ẹ̀gbẹ́ ọ̀mùtí, àti ìbọ̀rìṣà tí í ṣe ohun ìríra.

4. Èyí tí ó yà wọ́n lẹ́nu pé ẹ̀yin kò ba wọn súré sínú irú àṣejú ìwà wọ̀bìà wọ́n, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ yín ní búburú.

5. Àwọn ẹni tí yóò jíyìn fún ẹni tí ó ti múra láti ṣe ìdájọ́ alààyè àti òkú.

6. Nítorí èyí ní a ṣá ṣe wàásù ìyìn rere fún àwọn òkú, kí a lè ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn nípa ti ara, ṣùgbọ́n kí wọ́n lè wà láàyè si Ọlọ́run nípa tí Ẹ̀mí.

7. Ṣùgbọ́n òpin ohun gbogbo kù sí dẹ̀dẹ̀; nítorí náà kí ẹ̀yin wà ní àìrékọjá, kí ẹ sì máa sọra nínú àdúrà.

8. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ní ìfẹ́ tí ó gbóná láàrin ara yín: nítorí ìfẹ́ ni ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.

9. Ẹ máa ṣe ara yín ni àlejò láìsí ìkùnsínú.

10. Bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn gbà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa ṣe ìpín fún ni rẹ̀ láàrin ara yín, bí ìríjú rere tí oníruúrú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.

11. Bí ẹnikẹ́ni ba ń sọ̀rọ̀, kí o máa sọ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́, kí í ṣe é bí agbára tí Ọlọ́run fifún un, kí a lè máa yin Ọlọ́run lógo ní ohun gbogbo nípa Jésù Kírísítì, ẹni tí ògo àti ìjọba wà fún láé àti láéláé. (Àmín).

Jíjìyà Pé Ó Jẹ Onígbàgbọ́

12. Olùfẹ́, ẹ má ṣe ka ìdánwò gbígbóná ti ń bẹ láàrin yín láti dán yín wò bi ẹni pé ohun àjèjì ni ó dé bá yín:

13. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ̀yin tí jẹ́ alábàápín ìyà Kírísítì, ẹ máa yọ̀, kí ẹ̀yin lè yọ ayọ̀ púpọ̀ nígbà tí a bá fi ògo rẹ̀ hàn.

14. Bí a bá gàn yín nítorí orúkọ Kírísítì, ẹni ìbùkún ni yín: nítorí Ẹ̀mí Ògo àti ti Ọlọ́run bà lé yín (ní ọ̀dọ̀ tí wọn, wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ibi, ṣùgbọ́n ní ọ̀dọ̀ ti yín a yìn ín lógo.)

15. Ṣùgbọ́n ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín jìyà bí àpànìyàn, tàbí bí olè, tàbí bí olùṣé búburú, tàbí bí ẹni tí ń tọjúbọ̀ ọ̀ràn ẹlòmíràn.

16. Ṣùgbọ́n bí ó bá jìyà bí kírísítẹ́nì kí ojú má ṣe tì í: ṣùgbọ́n kí ó kúkú yin Ọlọ́run lógo ní orúkọ yìí.

17. Nítorí ti ìgbà náà dé, tí ìdájọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ láti ilé Ọlọ́run wá: bí ó bá sì tètè tí ọ̀dọ̀ wa bẹ̀rẹ̀, ìgbẹ̀hìn àwọn tí kò gba ìyìn rere Ọlọ́run yó ha ti rí?

18. “Bí ó bá ṣe pé agbára káká ni a fi gba olódodo là,níbo ni aláìwà-bí-Ọlọ́run àti ẹlẹ́sẹ̀ yóò gbe yọjú sí?”

19. Nítorí náà ẹ jẹ́ kí àwọn tí ń jìyà gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run máa ṣe rere, fi ọkàn wọn lè Ẹlẹ́dàá olóòtọ́ lọ́wọ́.