orí

  1. 1

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ọbadáyà 1 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìran ti Ọbadáyà. Èyí ni Olúwa Ọlọ́run wí nípa Édómù.Àwa ti gbọ́ ohùn kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá:A sì ti rán ikọ̀ kan sí gbogbo aláìkọlà láti sọ pé,“Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a dìde ogun sí i.”

2. “Kíyèsí i, Èmi yóò sọ ọ́ di kékeré láàrin àwọn aláìkọlà;ìwọ yóò sì di gígàn lọ́pọ̀lọpọ̀,

3. Ìgbéraga àyà rẹ ti tàn ọ́ jẹ,ìwọ tí ń gbé inú pálapàla àpáta,tí o sì kọ́ ibùgbé rẹ sí ibi gíga,ìwọ wí nínú ọkàn rẹ pé,‘Ta ni yóò mú mi sọ̀kalẹ̀?’

4. Bí ìwọ tilẹ̀ gbé ara rẹ ga bí ẹyẹ idì,Bí ìwọ tilẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ rẹ sí àárin àwọn ìràwọ̀,Láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti sọ̀ ọ kalẹ̀,”ni Olúwa wí.

5. “Bí àwọn olè tọ̀ ọ́ wá,Bí àwọn ọlọ́sà ní òru,Áà! Irú ìparun wo ló dúró dè ọ́:ṣé wọn kò jalè tó bí wọ́n ti fẹ́?Bí àwọn tí ń ká èso àjàrà tọ̀ ọ́ wá,ṣé wọn kò ni fi èésẹ́ èso àjàrà díẹ̀ sílẹ̀?

6. Báwo ni a ṣe se àwárí nǹkan Ísọ̀tí a sì wá ohun ìní ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ jáde

7. Gbogbo àwọn ẹni ìmùlẹ̀ rẹti mú ọ dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ rẹ:Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì ti borí rẹ;àwọn tó jẹ oúnjẹ rẹ dẹ pàkúté dè ọ́,ṣùgbọ́n ìwọ kò ní ní òye rẹ̀.”

8. Olúwa wí pé, “Ní ọjọ́ náà,Èmi yóò pa àwọn ọlọ́gbọ́n Édómù run,àti àwọn amòye run kúrò ní òkè Ísọ̀?

9. A ó ṣe ẹ̀rù ba àwọn jagunjagun rẹ, Ìwọ Témánì,gbogbo àwọn tó wà ní orí òkè Ísọ̀ní a ó gé kúrò nínú ìpànìyàn náà.

10. Nítorí ìwà ipá sí Jákọ́bù arákùnrin rẹ,ìtìjú yóò bò ọ,a ó sì pa ọ run títí láé.

11. Ní ọjọ́ tí ìwọ dúró ní apákan,ní ọjọ́ tí àlejò kó ogún rẹ lọ,tí àwọn àjèjì sì wọ ibodè rẹtí wọ́n sì sẹ́ kèké lórí Jérúsálẹ́mù,ìwọ náà wà bí ọ̀kan nínú wọn.

12. Ìwọ kì bá tí fi ojú kéré arákùnrin rẹ,ní àkókò ìbànújẹ́ rẹ̀ìwọ kì bá tí yọ̀ lórí àwọn ọmọ Júdà,ní ọjọ́ ìparun wọnìwọ kì bá tí gbéraga púpọ̀ní ọjọ́ wàhálà wọn.

13. Ìwọ kì bá tí wọ inú ibodè àwọn ènìyàn mi lọ,ní ọjọ́ àjálù wọn.Ìwọ kì bá tí fojú kó wọn mọ́lẹ̀nínu ìdàmú wọn, ní ọjọ́ àjálù wọn.Ìwọ kì bá tí jí ẹrù wọn kó,ní ọjọ́ ìpọ́njú wọn.

14. Ìwọ kì bá tí dúró ní ìkóríta ọ̀nàláti ké àwọn tirẹ̀ tó ti sálà kúrò.Ìwọ kì bá tí fa àwọn tó sẹ́kùwọn lélẹ̀ ní ọjọ́ wàhálà wọn.

15. “Nítorí ọjọ́ Olúwa súnmọ́ etílélórí gbogbo àwọn aláìkọlà.Bí ìwọ ti se, bẹ́ẹ̀ ni a ó se sí ìwọ náà;ẹ̀san rẹ yóò sì yípadà sí orí ara rẹ.

16. Gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀ se mu lórí òkè mímọ́ miBẹ́ẹ̀ ni gbogbo aláìkọlà yóò máa mu títíWọn yóò mu wọn yóò sì gbémìWọn yóò sì wà bí ẹni pé wọn kò wà rí

17. Ṣùgbọ́n ìgbàlà yóò wà lórí òkè SíónìWọn yóò sì jẹ́ mímọ́àti ilé Jákọ́bù yóò sì ní ìní wọn

18. Ilé Jákọ́bù yóò sì jẹ́ ináàti ilé Jósẹ́fù ọwọ́ ináilé Ísọ̀ yóò jẹ àkékù koríkowọn yóò fi iná sí i,wọn yóò jo run.Kì yóò sí ẹni tí yóò kù ní ilé Ísọ̀.”Nítorí Olúwa ti wí i.

19. Àwọn ará Gúsù yóò ni òkè Ísọ̀,àwọn ará ẹsẹ̀ òkè yóò niilẹ̀ àwọn ará Fílísítíánì ní ìní.Wọn yóò sì ni oko Éfúráímù àti Samáríà;Bẹ́ńjámínì yóò ní Gílíádì ní ìní.

20. Àwọn ìgbèkùn Ísírẹ́lì tí ó wà níKénánì yóò ni ilẹ̀ títí dé Séréfátì;àwọn ìgbékùn láti Jérúsálẹ́mùtí ó wà ní Séfárádìyóò ni àwọn ìlú Gúsù ní ìní

21. Àwọn olùgbàlà yóò sì gòkè Síónì wáláti jọba lé orí àwọn òkè Ísọ̀.Ìjọba náà yóò sì jẹ́ ti Olúwa.