Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 28:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè pé,

2. “Fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní òfin yìí kí o sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ rí i wí pé ẹ gbé e wá sí iwájú mi ní àkókò tí a ti yàn, oúnjẹ ọrẹ ẹbọ mi tí a fi iná ṣe sí mi, gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí mi.’

3. Sọ fún wọn, ‘Èyí ní ọrẹ ẹbọ tí a fi iná sun tí ẹ gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa: akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méjì ọlọ́dún kan aláìlábàwọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ọrẹ sísun ní ojojúmọ́.

4. Pèsè ọ̀dọ́ àgùntàn kan ní òwúrọ̀ àti òmíràn ní àfẹ̀mọ́júmọ́.

5. Pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ tí ó jẹ́ ìdámẹ́wàá éfà ìyẹ̀fun dáradára tí a pò pọ̀ mọ́ ìdámẹ́rin hínì òróró tí a yọ lára Ólífì.

6. Èyí ni ẹbọ sísun gbogbo ìgbà tí a fi lẹ́lẹ̀ ní òkè Sínáì gẹ́gẹ́ bí olóòrùn dídùn ẹbọ tí a fi iná sun fún Olúwa pẹ̀lú iná.

7. Àfikún ọrẹ ohun mímu rẹ gbọdọ̀ jẹ́ ìdámẹ́rin ti hínì dídé omi mímu tí ó kan pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́ àgùntàn. Da ẹbọ mímu náà síta sí Olúwa ní ibi mímọ́.

8. Pèsè ọ̀dọ́ àgùntàn kejì ní àfẹ̀mọ̀júmọ́, pẹ̀lú oríṣìí ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu èyí tí ó pèsè ní òwúrọ̀, èyí ni ẹbọ tí a fi iná ṣe, olóòrùn dídùn sí Olúwa.

9. “ ‘Ní ọjọ́ ìsinmi, pèsè akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méjì olọ́dún kan tí kò lábùkù, pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu àti ẹbọ ohun jíjẹ tí i ṣe ìdá méjì nínú ìdámẹ́wàá òṣùwọn ìyèfun ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò.

10. Èyí ni ẹbọ sísun fún gbogbo ọjọ́ ìsinmi kọ̀ọ̀kan, ní àfikún pẹ̀lú ẹbọ sísun àti ẹbọ ohun mímu.

11. “ ‘Àti ní ọjọ́ tí o bẹ̀rẹ̀ oṣù kọ̀ọ̀kan, kí ẹ̀yin kí ó gbé ẹbọ sísun fún Olúwa pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù méjì, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, kí gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ aláìlábùkù.

12. Pẹ̀lú akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ni kí wọn ó rú ẹbọ ohun jíjẹ ẹbọ ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá ìyẹ̀fun tí a pòpọ̀ pẹ̀lú òróró; pẹ̀lú àgbò, ni kí wọn ó rú ẹbọ ohun jíjẹ tí í ṣe ìdáméjì nínú mẹ́wá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun tí a pòpọ̀ mọ́ òróró;

13. pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́ àgùntàn, ni kí ẹ rú ẹbọ ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúnná tí a pò pọ̀ mọ́ òróró. Èyí ni ẹbọ sísun, òórùn dídùn, àti ẹbọ tí a ṣe fún Olúwa pẹ̀lú iná.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 28