Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Málákì 2:5-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. “Májẹ̀mu mi wà pẹ̀lú rẹ̀, májẹ̀mu ti ìyè àti àlàáfíà wà pẹ̀lú rẹ̀; mo sì fi wọn fún un, nítorí bíbẹ̀rù tí ó bẹ̀rù mi, tí ẹ̀rù orúkọ mi sì bà á.

6. Òfin òtítọ́ wà ni ẹnu rẹ̀, a kò sì rí irọ́ ni ètè rẹ̀: ó ba mi rìn ní àlàáfíà àti ni ídúró ṣinṣin, ó sì yí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.

7. “Nítorí ètè àlùfáà ní a ti máa pa ìmọ̀ mọ́, kí àwọn ènìyàn lè máa wá ìtọ́ni ni ẹnu rẹ̀: nítorí òun ni iransẹ Olúwa àwọn ọmọ ogun.

8. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yapa kúrò ní ọ̀nà náà; ẹ̀yin sì ti fi ìkọ́ni yín mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kọsẹ̀; ẹ̀yin ti ba májẹ̀mú tí mo da pẹ̀lú Léfì jẹ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.

9. “Nítorí náà ni èmi pẹ̀lú ṣe sọ yín di ẹ̀gàn, àti ẹni àìkàsí níwájú gbogbo ènìyàn, nítorí ẹ̀yin kò tẹ̀lé ọ̀nà mi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń ṣe ojúṣàájú nínú òfin.”

10. Baba kan náà kí gbogbo wa ha ní? Ọlọ́run kan náà kọ́ ni ó dá wa bí? Nítorí kín ni àwa ha ṣe sọ májẹ̀mú àwọn baba wa di aláìmọ nípa híhùwà àrékérekè olúkulùkù sí arákùnrin rẹ̀?

11. Júdà ti ń hùwà àrékérekè, a sì ti hùwà ìríra ní Ísírẹ́lì àti ni Jérúsálẹ́mù: nítorí Júdà tí ṣe eyi ti ó lè sọ ibi mímọ́ Olúwa di aláìmọ́ nípa gbígbé ọmọbìnrin ọlọ́run àjèjì ni ìyàwó.

12. Ní ti ẹni tí ó se èyí, ẹni tí ó wù kí ó jẹ, kí Olúwa kí ó gé e kúrò nínú àgọ́ Jákọ́bù, bí ó tilẹ̀ mú ẹbọ ọrẹ wá fún Olúwa àwọn ọmọ ogun.

13. Èyí ni ohun mìíràn tí ẹ̀yin sì tún ṣe: Ẹ̀yin fi omijé bo pẹpẹ Olúwa mọ́lẹ̀. Ẹ̀yín sọkún, ẹ̀yín sì ba ara jẹ́ nítorí tì Òun kò ka ọrẹ yín sí mọ́, tàbí kí ó fi inú dídùn gba nǹkan yìí lọ́wọ́ yín.

14. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, “Nítorí kín ní?” Nítorí Olúwa ti ṣe ẹlẹ́rìí láàrin ìwọ àti láàrin aya èwe rẹ, ẹni tí ìwọ ti ń hùwà ẹ̀tàn síi: bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkeji rẹ ni òun jẹ́, àti aya májẹ̀mú rẹ.

15. Ọlọ́run kò hà ti ṣe wọ́n ní ọ̀kan? Ni ara àti ni ẹ̀mí tirẹ̀ ni. Èéṣe tí Ọlọ́run da yín l'ọ́kàn? Kí òun bá à lè wá irú ọmọ bí ti Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹ tọ́jú ẹ̀mí yín, ẹ má sì ṣe hùwà ẹ̀tàn sí aya èwe yín;

16. “Mo kórìíra ìkọ̀sílẹ̀,” ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, “bẹ́ẹ̀ ni mo kóríra kí èníyàn máa fi ipá bó ara rẹ̀ àti pẹ̀lú asọ rẹ̀,” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.Nítorí náà ẹ sọ́ ẹ̀mí yín, kí ẹ má se hùwà ẹ̀tàn.

17. Ẹ̀yin ti fi ọ̀rọ̀ yin dá Olúwa ní agara.Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèré pé, “Nínú kín ni àwa fi dá a lágara?”Nígbà tí ẹ̀yìn wí pé, “Gbogbo ẹni tí ó ṣe ibi, rere ni níwájú Olúwa, inú rẹ̀ sì dùn sí wọn,” tabi “Níbo ni Ọlọ́run ìdájọ́ gbé wà?”

Ka pipe ipin Málákì 2