Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 8:19-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Bí ó ti ṣe èyí tán, àwọn ọkùnrin tí ó ba sì dìde kánkán kúrò ní ipò wọn, wọ́n sáré ṣíwájú. Wọn wọ ìlú náà, wọ́n gbà á, wọ́n sì yára ti iná bọ̀ ọ́.

20. Àwọn ọkùnrin Áì bojú wo ẹ̀yìn, wọ́n rí èéfín ìlú náà ń gòkè lọ sí ọ̀run, ṣùgbọ́n wọn kò rí, àyè láti sá àsálà lọ sí ibìkan kan, nítorí tí àwọn ará Ísírẹ́lì tí wọ́n tí ń sálọ sí ihà ti yípadà sí àwọn tí ń lépa wọn.

21. Nígbà tí Jóṣúà àti gbogbo àwọn ará Ísírẹ́lì rí i pé àwọn tí ó ba ti gba ìlú náà, tí èéfín ìlú náà sì ń gòkè, wọ́n yí padà wọ́n sì kọlu àwọn ọkùnrin Áì.

22. Àwọn ọmọ ogun tí ó ba náà sì yípadà sí wọn láti inú ìlú náà, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wà ní agbede-méjì àwọn ará Ísírẹ́lì ní ìhà méjèèjì. Ísírẹ́lì sì pa wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì jẹ́ kí ọ̀kan kí ó yè tàbí kí ó ṣálọ nínú un wọn.

23. Ṣùgbọ́n wọ́n mú ọba Áì láàyè, wọ́n sì mu-un tọ Jósúà wá.

24. Nígbà tí Ísírẹ́lì parí pípa àwọn ọkùnrin Áì ní pápá àti ní ihà ní ibi tí wọ́n ti lépa wọn lọ, nígbà tí wọ́n pa gbogbo wọn tan, gbogbo àwọn Ísírẹ̀lì sì padà sí Áì, wọ́n sì pa àwọn tí ó ṣẹ́kù síbẹ̀.

25. Ẹgbẹ̀rún méjìlá ọkùnrin àti obìnrin ni ó kú ní ọjọ́ náà-gbogbo wọn jẹ́ àwọn ènìyàn Áì.

26. Nítorí tí Jósúà kò fa ọwọ́ ọ rẹ̀ tí ó di ọ̀kọ̀ mú sí ẹ̀yìn, títí ó fi pa gbogbo àwọn tí ń gbé ìlú Áì run.

27. Ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì kó ẹran ọ̀sìn àti ìkógún ti ìlú yìí fún ara wọn, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Jóṣúà.

28. Jóṣúà sì jó Áì, ó sì sọ ọ́ di ààtàn, àní ahoro di òní yìí.

29. Ó sì gbé ọba Áì kọ́ orí igi, ó sì fi kalẹ̀ síbẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́. Bí òòrùn sì ti wọ̀ ni Jóṣúà pàṣẹ fún wọn láti sọ òkú rẹ̀ kalẹ̀ kúrò ní orí igi, kí wọn sì wọ́ ọ jù sí àtiwọ ẹnu ibodè ìlú náà. Wọ́n sì kó òkítì òkúta ńlá lé e ní orí, èyí tí ó wà títí di òní yìí.

30. Nígbà náà ni Jóṣúà mọ pẹpẹ kan fún Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ní òkè Ébálì,

31. gẹ́gẹ́ bí Móṣè ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ó sì kọ́ ọ́ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ nínú Iwé Òfin Móṣè, pẹpẹ odindi òkúta, èyí tí ẹnìkan kò fi ohun èlò irin kàn rí. Wọ́n sì rú ọrẹ ẹbo ṣísun àti ọrẹ àlàáfíà ní orí i rẹ̀ sí Olúwa.

32. Níbẹ̀ ní ojú àwọn ará Ísírẹ́lì, Jósúà sì ṣe àdàkọ òfin Mósè èyí tí ó ti kọ sí ara òkúta náà.

33. Gbogbo Ísírẹ́lì, àlejò àti ọmọ ìlú, pẹ̀lú àwọn àgbà, olórí àti onídàájọ́ dúró ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì àpótí ẹ̀rí Olúwa tí ó kọjú sí àwọn àlùfáà tí ó rù ú, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì. Ìdajì àwọn ènìyàn náà dúró ní Òkè Gérísímù, àwọn ìdajì si dúró ni òkè Ébálì, gẹ́gẹ́ bí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ rí, pé kí wọn súre fún àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì.

Ka pipe ipin Jóṣúà 8