orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóẹ́lì 1 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jóẹ́lì ọmọ Pétúélì wá.

Ìsígun Eṣú

2. Ẹ gbọ́ èyí ẹ̀yin àgbààgbà;ẹ fi etí sílẹ̀ gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ará ilẹ̀ náà.Ǹjẹ́ irú èyí ha wà ní ọjọ́ yín,tàbí ní ọjọ́ àwọn baba yín?

3. Ẹ sọ ọ́ fún àwọn ọmọ yín,ki àwọn ọmọ yín sọ fún àwọn ọmọ wọn,ki àwọn ọmọ wọn sọ fún àwọn ìran mìíràn.

4. Èyí tí eṣú tí agénijẹ jẹ kùní ọ̀wọ́ eṣú jẹÈyí tí ọ̀wọ́ eṣú jẹ kùní eṣú tata jẹÈyí tí eṣú tata jẹ kùni eṣú apanirun mìíràn jẹ

5. Ẹ jí gbogbo ẹ̀yín ọ̀mùtí kí ẹ sì ṣunkúnẹ pohùnréré ẹkún gbogbo ẹ̀yinọ̀mu-wáìnì; ẹ pohùnréré ẹkún nítorí wáìnì tuntunnítorí a gbà á kúrò lẹ́nu yín.

6. Nítorí orílẹ̀ èdè kan ti sígun sí ilẹ̀ mìírànó ní agbára púpọ̀, kò sì ní òǹkà;ó ní eyín kìnnìúnó sì ní èrìgì abo kìnnìún.

7. Ó ti pa àjàrà mi run,ó sì ti ya ẹ̀ka igi ọ̀pọ̀tọ́ mi kúrò,ó ti bò èèpo rẹ̀ jálẹ̀, ó sì sọ ọ́ nù;àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ni a sì sọ di fun-fun.

8. Ẹ pohùnréré ẹkún bí wúndíátí a fi aṣọ ọ̀fọ̀ dí ni àmúre, nítorí ọkọ ìgbà èwe rẹ̀.

9. A ké ọrẹ jíjẹ́ àti ọrẹ mímú kúròní ilé Olúwa;àwọn àlùfáà ń ṣọ̀fọ̀, àwọnìrànṣẹ́ Olúwa,

10. Oko di ìgboro, ilẹ̀ ń sọ̀fọ̀ nítorí,a fi ọkà ṣòfò:ọtí wáìnì tuntún gbé, òróró ń bùṣe.

11. Kí ojú kí ó tì yín, ẹ̀yin àgbẹ̀;ẹ pohùn réré ẹkún ẹ̀yin olùtọ́jú àjàrà,nítorí àlìkámà àti nítorí ọkà báálì;nítorí ìkórè oko ṣègbé.

12. Àjàrà gbẹ, igi ọ̀pọ̀tọ́ sì rọ̀ dànù;igi pómégánátì, igi ọ̀pẹ pẹ̀lú,àti igi ápíílì, gbogbo igi igbó ni o rọ:Nítorí náà ayọ̀ ọmọ ènìyàn gbẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn

Ìpè Fún Ìrònúpìwàdà

13. Ẹ di ara yín ni àmùrè,sí pohùn réré ẹkún ẹyín àlùfáà:ẹ pohùn réré ẹkún, ẹyín ìránṣẹ́ pẹpẹ:ẹ wá, fi gbogbo òru dùbúlẹ̀ nínú aṣọ ọ̀fọ̀,ẹ̀yin ìrànsẹ́ Ọlọ́run mi: nítorí tí a dá ọrẹ jíjẹ àti ọrẹmímú dúró ní ilé Ọlọ́run un yín.

14. Ẹ yà ààwẹ̀ kan sí mímọ́,ẹ pe àjọ kan tí o ní ìrònú,ẹ pe àwọn àgbà,àti gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náàjọ sí ilé Olúwa Ọlọ́run yín,kí ẹ sí képe Olúwa

15. A! Fún ọjọ́ náà,nítorí ọjọ́ Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀,yóò de bí ìparun láti ọwọ́ Olódùmare.

16. A kò ha ké oúnjẹ kúrò níwájúojú wá yìí,ayọ̀ àti inú dídùn kúrò nínú iléỌlọ́run wá?

17. Irúgbìn bàjẹ́ nínú ebè wọn,a sọ àká di ahoro, a wó àká palẹ̀;nítorí tí a mú ọkà rọ.

18. Àwọn ẹranko tí ń kerora tó!Àwọn agbo ẹran dààmú,nítorí tí wọ́n kò ni pápá oko;nítòótọ́, àwọn agbo àgùntàn jìyà.

19. Olúwa, sí ọ ni èmi o ké pè,nítorí iná tí run pápa oko tútú ihà,ọwọ́ iná sí ti jó gbogbo igi igbó.

20. Àwọn ẹranko igbó gbé ojú sókè sí ọ pẹ̀lú:nítorí tí àwọn iṣàn omi gbẹ,iná sí ti jó àwọn pápá oko ihà run.