orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50
  51. 51
  52. 52

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èyí ní ohun tí Olúwa wí: “Lọ ra ìkòkò lọ́dọ̀ alámọ̀, mú dání lára àwọn àgbààgbà ọkùnrin àti wòlíì.

2. Hó sí àfonífojì Bẹni Hínínónì, nítòsí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé pótísẹ́dì níbẹ̀ sì ni kí o kéde ọ̀rọ̀ tí mo bá ọ sọ.

3. Kí o sì wí pé ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin Ọba àwọn Júdà àti ẹ̀yin ará Jérúsálẹ́mù. Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ. Dẹtí sí mi! Èmi yóò mú ìparun wá síbí, etí gbogbo wọn tó bá gbọ́ ọ yóò hó yaya.

4. Nítorí wọ́n ti gbàgbé mi, wọ́n sì ti sọ ibí di ilé fún òrìṣà àjòjì; wọ́n ti sun ẹbọ nínú rẹ̀ fún òrìṣà tí àwọn baba wọn tàbí tí Ọba Júdà kò mọ̀ rí, wọ́n ti fi ẹ̀jẹ̀ aláìsẹ̀ kún ilẹ̀ yìí.

5. Wọ́n ti kọ́ ibi gíga fún Báálì láti sun ọmọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí ohun ẹbọ sí Báálì. Nǹkan ni èmi kò pa láṣẹ tàbí dárúkọ tí kò sì wá láti inú ọkàn mi.

6. Nítorí náà sọ́ra ọjọ́ ń bọ̀ ni Olúwa wí nígbà tí àwọn ènìyàn tí a kì yóò pe ibí ní Tófẹ́tì tàbí ọmọ Hininómù, ṣùgbọ́n Àfonífojì ìpakúpa.

7. “ ‘Ní ibí yìí ni èmi yóò ti pa èrò Júdà àti Jérúsálẹ́mù run. Èmí yóò mú wọn ṣubú nípa idà níwájú àwọn ọ̀tá wọn, lọ́wọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mi wọn. Èmi yóò sì fi òkú wọn ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀.

8. Èmi yóò sọ ìlú yìí di ahoro àti ohun ẹ̀gàn, gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò bẹ̀rù wọn yóò sì máa fòyà nítorí gbogbo ọgbẹ́ rẹ̀.

9. Èmi yóò mú kí wọn jẹ ẹran ara ọmọ wọn ọkùnrin àti obìnrin, wọn yóò sì jẹ ẹran ara wọn lásìkò ìparun wọn láti ọwọ́ ọ̀tá wọn, tí ó ń wá ẹ̀mí wọn.’

10. “Nígbà náà ni ìwọ yóò fọ́ ìkòkò náà ní oju àwọn tí ó bá ọ lọ.

11. Kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun wí. Èmi a fọ́ orílẹ̀ èdè yìí àti ìlú yìí gẹ́gẹ́ bí ìkòkò amọ̀ yìí ṣe fọ́ tí kò sì ní sí àtúnṣe. Wọn a sì sin àwọn òkú sí Tófẹ́tì títí tí kò fi ní sí àyè mọ́.

12. Èyí ni ohun tí èmi yóò ṣe sí ibí yìí àti àwọn tí ń gbé ní ibí yìí ni Olúwa wí. Èmi yóò mú ìlú yìí dàbí Tófẹ́tì.

13. Àwọn ilé tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù àti ti Ọba ìlú Júdà ni a ó sọ di àìmọ́ gẹ́gẹ́ bí ti ibí yìí ní Tófẹ́tì gbogbo ilé tí wọ́n ti ń sun tùràrí ni orí àjà sí gbogbo ènìyàn tí ó sì ń da ọtí gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí Ọlọ́run mìíràn.’ ”

14. Jeremáyà sì padà láti Tófẹ́tì níbi tí Olúwa rán an sí láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ó sì dúró ní gbangba Tẹ́ḿpìlì Olúwa, ó sì sọ fún gbogbo ènìyàn pé,

15. “Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísíẹ́lì wí: ‘Tẹ́tí sílẹ̀! Èmi yóò mú ìdààmú tí mo ti sọ àṣọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ bá ìlú yìí àti ìgbéríko tí ó yí i ká, nítorí ọlọ́rùn líle ni wọ́n, wọn kò si ní fẹ́ fetí sí ọ̀rọ̀ mi.’ ”