orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sírà 9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àdúrà Ẹ́sírà Nípa Ìgbéyàwó Pẹ̀lú Àwọn Àjòjì

1. Lẹ́yìn ìgbà tí a ti ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tán, àwọn olórí tọ̀ mí wá wọ́n sì wí pé, Àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì, ti ó fi mọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, kò tì í ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò láàrin àwọn ènìyàn agbègbè tí wọ́n ń ṣe ohun ìríra bí i ti àwọn ọmọ Kénánì, Hítì, Pérísì, Jébúsì, Ámónì, Móábù Éjíbítì àti Ámórì.

2. Wọ́n ti fẹ́ lára àwọn ọmọbìnrin wọn fún ara wọn àti fún àwọn ọmọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí aya, wọ́n ti da ìran mímọ́ pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn ti ó wà ní àyíká wọn. Àwọn olórí àti àwọn ìjòyè ta àwọn ènìyàn tó kù yọ nínú hihu ìwà “Àìsòótọ́.”

3. Nígbà tí mo gbọ́ èyí, mo fa àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti agbádá mi ya, mo ja irun orí àti irungbọ̀n mi, mo sì jókòó ní ìbànújẹ́.

4. Nígbà náà ni gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ísírẹ́lì kó ara wọn jọ yí mi ká nítorí àìsòótọ́ àwọn ìgbékùn yìí. Èmi sì jókòó níbẹ̀ ní ìbànújẹ́ títí di àkókò ìrúbọ àṣálẹ̀.

5. Ní ìgbà tí o di àkókò ìrúbọ àṣálẹ̀, mo dìde kúrò nínú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn mi, pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti agbádá mi yíya ní ọrùn mi, mo kúnlẹ̀ lórí eékún mi méjèèjì, mo sì tẹ́ ọwọ́ mi méjèèjì sí Olúwa Ọlọ́run mi.

6. Mo sì gbàdúrà:Ọlọ́run mi, ojú tì mí gidigidi kò sì yá mi lórí láti gbé ojú mi sókè sí ọ, Ọlọ́run mi, nítorí ẹṣẹ̀ wá ga ju orí wa lọ, àwọn àìṣedéédéé wa sì ga kan àwọn ọ̀run.

7. Láti ìgbà àwọn baba wá, títí di ìsinsin yìí, àìṣedéédéé wa ti pọ̀ jọjọ. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, àwa àti àwọn ọba wa àti àwọn àlùfáà wa ni a ti sọ di ẹni idà àti ìgbèkùn, ìkógun àti ẹni ẹ̀ṣín lọ́wọ́ àwọn àjèjì ọba, bí ó ti rí lónìí.

8. Ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí, fún ìgbà díẹ̀, Olúwa Ọlọ́run ti fi àánú rẹ̀ dá àwa tí ó sẹ́kù sí tí ó sì fún wa ni ibi pàtàkì nínú ibi mímọ́ rẹ̀, nítorí náà Ọlọ́run wa ti fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú wa àti ìgbé ayé túntún kúrò nínú ìgbékùn wa.

9. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa jẹ́ ẹrú, Ọlọ́run wa kò fi wa sílẹ̀ nínú ìgbèkùn wa. Ó ti fi àánú hàn fún wa ni iwájú àwọn ọba Páṣíà: Ó ti fún wa ní ìgbé ayé tuntún láti tún odi ilé Ọlọ́run wa mọ, kí a sì tún àwókù rẹ̀ mọ, ó sì fi odi ààbò fún wa ní Júdà àti Jérúsálẹ́mù.

10. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, kí ni àwa yóò wí lẹ́yìn èyí? Ìwọ Ọlọ́run wa, nítorí tí àwa kò pa àṣẹ rẹ mọ́

11. èyí tí ìwọ fún wa láti ipaṣẹ̀ àwọn wòlíì ìrànṣẹ rẹ, nígbà ti ìwọ wí pé ilẹ̀ ti ẹ̀yin ń wọ̀ lọ láti lọ gbà jẹ́ ilẹ̀ tí ó di àìmọ̀ pẹ̀lú ìwà ìbàjẹ́ àwọn ènìyàn rẹ, nípa ṣíṣe ohun ìríra ilẹ̀ náà ti kún fún ohun àìmọ́ láti igun kan dé ìkejì.

12. Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn ọmọbìnrin yín fún àwọn ọmọkùnrin wọn ní ìyàwó tàbí kí ẹ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín ní ìyàwó. Ẹ má ṣe dá májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú wọn nígbà-kí-gbà kí ẹ̀yin kí ó sì le lágbára, kí ẹ sì jẹ ohun dáradára ilẹ̀ náà, kí ẹ sì fi sílẹ̀ fún àwọn ọmọ yín gẹ́gẹ́ bí ogún ayé rayé;

13. Ohun tí ó ti sẹlẹ̀ sí wa jẹ́ ayọrísí iṣẹ́ búburú wa àti ẹ̀bi-ẹ̀ṣẹ̀ ńlá wa, ṣíbẹ̀, Ọlọ́run wa, ìjìyà ti ìwọ fún wa kéré si ìjìyà tí ó yẹ fún ẹ̀ṣẹ̀ ti a dá, ìwọ sì fún wa ní àwọn ènìyàn tó sẹ́kù bí èyí.

14. Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwa tún yẹ̀ kúrò nínú àṣẹ rẹ, kí a sì máa ṣe ìgbéyàwó papọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọn ti ṣe onírúurú ohun ìríra báyìí? Ṣe ìwọ kò ní bínú sí wa láti pa wá run tí kì yóò sẹ́ ku ẹnìkẹ́ni tí yóò là?

15. Ìwọ Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ìwọ jẹ́ olódodo O dá wa sí lónìí bí àwọn tí ó ṣẹ́kà. Àwa nìyí níwájú rẹ nínú ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nítorí rẹ̀ ẹyọ ẹnìkan kò lè dúró níwájú rẹ.