orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sírà 5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Lẹ́tà Táténáì sí Dáríúsì

1. Nígbà náà wòlíì Hágáì àti wòlíì Ṣekaráyà, láti ìrán Ìdó, sọ àṣọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ará Júù ní Júdà àti Jérúsálẹ́mù ní orúkọ Ọlọ́run Ísírẹ́lì tí ẹ̀mí rẹ̀ ń bẹ lára wọn.

2. Nígbà náà Ṣerubábélì ọmọ Ṣéálítíélì àti Jéṣúà ọmọ Jóṣádákì gbáradì fún iṣẹ́ àti tún ilé Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù kọ́. Àwọn wòlíì Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú wọn, tí wọ́n ń ràn wọ́n lọ́wọ́.

3. Ní àkókò náà Táténáì, Baálẹ̀ ti agbègbè Yúfúrátè àti Ṣétarì-Bóṣénáì àti àwọn ẹgbẹ́gbẹ́ wọn lọ sí ọ̀dọ̀ wọn Wọ́n sì béèrè pé, “Ta ni ó fún un yín ní àṣẹ láti tún tẹ́ḿpìlì yìí kọ́ àti láti tún odi yìí mọ?”

4. Wọ́n sì tún béèrè pé, “Kí ni orúkọ àwọn ọkùnrin tí ó ń kọ́ ilé yìí?”

5. Ṣùgbọ́n ojú Ọlọ́run wọn wà lára àwọn àgbààgbà Júù, wọn kò sì dá wọn dúró tí tí ìròyìn yóò fi dè ọ̀dọ̀ Dáríúsì kí wọ́n sì gba èsì tí à kọ sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.

6. Èyí ni ẹ̀dà lẹ́tà tí Tétanáì, olórí agbégbé Yúfúrátè àti Ṣétarì-Bóṣénáì àti àwọn ẹlẹ́gbẹ́ ẹ wọn. Àwọn olóyè ti agbégbé Yúfúrátè, fi ránṣẹ́ sí ọba Dáríúsì.

7. Ìròyìn tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí i kà báyìí pé:Sí ọba Dáríúsì:Àlàáfíà fún un yín.

8. Kí ọba kí ó mọ̀ pé a lọ sí ẹ̀kún Júdà, sí tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run alágbára. Àwọn ènìyàn náà ń kọ́ ọ pẹ̀lú àwọn òkúta ńlá ńlá àti pẹ̀lú fífi àwọn igi sí ara ògiri. Wọ́n ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú àìsinmi, ó sì ń ní ìtẹ̀ṣíwájú kíákíá lábẹ́ ìṣàkóso wọn.

9. A bi àwọn àgbààgbà, a sì fi ọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò pé, “Ta ni ó fún un yín ní àṣẹ láti tún ilé Olúwa yìí kọ́ àti láti tún odi rẹ̀ mọ?”

10. A sì tún bèèrè orúkọ wọn pẹ̀lú, kí a lè kọ àwọn orúkọ àwọn olórí wọn silẹ̀ kí ẹ ba à le mọ ọ́n.

11. Èyí ni ìdáhùn tí wọ́n fún wa:Àwa ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, àwa sì ń tún tẹ́ḿpìlì ilé Olúwa tí a ti kọ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn kọ́, èyí tí ọba olókìkí kan ní Ísírẹ́lì kọ́, tí ó sì parí i rẹ̀.

12. Ṣùgbọ́n nítorí tí àwọn baba wa mú Ọlọ́run ọ̀run bínú, ó fi wọ́n lé Nebukadinésárì ti Kálídéà, ọba Bábílónì lọ́wọ́, ẹni tí ó run tẹ́ḿpìlì Olúwa yìí tí ó sì kó àwọn ènìyàn náà padà sí Bábílónì.

13. Ṣùgbọ́n ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba Ṣáírúsì ọba Bábílónì, ọba Ṣáírúsì pàṣẹ pé kí a tún ilé Ọlọ́run yìí kọ́.

14. Kí àwọn ènìyàn ní ibikíbi tí ẹni tí ó lọ bá ń gbé kí ó fi fàdákà àti wúrà pẹ̀lú ohun tí ó dára àti ẹran-ọ̀sìn pẹ̀lú ọrẹ àtinúwá ràn-án lọ́wọ́ fún tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù. Kí wọn sì mú wá sí tẹ́ḿpílì ní BábílónìNígbà náà ọba Sáírúsì kó wọn fún ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Ṣesibásárì, ẹni tí ó ti yàn gẹ́gẹ́ bí i Baálẹ̀,

15. ó sì sọ fún un pé, “Kó àwọn ohun èlò yìí kí o lọ, kí o sì kó wọn sí inú ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù, pẹ̀lú kí ẹ sì tún ilé Ọlọ́run kọ́ sí ipò o rẹ̀.”

16. Nígbà náà ni Ṣesibásásárì náà wá, ó sí fi ìpìlẹ̀ ilé Ọlọ́run tí ó wá ní Jérúsálẹ́mù lẹ́lẹ̀, láti ìgbà náà àní títí di ìsínsìn yìí ni o ti n bẹ ní kíkọ́ ṣùgbọ́n, kò sí tí ì parí tán.

17. Nísinsìn yìí tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, ẹ jẹ́ kí a ṣe ìwádìí nínú ìwé ìrántí ní ilé ìṣúra ọba ní Bábílónì láti rí bí ọba Ṣáírúsì fi àṣẹ lélẹ̀ lóòótọ́ láti tún ilé Ọlọ́run yìí kọ́ ní Jérúsálẹ́mù. Nígbà náà jẹ́ kí ọba kó fi ìpinnu rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí ránṣẹ́ sí wa.