Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremáyà 2:13-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Kí ni mo le sọ fún ọ?Pẹ̀lú u kí ni mo lè fi ọ́ wé,Ìwọ ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù?Kí sì ni mo lè fi ọ́ wé,kí n lè tù ọ́ nínú,Ìwọ wúndíá bìnrin Síónì?Ọgbẹ́ rẹ jìn bí òkun.Ta ni yóò wò ọ́ sàn?

14. Ìran àwọn wòlíì rẹjẹ́ kìkì ẹ̀tàn láìní ìwọ̀n;wọn kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàntí yóò mú ìgbèkùn kúrò fún ọ.Àwọn òrìṣà tí wọ́n fún ọjẹ́ èké àti ìsìnà.

15. Àwọn tí ó gba ọ̀nà ọ̀dọ̀ rẹpàtẹ́wọ́ lé ọ lórí;wọ́n kẹ́gàn wọ́n ju orí wọnsí ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù:“Èyí ha ni ìlú tí à ń pè níàṣepé ẹwà,ìdùnnú gbogbo ayé?”

16. Gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ la ẹnu wọngbòòrò sí ọ;wọ́n kẹ́gàn, wọ́n sì payín kekewọ́n wí pé, “A ti gbé e mì tán.Èyí ni ọjọ́ tí a ti ń retí;tí a sì wá láti rí.”

17. Olúwa ti ṣe ohun tí ó pinnu;ó ti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ,tí ó sì pàṣẹ ní ọjọ́ pípẹ́.Ó ti sí ọ nípò láì láàánú,ó fún ọ̀tá ní ìsẹ́gun lórí rẹ,ó ti gbé ìwo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ga.

18. Ọkàn àwọn ènìyànkígbe jáde sí Olúwa.Odi ọmọbìnrin Síónì,jẹ́ kí ẹkún rẹ̀ ṣàn bí odòní ọ̀sán àti òru;má ṣe fi ara rẹ fún ìtura,ojú rẹ fún ìsinmi.

19. Dìde, kígbe sókè ní àsálẹ́,bí ìṣọ́ òru ti bẹ̀rẹ̀tú ọkàn rẹ̀ jáde bí ominíwájú Olúwa.Gbé ọwọ́ yín sókè sí inítorí ẹ̀mí àwọn èwe rẹ̀tí ó ń kú lọ nítorí ebiní gbogbo oríta òpópó.

20. “Wòó, Olúwa, kí o sì rò ó:Ta ni ìwọ ti fìyà jẹ bí èyíǸjẹ́ àwọn obìnrin yóò ha jẹ ọmọ wọn,àwọn ọmọ tí wọn ń se ìtọ́jú fún?Ǹjẹ́ kí a pa olórí àlùfáà àti àwọn wòlíìní ibi mímọ́ Olúwa?

21. “Ọmọdé àti àgbà ń sùn papọ̀sínú eruku àwọn òpópó;àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin miti ṣègbé nípa idà.Ìwọ pa wọ́n run ní ọjọ́ ìbínú rẹ;Ìwọ pa wọ́n láìní àánú.

22. “Bí ó ti ṣe ní ọjọ́ àṣè,bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe fi ẹ̀rù sí ẹ̀gbẹ́ mi.Ní ọjọ́ ìbínú Olúwakòsí ẹni tí ó sálà tí ó sì yè;àwọn tí mo ti tọ́jú tí mo sì fẹ́ràn,ni ọ̀ta mi parun.”

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremáyà 2