Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 4:28-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí Nebukadinéṣárì ọba.

29. Lẹ́yìn oṣù kejìla, bí ọba ṣe ń rìn káàkiri lórí òrùlé ààfin ìjọba Bábílónì,

30. Ó sọ pé, “Èyí ha kọ́ ni Bábílónì ńlá tí mo kọ́ gẹ́gẹ́ bí ilé ọba, nípa agbára à mi àti fún ògo ọláńlá à mi?”

31. Bí ọba ṣe ń sọ ọ̀rọ̀ náà lọ́wọ́ ohùn kan wá láti ọ̀run “Ìwọ Nebukadinéṣárì ọba, ìwọ ni a ti pàṣẹ nípa rẹ̀, a ti gba ìjọba à rẹ kúrò ní ọwọ́ ọ̀ rẹ.

32. A ó lé ọ kúrò láàrin àwọn ènìyàn, ìwọ yóò sì lọ máa gbé àárin àwọn ẹranko igbó; ìwọ yóò jẹ koríko bí i màlúù, ìgbà méje yóò kọjá lórí i rẹ títí ìwọ yóò fi mọ̀ wí pé, Ọ̀gá Ògo jọba lórí ìjọba ènìyàn àti pé ó ń fi fún ẹni tí ó bá wù ú.”

33. Lẹ́ṣẹ̀kẹṣẹ̀ ni ohun tí a sọ nípa Nebukadinéṣárì ṣẹlẹ̀ sí i. A lé e kúrò láàrin ènìyàn, ó sì ń jẹ koríko bí i màlúù, ìrì ọ̀run sì ń ṣẹ̀ sí ara rẹ̀, títí irun orí i rẹ̀ fi gùn bí i ti ìyẹ́ ẹyẹ idì, tí èékánná rẹ̀ sì dàbí i ti ẹyẹ.

34. Ní òpin ìgbà náà, Èmi, Nebukadinéṣárì gbé ojú ù mi sókè sí ọ̀run, iyè mi sì sọjí. Mo fi ọpẹ́ fún Ọ̀ga Ògo; mo fi ọlá àti ògo fún ẹni tí ó wà láéláé.Ìjọba rẹ̀ ìjọba títí ayé niìjọba rẹ̀ wà láti ìran dé ìran

35. Gbogbo àwọn ènìyàn ayéni a kà sí asán.Ó ń ṣe bí ó ti wù ú,pẹ̀lú àwọn ogun ọ̀run,àti gbogbo àwọn ènìyàn ayétí kò sì sí ẹnì kankan tí ó lè dí i lọ́wọ́tàbí sọ fún un wí pé: “Kí ni ìwọ ń ṣe?”

36. Ní àkókò kan náà, iyè mi padà, ọlá àti ògo dídán mi padà tọ̀ mí wá fún ògo ìjọba mi. Àwọn ìgbìmọ̀ àti àwọn ọlọ́lá mi, wá mi rí, wọ́n sì dá mi padà sórí ìjọba mi, mo sì di alágbára ju ti ìṣáájú lọ.

37. Báyìí, èmi, Nebukadinéṣárì fi ọpẹ́, mo sì gbé Ọlọ́run ga, mo sì fi ògo fún ọba ọ̀run, nítorí pé gbogbo nǹkan tí ó ṣe ló dára, gbogbo ọ̀nà rẹ̀ sì tọ́. Gbogbo àwọn tó sì ń rìn ní ìgbéraga ni ó le rẹ̀ sílẹ̀.

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 4