Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 4:18-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. “Èyí ni àlá tí èmi Nebukadinéṣárì ọba lá. Ní ìsinsìn yìí ìwọ Beliteṣáṣárì, sọ ohun tí ó túmọ̀ sí fún mi, nítorí kò sí amòye kan ní ìjọba mi, tí ó lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi. Ṣùgbọ́n ìwọ lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀, nítorí tí ẹ̀mí Ọlọ́run mímọ́ wà ní inú un rẹ.”

19. Nígbà náà ni Dáníẹ́lì (ẹni tí à ń pè ní Beliteṣáṣárì) páyà gidigidi fún ìgbà díẹ̀, èrò inú un rẹ̀ sì bà á lẹ́rù. Nígbà náà ni ọba wí pé, “Beliteṣáṣárì, má ṣe jẹ́ kí àlá náà tàbí ìtumọ̀ rẹ̀ kí ó dẹ́rù bà ọ́.”Beliteṣáṣárì sì dáhùn wí pé, “Olúwa mi, kí àlá yìí jẹ́ ti àwọn ọ̀tá a rẹ, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ti àwọn aṣòdì sí ọ:

20. Igi tí ìwọ rí, tí ó dàgbà, tí ó sì lágbára, tí orí i rẹ̀ sì ń kan ọ̀run, tí ó lẹ́wà àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso, tí ó ń pèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn, tí ó ṣe ààbò lórí ẹranko igbó àti èyí tí ẹ̀ka rẹ̀ pèsè àyè fún ẹyẹ ojú ọ̀run.

21. Èyí tí ewé e rẹ̀ lẹ́wà, tí èṣo rẹ̀ si pọ̀, nínú èyí tí oúnjẹ sì wà fún gbogbo ẹ̀dá, lábẹ́ èyí tí àwọn ẹranko ìgbó ń gbé, lórí ẹ̀ka èyí ti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ní ibùgbé wọn.

22. Ìwọ ọba ni igi náà, ìwọ ti dàgbà, o sì lágbára, títóbi i rẹ ga ó sì kan ọ̀run, ìjọba rẹ sì gbilẹ̀ títí dé òpin ayé.

23. “Ìwọ ọba, rí ìránṣẹ́ ẹni mímọ́ kan, tí ó ń bọ̀ láti ọ̀run ó sì sọ pé, ‘Gé igi náà kí o sì run ún, ṣùgbọ́n fi kùkùté rẹ tí a dè pẹ̀lú irin àti idẹ sílẹ̀ nínú koríko igbó, nígbà tí gbòǹgbò rẹ̀ sì wà nínú ilẹ̀ kí o sì jẹ́ kí ìrì ọ̀run ṣẹ̀ sórí i rẹ̀, jẹ́ kí ìpín in rẹ̀ wà láàrin ẹranko búburú títí ìgbà méje yóò fi kọjá lórí i rẹ̀.’

24. “Èyí ni ìtúmọ̀ àlá rẹ ọba àti àṣẹ tí Ọ̀gá Ògo mú wá sórí ọba olúwa mi:

25. A ó lé ọ jáde kúrò láàrin ènìyàn, ìwọ yóò sì máa gbé láàrin ẹranko búburú: ìwọ yóò jẹ koríko bí i màlúù, ìrì ọ̀run yóò sì sẹ̀ sára rẹ. Ìgbà méje yóò sì kọjá lórí ì rẹ, títí ìwọ yóò fi mọ̀ wí pé Ọ̀gá Ògo ń jọba lórí ìjọba ènìyàn, ó sì ń fi fún ẹni tí ó bá wù ú.

26. Bí wọ́n ṣe pàṣẹ pé kí wọn fi kùkùté àti gbòǹgbò igi náà sílẹ̀, èyí túmọ̀ sí wí pé a ó dá ìjọba rẹ padà fún ọ lẹ́yìn ìgbà tí o bá ti mọ̀ wí pé, Ọ̀run jọba.

27. Nítorí náà ọba, jẹ́ kí ìmọ̀ràn mi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún ọ, kọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ sílẹ̀ kí o sì ṣe rere, àti ìwà búburú rẹ nípa ṣíṣe àánú fún àwọn talákà. Ó lè jẹ́ pé nígbà náà ni ìwọ yóò ṣe rere.”

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 4