Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 60:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Dìde, tànmọ́lẹ̀, nítorí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé,ògo Olúwa sì ràdọ̀bò ọ́.

2. Kíyèsí i, òkùnkùn bo ilẹ̀ ayéòkùnkùn biribiri sì wà lórí àwọn ènìyàn,ṣùgbọ́n Olúwa ràn bò ọ́ògo rẹ̀ sì farahàn lóríi rẹ.

3. Àwọn orílẹ̀ èdè yóò wá sí ìmọ́lẹ̀ rẹ,àti àwọn ọba sí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ rẹ.

4. “Gbé ojú rẹ ṣókè kí o sì wò yíká rẹ:Gbogbo wọn gbárajọ wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ;àwọn ọmọ rẹ wá láti ọ̀nà jíjìn,àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrìn rẹ ni a gbé ní apá.

5. Nígbà náà ni ìwọ yóò wò tí ojú rẹ yóò máa dán,ọkàn rẹ yó fó yó sì kún fún ayọ̀;ọrọ̀ inú òkun ni a ó kò wá sọ́dọ̀ rẹ,sí ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè yóò wá.

6. Ọ̀wọ́ ràkunmí yóò bo gbogbo ilẹ̀ rẹ,àwọn ọ̀dọ́ ràkunmí Mídíánì àti Ẹfà.Àti gbogbo wọn létí Ṣèbà yóò wá,wọn yóò mú Góòlù àti tùràrí lọ́wọ́tí wọn yóò sì máa kéde ìyìn Olúwa.

7. Gbogbo agbo ẹran Kédárì ni a ó kójọ sọ́dọ̀ rẹ,àwọn àgbò ti Nébáíótì yóò sìn ọ́;wọn yóò jẹ́ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà lóríi pẹpẹ mi,bẹ́ẹ̀ ni n ó sì ṣe tẹ́ḿpìlì ògo mi lọ́ṣọ̀ọ́.

8. “Ta ni àwọn wọ̀nyí tí ń fò lọ bí i kùrukùru,gẹ́gẹ́ bí àwọn àdàbà sí ìtẹ́ wọn?

9. Lótìítọ́ àwọn erékùṣù bojú wò mí;ní ìṣíwájú ni àwọn ọkọ̀ ojú omi Táṣíṣì;mú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wá láti ọ̀nà jínjìn,pẹ̀lú fàdákà àti góòlùu wọn,fún ti ọlá Olúwa Ọlọ́run rẹ,Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,nítorí òun ti fi ohun dídára ṣe ó lọ́ṣọ̀ọ́.

10. “Àwọn àjèjì yóò tún ògiriì rẹ mọàwọn ọba wọn yóò sì sìn ọ́.Bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé ní ìbínú ni mo lù ọ́,ní àánú èmi yóò ṣe inú rere sí ọ.

11. Gbogbo ẹnu bodè rẹ ni yóò wà ní sísí sílẹ̀,a kì yóò tì wọ́n ní ọ̀sán àti ní òru,tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọkùnrin yóò le è kóọrọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè wátí àwọn ọba wọn yóò ṣáájú níọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ìṣẹ́gun.

12. Nítorí pé orílẹ̀ èdè tàbí ilẹ̀ ọba tí kì yóò sìn ọ́ ni yóò parun;pátapáta ni yóò sì dahoro.

Ka pipe ipin Àìsáyà 60