Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 59:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lódodo ọwọ́ Olúwa kò kúrú láti gbàlà,tàbí kí etí rẹ̀ wúwo láti gbọ́.

2. Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yín ló ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run yín;Ẹ̀ṣẹ̀ yín ti fi ojúu rẹ̀ pamọ́ fún un yíntó bẹ́ẹ̀ tí òun kò fi le gbọ́.

3. Nítorí ọwọ́ọ yín di aláìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀,àti ìka ọwọ́ọ yín fún ẹ̀bi.Ètèe yín ń pa irọ́ púpọ̀,ahọ́n an yín sì ń ṣọ̀rọ̀ nǹkan ibi.

4. Kò sí ẹni tí ó bèèrè fún ìdájọ́ òdodo;kò sí ẹni tí ó ro ẹjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú òtítọ́.Wọ́n gbọ́kànlé àwíjàre aṣán àti ọ̀rọ̀ irọ́;wọ́n lóyún ìkà, wọn sì bí wàhálà

5. Wọn ń pa ẹyín pamọ́lẹ̀wọn sì ń ta owú aláǹtakùn.Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹyin wọn yóò kú,àti nígbà tí a pa ọ̀kan, pamọ́lẹ̀ ni ó jáde.

6. Òwú wọn kò wúlò fún aṣọ rírán;wọn kò lè fi aṣọ tí wọ́n hun bo ara wọn.Iṣẹ́ wọn jẹ́ ti ibi, ìwà jàǹdàkú sì kún ọwọ́ wọn.

7. Ẹsẹ̀ wọn yára bọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀;wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.Èrò wọn sì jẹ́ èrò ibi;ìparun àti ìdahoro ni ó wà ní ṣíṣe àmì ọ̀nà wọn.

8. Ọ̀nà àlàáfíà èyí ni wọn kò mọ̀;kò sí òdodo ní ojú ọ̀nà wọnwọ́n ti sọ wọ́n dì ọ̀nà kọ́rọkọ́rọ,kò sí ẹni tí ó tọ ọ̀nà yìí tí yóò rí àlàáfíà.

9. Nítorí èyí ni ẹ̀tọ́ fi jìnnà sí wa,àti tí òdodo kò fi tẹ̀wá lọ́wọ́.A ń wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo rẹ jẹ́ òkùnkùn;fún ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n à ń rìn nínú òjìji.

10. Gẹ́gẹ́ bí afọ́jú à ń táràrà lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògirití a ń wá ọ̀nà wa gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí kò ní ojú.Ní ọ̀sán gangan ni à ń kọsẹ̀ bí ẹni pé alẹ́ ni;láàrin alágbára àwa dàbí òkú.

11. Gbogbo wa là ń ké bí i bíárì;àwa pohùnréré ẹkún bí àdàbàA ń wá ìdájọ́ òdodo ṣùgbọ́n kò sí; à ń wọ̀nàfún ìtúsílẹ̀, ṣùgbọ́n ó jìnnà réré.

Ka pipe ipin Àìsáyà 59