Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 37:2-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Òun sì rán Eliákímù alákoṣo ààfin, Ṣébínà akọ̀wé, àti aṣíwájú àwọn àlùfáà, gbogbo wọn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ Wòlíì Àìṣáyà ọmọ Ámósì.

3. Wọ́n sọ fún un pé, “Báyìí ni Heṣekáyà sọ: ọjọ́ òní jẹ́ ọjọ́ ìbànújẹ́, ìbáwí àti ìtìjú gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí àwọn ọmọdé kùdẹ̀dẹ̀ ìbí tí kò sì sí agbára láti bí wọn.

4. Ó lè jẹ́ pé Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ọ̀gágun ẹni tí ọ̀gá rẹ̀ ọba Ásíríà ti rán láti fi Ọlọ́run alààyè ṣe ẹlẹ́yà, àti pé òun ni yóò bá a wí nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti gbọ́. Nítorí náà gbàdúrà fún àwọn tí ó ṣẹ́kù tí wọ́n sì wà láàyè.”

5. Nígbà tí àwọn ìjòyè ọba Heṣekáyà dé ọ̀dọ̀ Àìṣáyà,

6. Àìṣáyà sọ fún wọn pé, “Ẹ sọ fún ọ̀gá yín pé, ‘Ohun tí Olúwa sọ nìyìí: Má ṣe bẹ̀rù ohun tí ẹ ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba Ásíríà tí ó wà nínú ìdè ti fi sọ̀rọ̀ òdì sí mi.

7. Tẹ́tísílẹ̀! Èmi yóò fi ẹ̀mí kan sínú rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé bí o bá ti gbọ́ ìròyìn kan, òun yóò padà sí orílẹ̀ èdè rẹ̀, níbẹ̀ ni n ó sì ti jẹ́ kí wọn ké e lulẹ̀ pẹ̀lú idà.’ ”

8. Nígbà tí ọ̀gágun gbọ́ pé ọba Áṣíríà ti fi Lákísì sílẹ̀, ó padà sẹ́yìn, ó sì bá ọba tí ń bá Líbínà jà.

9. Ní àkókò yìí Ṣenakérúbù gbọ́ ìròyìn kan pé Tíhákà ará Kúṣì ọba Éjíbítì ń jáde bọ̀ wá bá òun jà. Nígbà tí ó gbọ́ èyí, ó rán oníṣẹ́ sí Heṣekáyà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí:

10. “Ẹ sọ fún Heṣekáyà ọba Júdà pé: Má ṣe jẹ́ kí òrìṣà tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé tàn ọ́ jẹ nígbà tí ó sọ pé, ‘a kì yóò jọ̀wọ́ Jérúsálẹ́mù fún ọba Ásíríà.’

11. Dájúdájú, ìwọ ti gbọ́ ohun tí ọba Ásíríà ti ṣe sí àwọn orílẹ̀ èdè, tí ó pa wọ́n run pátapáta. Ǹjẹ́ a ó ha dá ọ nídè bí?

12. Ǹjẹ́ àwọn òrìṣà àwọn orílẹ̀ èdè tí àwọn baba ńlá mi parun ha gbà wọ́n sílẹ̀ bí àwọn òrìṣà Gósénì, Háránì, Résípì àti àwọn ènìyàn Ẹ́dẹ́nì tí wọ́n wà ní ìlú Áṣárì?

13. Níbo ni ọba Hámátì wà, ọba Ápádì, ọba Ìlú Ṣefáfíámù tàbí Hénà tàbí Ífà?”

Ka pipe ipin Àìsáyà 37