Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 8:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nísin yìí, Èlíṣà wí fún obìnrin náà tí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin jí pàdà sáyé pé, “jáde lọ pẹ̀lú ìdílé rẹ kí o sì lọ dúró fún ìgbà díẹ̀ ní ibíkíbi tí o bá le dúró sí, nítorí Olúwa ti pàṣẹ ìyàn ní ìlú tí yóò lò tó ọdún méje.”

2. Obìnrin náà tẹ̀ ṣíwájú gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn Ọlọ́run ti sọ. Òun àti ìdílé rẹ̀ sá lọ, wọ́n sì dúró ní ilé àwọn ará Fílístínì fún ọdún méje.

3. Ní ẹ̀yìn ọdún méje ó sì padà wá láti ilẹ̀ àwọn ará Fílístínì ó sì lọ sí ọ̀dọ̀ ọba láti lọ bẹ̀ẹ́ fún ilé àti ilẹ̀ rẹ̀.

4. Ọba sì ń sọ̀rọ̀ sí Géhásì, ìránṣẹ́ ènìyàn Ọlọ́run pé, “Sọ fún mi nípa gbogbo ohun ńlá tí Èlísà ti ṣe.”

5. Bí Gèhásì ti ń sọ bí tí Èlíṣà ṣe jí òkú di alàyè, obìnrin náà tí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tí Èlíṣà ti dá padà sí ayé wá láti bẹ ọba fún ilé àti ilẹ̀ rẹ̀.Gèhásì sì wí pé, “Obìnrin náà nì yí Olúwa mi ọba, ọmọkùnrin rẹ náà nìyí tí Èlísà ti jí dìde sí ayé.”

6. Ọba bèèrè lọ́wọ́ obìnrin náà nípa rẹ̀, ó sì sọ fún un.Ó sì yan ìjòyè kan fún ún fún ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó sì wí fún un pé, “Ẹ fún un padà gbogbo ohun tí ó bá jẹ́ tirẹ̀, àti pẹ̀lú gbogbo èrè ilé rẹ̀ fún ún láti ọjọ́ tí ó ti kúrò ní ìlú títí di àsìkòyí.”

7. Èlíṣà lọ sí Dámásíkù, Bẹni-Hádádì ọba Ṣíríà ń ṣe àìsàn. Nígbà tí wọ́n sọ fún ọba pé, “Ènìyàn Ọlọ́run ti wá láti gbogbo ọ̀nà òkè síbí”,

8. ó sì wí fún Hásáélì pé, “Mú ẹ̀bùn kan pẹ̀lú rẹ láti lọ pàdé ènìyàn Ọlọ́run. Kí o sì béèrè Olúwa láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé ṣé èmi yóò sàn nínú àìsàn yìí?”

9. Hásáélì lọ láti pàdé Èlísà, ó mú lọ pẹ̀lú rẹ̀ ẹ̀bùn gẹ́gẹ́ bí ogójì ẹrù ìbákasìẹ tí gbogbo ìní tí ó dára jù fún wíwò ti Dámásíkù, ó sì wọlé lọ ó sì dúró níwájú rẹ̀, ó sì wí pé, “Ọmọ rẹ Bénhádádì ọba Ṣíríà rán mi láti béèrè pé, ‘Ṣé èmi yóò sàn nínú àìsàn mi yìí?’ ”

10. Èlíṣà da á lóhùn pé, “Lọ kí o lọ sọ fún un pé, ‘Ìwo ìbá sàn ní tòótọ́’; ṣùgbọ́n Olúwa ti fi hàn mí pé nítòotọ́ òun yóò kú.”

11. Ó sì ranjú mọ́ ọn pẹ̀lú àtẹjúmọ́ gidigidi títí tí ojú fi ti Hásáélì. Nígbà náà ènìyàn Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí ní sunkún.

12. “Kí ni ó dé tí Olúwa mi fi ń sunkún?” Hásáélì bèèrè.“Nítorí pé èmi mọ ibi tí ìwọ yóò ṣe sí Ísírẹ́lì,” ó sì dáhùn pé, “Ìwọ yóò fi iná si odi agbára wọn, ìwọ yóò, pa àwọn ọ̀dọ́ ọmọkùnrin wọn pẹ̀lú idà, ìwọ yóò kọlù àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn, ìwọ ó sì fọ́ wọn túútúú, ìwọ o sì la inú àwọn aboyún wọn.”

13. Hásáélì sì wí pé. “Báwo ni ìránṣẹ́ rẹ, ajá lásán làsàn yóò ṣe ṣe irú nǹkan ńlá bẹ́ẹ̀?”“Olúwa ti fi hàn mí pé ìwọ ni yóò jẹ ọba síríà,” Èlíṣà dá a lóhùn.

Ka pipe ipin 2 Ọba 8