Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 5:16-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Wòlíì náà dáhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ń bẹ láàyè, ẹni tí mo ń sìn, èmi kò ní gba ohun kan,” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Námánì rọ̀ ọ́ láti gbàá, ó kọ̀.

17. “Tí o kò bá ní gba,” Námánì wí pé, “Jọ̀wọ́ jẹ́ kí èmi, ìránṣẹ́ rẹ fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹrù ẹrùpẹ̀ ìbaka méjì, nítorí láti òní lọ ìránṣẹ́ rẹ kì yóò rú ẹbọ sísun àti rúbọ sí ọ̀kan lára àwọn ọlọ́run mìíràn ṣùgbọ́n Olúwa.

18. Ṣùgbọ́n kí Olúwa kí ó dáríjì ìránṣẹ́ rẹ fún nǹkan yìí: Nígbà tí ọ̀gá mi wọ inú ilé Rímónì láti fi orí balẹ̀ tí ó sì fi ara ti ọwọ́ mi tí mo sì tẹ ara mi ba pẹ̀lú níbẹ̀. Nígbà tí èmi tẹ ara mi ba ní ilé Rímónì, kí Olúwa dáríji ìránṣẹ́ rẹ fún èyí.”

19. Èlíṣà wí pé, “Má a lọ ní àlàáfíà.”Lẹ́yìn ìgbà tí Námánì tí rin ìrìnàjò tí ó jìnnà,

20. Géhásì, ìránṣẹ́ Èlíṣà ènìyàn Ọlọ́run, ó wí fún ara rẹ̀ pé, “Ọ̀gá mi jẹ́ ẹni tí ó rọ̀ lórí Námánì, ará Árámù, nípa pé kò gba ohunkóhun ní ọwọ́ rẹ̀ ohun tí ó mú wá, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ń bẹ láàyè, èmi yóò sá tẹ̀lé e èmi yóò sì gba ohun kan ńi ọwọ́ rẹ̀.”

21. Bẹ́ẹ̀ ni Géhásì sáré tẹ̀lé Námánì. Nígbà tí Námánì rí i tí ó ń sáré tẹ̀lé e, ó sì sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ láti pàdé rẹ̀. “Ṣé gbogbo nǹkan wà dáadáa?” ó béèrè.

22. “Gbogbo nǹkan wà dáadáa,” Géhásì dá a lóhùn. “Ọ̀gá mi rán mi láti sọ wí pé, ‘Àwọn ọ̀dọ́ ọmọkùnrin méjì láti ọ̀dọ̀ ọmọ wòlíì wọ́n ṣẹ̀ ṣẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ mi láti orí òkè ìlú ti Éfúráímù. Jọ̀wọ́ fún wọn ní ẹ̀bùn fàdákà àti ìpàrọ̀ aṣọ méjì.’ ”

23. Námánì wí pé, “Ní gbogbo ọ̀nà, mú ẹ̀bùn méjì.” Ó sì rọ Géhásì láti gbà wọ́n, ó sì di ẹ̀bùn méjì náà ti fàdákà ní inú àpò méjì, pẹ̀lú ìpààrọ̀ aṣọ méjì, ó sì fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ méjì, wọ́n sì kó wọn lọ sọ́dọ̀ Géhásì.

24. Nígbà tí Géhásì wá sí ilẹ̀ gíga, ó sì mú nǹkan náà lọ́dọ̀ ìránṣẹ́ ó sì gbé wọn kúrò ní ilé, ó sì rán ọkùnrin náà jáde ó sì lọ.

25. Nígbà náà ó sì wọlé wá ó sì dúró níwájú ọ̀gá rẹ̀ Èlíṣà.“Níbo ni o ti wà Géhásì?” Èlíṣà bèèrè.“Ìránṣẹ́ rẹ kò lọ sí ibìkan kan.” Géhásì dá a lóhùn.

26. Ṣùgbọ́n Èlíṣà wí fún un pé, “Ẹ̀mí mi kò ha wà pẹ̀lú rẹ nígbà tí ọkùnrin náà sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ láti pàdé rẹ? Ṣé àsìkò tí ó yẹ láti gba owó nìyìí, tàbí láti gba aṣọ, ọgbà-ólífì, ọgbà àjàrà, àgùntàn, màlúù tàbí ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin?

27. Ẹ̀tẹ̀ Námánì yóò rọ̀mọ́ ọ àti sí irú ọmọ rẹ títí láé.” Nígbà náà Géhásì kúrò níwájú Èlíṣà, ó sì di adẹ́tẹ̀, ó sì funfun gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ̀n òwú.

Ka pipe ipin 2 Ọba 5