Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 21:6-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ó fi ọmọ ara rẹ̀ rúbọ̀ nínú iná, a máa ṣe àkíyèsí àfọ̀ṣẹ àti àlùpàyídà, ó sì máa ń bá àwọn òku àti oṣó lò. Ó hùwà búburú púpọ̀ ní ojú Olúwa láti mú un bínú.

7. Ó sì gbé fínfín ère òrìṣà tí ó ti ṣe ó sì gbé e sínú ilé Olúwa, èyí tí Olúwa ti sọ fún Dáfídì àti sí ọmọ rẹ̀ Ṣólómónì, “Nínú ilé Olúwa yìí àti ní Jérúsálẹ́mù, tí èmi ti yàn jáde lára gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, èmi yóò kọ orúkọ mi títí láéláé.

8. Èmi kò ní jẹ́ kí ẹsẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹ̀ kúrò láti ilẹ̀ tí èmi fi fún àwọn babańlá wọn tí ó bá jẹ́ wí pé wọn yóò ṣe àkíyèsí láti ṣe gbogbo ohun tí èmi ti paláṣẹ fún wọn kí wọn sì pa gbogbo òfin tí ìránṣẹ́ mi Móṣè fi fún wọn mọ́.”

9. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò tẹ́tí. Mánásè tàn wọ́n ṣíwájú, bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n lè ṣe búburú ju gbogbo orílẹ̀ èdè tí Olúwa tí parun níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ.

10. Olúwa sì wí nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì pé:

11. “Mánásè ọba Júdà ti ṣe ẹ̀ṣẹ̀ ohun ìríra. Ó ti ṣe ohun búburú jùlọ ju àwọn ará Ámórì lọ ẹni tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀ tí ó sì ti ṣáájú Júdà sínú ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú àwọn ère rẹ̀.

Ka pipe ipin 2 Ọba 21