Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 21:10-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Olúwa sì wí nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì pé:

11. “Mánásè ọba Júdà ti ṣe ẹ̀ṣẹ̀ ohun ìríra. Ó ti ṣe ohun búburú jùlọ ju àwọn ará Ámórì lọ ẹni tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀ tí ó sì ti ṣáájú Júdà sínú ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú àwọn ère rẹ̀.

12. Nítorí náà èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wí: Èmi le è lọ mú irú ibi báyìí wá sórí Jérúsálẹ́mù àti Júdà kí gbogbo etí olúkúlùkù tí ó gbọ́ nípa rẹ̀ le è hó.

13. Èmi yóò sì nà okùn ìwọ̀nkan tí a lò lórí Jérúsálẹ́mù àti lórí Ṣamáríà àti òjé ìdiwọ̀n ti a lòlò lórí ilé Áhábù. Èmi yóò sì nu Jérúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí ọkàn tí ń nu àwokòtò nù ti o n nù un tí o sì ń dorí rẹ̀ kodò.

14. Èmi yóò sì kọ ìyókù àwọn ìní mi sílẹ̀ èmi yóò sì kó wọn lé àwọn ọ̀ta wọn lọ́wọ́. Wọn yóò sì di ìkógun àti ìjẹ fún gbogbo àwọn ọ̀ta wọn,

15. nítorí pé wọ́n ti ṣe búburú ní ojú mi, wọ́n sì ti mú mi bínú láti ọjọ́ tí babańlá wọn ti jáde wá láti Éjíbítì títí di òní yìí.”

16. Pẹ̀lúpẹ̀lù, Mánásè pẹ̀lú ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ púpọ̀ tí ó kún Jérúsálẹ́mù láti ìkangun dé ìkangun ní ẹ̀gbẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti mú Júdà ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni, kí wọ́n lè ṣe ohun búburú ní ojú Olúwa.

17. Ní ti iṣẹ́ ìyókù ti ìjọba Mánásè, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, àti fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, ṣé wọ́n kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn àwọn ọba Júdà?

18. Mánásè sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ wọ́n sì sin ín nínú ọgbà ààfin rẹ̀, ọgbà Úṣà Ámónì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

19. Ámónì jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó jọba. Orúkọ bàbá rẹ̀ a sì máa jẹ́ Méṣúlémétì ọmọbìnrin Hárúsì: ó wá láti Jótíbà, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún méjì.

20. Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa àti gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Mánásè ti ṣe.

21. Ó rìn ní gbogbo ọ̀nà baba rẹ̀: Ó sì ń sin àwọn ère tí baba rẹ̀ ń sìn, ó sì ń tẹrí rẹ̀ ba fún wọn.

22. Ó sì kọ Olúwa Ọlọ́run baba rẹ̀ sílẹ̀ kò sì rìn ní ọ̀nà ti Olúwa.

Ka pipe ipin 2 Ọba 21