Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 18:23-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. “ ‘Wá Nísinsìn yìí, ṣe àdéhùn pẹ̀lú ọ̀gá mi, ọba Áṣíríà: Èmi yóò sì fún ọ ní ẹgbàá ẹṣin (2000) tí ìwọ bá lè kó àwọn tí yóò gùn ún sí orí rẹ!

24. Báwo ni ìwọ yóò ṣe le padà sẹ́yìn ọ̀kan lára àwọn oníṣẹ́, tí ó gbẹ̀yìn lára àwọn oníṣẹ́ ọ̀gá mi, tí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé; ẹ̀yin gbẹ́kẹ̀ yín lé Éjíbítì fún àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin?

25. Síwájú síi, èmi ti wá láti mú àti láti parun ibíyìí láìsí ọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa? Olúwa fún rara rẹ̀ sọ fún mi pé kí n yára láti yan lórí ìlú yìí, kí n sì paárun.’ ”

26. Nígbà náà Éláékímù ọmọ Hílíkíáyà, àti ṣébínà àti Jóà sọ fún olùdarí pápá pé, “Jọ̀wọ́ sọ̀rọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ ní èdè Ṣíríà, nítorí ti ó tí yé wa, má ṣe sọ̀rọ̀ fún wa pẹ̀lú èdè Hébérù ní etí ìgbọ́ àwọn ènìyàn tí ń bẹ lórí odi.”

27. Ṣùgbọ́n aláṣẹ dáhùn pé, “Ṣé fún ọ̀gá rẹ àti ìwọ nìkan ní ọ̀ga mi rán mi sí láti sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí kì í sìí ṣe fún àwọn ọkùnrin tí ó jókòó lórí odo-ta ni gẹ́gẹ́ bí ìwọ, ni yóò ní láti jẹ ìgbẹ́ ará wọn kí wọ́n sì mu ìtọ̀ ará wọn?”

28. Nígbà náà aláṣẹ dìdé ó sì pè jáde ní èdè Hébérù pé, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba ńlá, ọba Ásìría!

29. Èyí ni ohun tí ọba sọ: má ṣe jẹ́ kí Héṣékíáyà tàn ọ́ jẹ kò le gbà ọ́ kúrò ní ọwọ́ mi

30. Má se jẹ́ kí Héṣékíáyà tì ọ́ láti gbàgbọ́ nínú Olúwa nípa sísọ pé, ‘Olúwa yóò gbà wá nítòótọ́; ìlú yìí ni wọn kò ní fi lé ọba ìlú Ásíríà lọ́wọ́.’

31. “Má ṣe tẹ́tí sí Héṣékíáyà. Èyí ni ohun tí ọba Ásíríà sọ: ‘Ṣe àlàáfíà pẹ̀lú mi kí o sì jáde wá sí ọ̀dọ̀ sí mi.’ Nígbà náà olúkúlùkù yín yóò jẹun láti inú àjàrà rẹ̀ àti igi ọ̀pọ̀tọ́, yóò sì mumi láti inú àmù rẹ̀,

32. Títí tí èmi yóò fi wá mú ọ lọ sí ilé gẹ́gẹ́ bí i tìrẹ, ilẹ̀ ọkà àti ọtí wáìnì, ilẹ̀ ouńjẹ àti ọgbà àjàrà, ilẹ̀ òróró ólífì àti ti ilẹ̀ oyin; yàn ìye má sì ṣe yàn ikú!“Kí ẹ má ṣe gbọ́ tí Heṣekáyà, nítorí ó ń tàn yín tí ó ba tí wí pé, ‘Olúwa yóò gbà wá?’

33. Ṣé òrìṣà àwọn orílẹ̀ èdè kankan ti gba ilé rẹ lọ́wọ́ àwọn ọba Ásíríà?

Ka pipe ipin 2 Ọba 18