Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 16:6-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ní àkókò náà, Résínì Ọba Ṣíríà gba Élátì padà fún Ṣíríà, ó sì lé àwọn ènìyàn Júdà kúrò ní Élátì: àwọn ará Ṣíríà sì wá sí Élíátì, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ títí di òní yìí.

7. Áhásì sì rán oníṣẹ́ sọ́dọ̀ Tigilati-Pílésérì ọba Ásíríà wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ni èmi, àti ọmọ rẹ; gòkè wá, kí o sì gbà mi lọ́wọ́ ọba Síríà, àti lọ́wọ́ ọba Ísírẹ́lì tí ó díde sí mi.”

8. Áhásì sì mú fàdákà àti wúrà tí a rí ní ilé Olúwa, àti nínú ìṣúrà ilé ọba, ó sì rán an sí ọba Ásíríà ní ọrẹ.

9. Ọba Ásíríà sì gbọ́ tirẹ̀: nítórí ọba Ásíríà gòkè wá sí Dámásíkù, ó sì kó o, ó sì mú un ní ìgbékùn lọ sí Kírì, ó sì pa Résínì.

10. Ọba sì lọ sí Dámásíkù láti pàdé Tigilati-Pílésérì, ọba Ásíríà, ó sì rí pẹpẹ kan tí ó wà ní Dámásíkù: Áhásì ọba sì rán àwòrán pẹpẹ náà, àti àpẹẹrẹ rẹ̀ sí Úráyà àlùfáà, gẹ́gẹ́ bí gbogbo iṣẹ́ ọ̀nà rẹ̀.

11. Úráyà àlùfáà sì kọ́ pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí Áhásì ọba fi ránṣẹ́ síi láti Dámásíkù; bẹ́ẹ̀ ni Úráyà àlùfàá ṣe é dé ìpadàbọ̀ Áhásì ọba láti Dámásíkù.

12. Nígbà tí ọba sì ti Dámásíkù dé, ọba sì rí pẹpẹ náà: ọba sì súnmọ́ pẹpẹ náà, ó sì rúbọ lórí rẹ̀.

13. Ó sì ṣun ẹbọ ọrẹ-ṣíṣun rẹ̀ àti ọrẹ-jíjẹ rẹ̀, o si ta ohun-mímu rẹ̀ sílẹ̀, ó sì wọ́n èjẹ̀ ọrẹ-àlàáfíà rẹ̀ sí ará pẹpẹ náà.

14. Ṣùgbọ́n ó mú pẹpẹ idẹ tí ó wà níwájú Olúwa kúrò láti iwájú ilé náà, láti àárin méjì pẹpẹ náà, àti ilé Olúwa, ó sì fi í sí apá àríwá pẹpẹ náà.

15. Áhásì ọba sì pàṣẹ fún Úráyà àlùfáà, wí pé, “Lórí pẹpẹ ńlá náà ni kó o máa ṣun ọrẹ-ṣíṣun òròwúrọ̀ àti ọrẹ-jijẹ alaalẹ́, àti ẹbọ ṣíṣun ti ọba, àti ọrẹ-jíjẹ rẹ̀, pẹ̀lú ọrẹ ṣíṣun tí gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti ọrẹ jíjẹ wọn, àti ọrẹ ohun mímu wọn; kí o sì wọ́n gbogbo ẹ̀jẹ̀ ọrẹ-sísun náà lórí rẹ̀, àti gbogbo ẹ̀jẹ̀ ẹbọ mìíràn: ṣùgbọ́n ní ti pẹpẹ idẹ náà èmi ó máa gbèrò ohun tí èmi ó fi ṣe.”

16. Báyìí ni Úráyà àlùfáà ṣe, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Áhásì ọba pa láṣẹ.

17. Áhásì ọba sì gé igi-ìpílẹ̀ àwọn àgbédúró náà, ó sí agbada náà kúrò lára wọn; ó sì gbé agbada nlá náà kalẹ̀ kúrò lára àwọn màlúù idẹ tí ń bẹ lábẹ́ rẹ̀, ó sì gbé e ka ilẹ̀ tí a fi òkúta tẹ́.

18. Ibi ààbò fún ọjọ́ ìsinmi tí a kọ́ nínú ilé náà, àti ọ̀nà ìjáde sí òde ọba, ni ó yípadà kúrò ní ilé Olúwa nítorí ọba Ásíríà.

19. Àti ìyókù ìṣe Áhásì tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Júdà?

20. Áhásì sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dáfídì: Heṣekáyà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

Ka pipe ipin 2 Ọba 16