Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 6:17-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Nísinsìnyí, Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ tí o ti sèlérí fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì kí ó wá sí ìmúṣẹ.

18. “Ṣùgbọ́n ṣé Ọlọ́run nítòótọ́ yóò máa bá àwọn ènìyàn gbé lórí ilẹ̀ ayé bí? Ọ̀run, àti ọ̀run gíga kò le gbà ọ́. Báwo ni ó ṣe kéré tó, ilé Olúwa tí mo ti kọ́!,

19. Síbẹ̀ ṣe àfiyèsí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ fún àánú, Olúwa Ọlọ́run mi, gbọ́ ẹkún àti àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ̀ ń gbà níwájú rẹ.

20. Kí ojú rẹ kí ó lè sí sí ilé Olúwa ní ọ̀sán àti lóru, ní ibí yìí tí ìwọ ti wí pé ìwọ yóò fi orúkọ rẹ síbẹ̀. Kí ìwọ kí ó gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà lórí ibí yìí.

21. Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ àti ti àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n bá ń gbàdúrà lórí ibí yìí. Gbọ́ láti ọ̀run, ibùgbé rẹ, nígbà tí ìwọ bá sì gbọ́, dáríjìn.

22. “Nígbà tí ọkùnrin kan bá sì ṣe aburú sí aládùúgbò rẹ̀ tí ó sì gbà kí ó ṣe ìbúra tí ó sì wá tí o sì búra níwájú pẹpẹ rẹ nínú ilé Olúwa yìí,

23. Nígbà naà, gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dáhùn. Ṣe ìdájọ́ láàrin àwọn ìránṣẹ́ rẹ, san padà fún ẹni tí ó jẹ̀bi nípa mímú padà wá sí orí òun tìkárarẹ̀ ohun tí ó ti ṣe. Ṣe ìdáláre fún olódodo, bẹ́ẹ̀ sì ni, fi fún-un gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ̀.

24. “Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì bá ní ìjákulẹ̀ níwájú àwọn ọ̀tá nítorí wọ́n ti dẹ́sẹ̀ sí ọ àti nígbà tí wọ́n bá sì yípadà, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n gbàdúrà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ nínú ilé Olúwa yìí,

25. Nígbà náà, gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì jìn wọ́n kí o sì mú wọn padà wá sílé tí o ti fi fún wọn àti àwọn bàbá wọn.

26. “Nígbà tí a bá ti ọ̀run tí kò sì sí òjò nítorí àwọn ènìyàn rẹ ti dẹ́sẹ̀ sí ọ, Nígbà tí wọ́n bá sì gbàdúrà sí ibí yìí tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ tí wọ́n sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí ìwọ ti pọ́n wọn lójú,

27. Nígbà náà gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ jìn àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì kọ́ wọn ní ọ̀nà tí ó tọ́ nínú èyí tí wọn ó má a rìn, kí o sì rán òjò lórí ilẹ̀ tí o ti fi fún àwọn ènìyàn rẹ fún ìní.

28. “Nígbà tí ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-àrùn bá wá sí ilẹ̀ náà, tàbí ìrẹ̀dànù tàbí ìmúwòdù, irúgbà tàbí ẹlẹ́ǹgà, tàbí nígbà tí àwọn ọ̀tá wọn bá yọ wọ́n lẹ́nu nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú wọn, ohunkóhun, ìpọnjú tàbí àrùn lè wá,

29. Nígbà tí àdúrà tàbí ẹ̀bẹ̀ bá sì wá láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì olúkúlùkù mọ̀ nípa ìpọ́njú rẹ̀ àti ìbànújẹ́, tí ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí ìhà ilé Olúwa yìí.

30. Nígbà náà gbọ́ láti ọ̀run ibùgbé rẹ dáríjì, kí o sì pín fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí i gbogbo ohun tí ó ṣe, nígbà tí ìwọ ti mọ ọkàn rẹ̀ (nítorí ìwọ nìkan ni ó mọ okàn ènìyàn)

31. Bẹ́ẹ̀ ni kí wọn kí ó lè bẹ̀rù rẹ kí wọn kí ó sì rìn ní ọ̀nà rẹ ní gbogbo ìgbà tí wọ́n ń gbé nínú ilé tí o ti fi fún àwọn baba wa.

32. “Ní ti àwọn àlejò tí wọn kò sí lára àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì ṣùgbọ́n tí wọ́n wá láti ọ̀nà jínjìn nítorí orúkọ ńlá rẹ àti ọwọ́ agbára rẹ àti nínà apá rẹ, nígbà tí ó bá wá tí ó sì gbàdúrà lórí ilé Olúwa yìí.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 6