Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 22:14-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ṣùgbọ́n Míkáyà wí pé, “Bí Olúwa ti wà, ohun tí Olúwa bá sọ fún mi ni èmi yóò sọ fún un.”

15. Nígbà tí ó sì dé, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Míkáyà, ṣé kí a lọ bá Ramoti-Gílíádì jagun, tàbí kí a jọ̀wọ́ rẹ̀?”Ó sì dáhùn wí pé, “Lọ, kí o sì ṣẹ́gun, nítorí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́.”

16. Ọba sì wí fún un pé, “Ìgbà mélòó ni èmi yóò fi ọ bú pé kí o má ṣe sọ ohun kan fún mi bí kò ṣe òtítọ́ ní orúkọ Olúwa?”

17. Míkáyà sì dáhùn pé, “Mo rí gbogbo Ísírẹ́lì túkáàkiri lórí àwọn òkè bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́, Olúwa sì wí pé, ‘Àwọn wọ̀nyí kò ní olúwa. Jẹ́ kí olúkúlùkù padà sí ilé rẹ̀ ní àlàáfíà.’ ”

18. Ọba Ísírẹ́lì sì wí fún Jèhósáfátì pé, “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún ọ pé kò fọ ire kan sí mi rí bí kò ṣe ibi?”

19. Míkáyà sì tún wí pé, “Nítorí náà gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa: Mo rí Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ogun ọ̀run dúró ní apá ọ̀tún àti ní apá òsì rẹ̀.

20. Olúwa sì wí pé, ‘Ta ni yóò tan Áhábù láti kọlu Ramoti-Gílíádì? Kí ó sì tọ ikú rẹ̀ lọ níbẹ̀?’“Ẹnìkan wí báyìí, ẹlòmíràn sì sọ mìíràn.

21. Ẹ̀mí kan sì jáde wá, ó sì dúró níwájú Olúwa, ó sì wí pé, ‘Èmi yóò tàn án.’

22. “Olúwa sì béèrè pé, ‘Báwo?’ Ó sì wí pé,“ ‘Èmi yóò jáde lọ, èmi yóò sì di ẹ̀mí èké ní ẹnu gbogbo àwọn wòlíì rẹ̀.’“Olúwa sì wí pé, ‘Ìwọ yóò tàn án, ìwọ yóò sì borí, jáde lọ, kí o sì ṣe bẹ́ẹ̀.’

23. “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ti fi ẹ̀mí èké sí ẹnu gbogbo àwọn wòlíì rẹ wọ̀nyí. Olúwa sì ti sọ ibi sí ọ.”

24. Nígbà náà ni Ṣedekíàh ọmọ Kénáánà sì dìde, ó sì gbá Míkáyàh lójú, ó sì wí pé, “Ọ̀nà wo ni ẹ̀mí Olúwa gbà lọ kúrò lọ́dọ̀ mi láti bá ọ sọ̀rọ̀?”

25. Míkáyà sì wí pé, “Ìwọ yóò rí i ní ọjọ́ náà, nígbà tí ìwọ yóò lọ láti inú ìyẹ̀wù dé ìyẹ̀wù láti fi ara rẹ pamọ́.”

26. Ọba Ísírẹ́lì sì pàṣẹ pé, “Ẹ mú Míkáyà, kí ẹ sì mú un padà sọ́dọ̀ Ámónì, olórí ìlú, àti sọ́dọ̀ Jóásì ọmọ ọba

27. kí ẹ sì wí pé, ‘Báyìí ni ọba wí: Ẹ fi eléyìí sínú túbú, kí ẹ sì fi oúnjẹ ìpọ́njú àti omi ìpọ́njú bọ́ ọ, títí èmi yóò fi padà bọ̀ ní àlàáfíà.’ ”

28. Míkáyà sì wí pé, “Bí ìwọ bá padà bọ̀ ní àlàáfíà, Olúwa kò ti ipa mi sọ̀rọ̀.” Ó sì tún wí pé, “Ẹ kíyèsí ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin ènìyàn gbogbo!”

29. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì àti Jèhósáfátì ọba Júdà gòkè lọ sí Ramoti-Gílíádì.

30. Ọba Ísírẹ́lì sì wí fún Jèhósáfátì pé, “Èmi yóò pa aṣọ dà, èmi yóò sì lọ sí ojú ìjà, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wọ aṣọ ìgúnwà rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì pa aṣọ dà, ó sì lọ sí ojú ìjà.

31. Ọba Árámù ti pàṣẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ rẹ̀ méjìlélọ́gbọ̀n wí pé, “Ẹ má ṣe bá ẹnìkankan jà, ẹni kékeré tàbí ẹni ńlá, bí kò ṣe ọba Ísírẹ́lì nìkan.”

Ka pipe ipin 1 Ọba 22