Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 8:15-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Lẹhin eyinì li awọn ọmọ Lefi yio ma wọ̀ inu ile lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ: ki iwọ ki o si wẹ̀ wọn mọ́, ki o si mú wọn wá li ọrẹ fifì.

16. Nitoripe patapata li a fi wọn fun mi ninu awọn ọmọ Israeli; ni ipò gbogbo awọn ti o ṣí inu, ani gbogbo akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ni mo gbà wọn fun ara mi.

17. Nitoripe ti emi ni gbogbo akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ati ti enia ati ti ẹran: li ọjọ́ ti mo kọlù gbogbo akọ̀bi ni ilẹ Egipti ni mo ti yà wọn simimọ́ fun ara mi.

18. Emi si ti gbà awọn ọmọ Lefi dipò gbogbo akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli.

19. Emi si fi awọn ọmọ Lefi fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ li ọrẹ lati inu awọn ọmọ Israeli wá, lati ma ṣe iṣẹ-ìsin awọn ọmọ Israeli ninu agọ́ ajọ, ati lati ma ṣètutu fun awọn ọmọ Israeli: ki àrun má ba sí ninu awọn ọmọ Israeli, nigbati awọn ọmọ Israeli ba sunmọ ibi-mimọ́.

20. Bayi ni Mose, ati Aaroni, ati gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ṣe si awọn ọmọ Lefi: gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun Mose niti awọn ọmọ Lefi, bẹ̃li awọn ọmọ Israeli ṣe si wọn.

21. Awọn ọmọ Lefi si wẹ̀ ara wọn mọ́ kuro ninu ẹ̀ṣẹ, nwọn si fọ̀ aṣọ wọn; Aaroni si mú wọn wá li ọrẹ fifì siwaju OLUWA: Aaroni si ṣètutu fun wọn lati wẹ̀ wọn mọ́.

22. Lẹhin eyinì ni awọn ọmọ Lefi si wọle lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin ninu agọ́ ajọ niwaju Aaroni, ati niwaju awọn ọmọ rẹ̀: bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose niti awọn ọmọ Lefi, bẹ̃ni nwọn ṣe si wọn.

23. OLUWA si sọ fun Mose pe,

24. Eyi ni ti awọn ọmọ Lefi: lati ẹni ọdún mẹdọgbọ̀n lọ ati jù bẹ̃ lọ ni ki nwọn ki o ma wọle lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin ninu agọ́ ajọ.

25. Ati lati ẹni ãdọta ọdún ni ki nwọn ki o ṣiwọ iṣẹ-ìsin, ki nwọn ki o má si ṣe sìn mọ́;

26. Bikoṣepe ki nwọn ki o ma ṣe iranṣẹ pẹlu awọn arakunrin wọn ninu agọ́ ajọ, lati ma ṣe itọju, ki nwọn ki o má si ṣe iṣẹ-ìsin mọ́. Bayi ni ki iwọ ki o ṣe si awọn ọmọ Lefi niti itọju wọn.

Ka pipe ipin Num 8