Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 5:7-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Bi kò ba si le mú ọdọ-agutan wá, njẹ ki o mú àdaba meji tabi ọmọ ẹiyẹle meji wá fun ẹbọ ẹbi fun OLUWA nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ti o ti ṣẹ̀; ọkan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji fun ẹbọ sisun.

8. Ki o si mú wọn tọ̀ alufa wá, ẹniti yio tète rubọ eyiti iṣe ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ti yio si mi i li ọrùn, ṣugbọn ki yio pín i meji:

9. Ki o si fi ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ nì wọ́n ìha pẹpẹ; ati ẹ̀jẹ iyokù ni ki a ro si isalẹ pẹpẹ na: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni.

10. Ki o si ru ekeji li ẹbọ sisun, gẹgẹ bi ìlana na: ki alufa ki o si ṣètutu fun u, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀, a o si dari rẹ̀ jì i.

11. Ṣugbọn bi on kò ba le mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji wá, njẹ ki ẹniti o ṣẹ̀ na ki o mú idamẹwa òṣuwọn efa iyẹfun daradara wá fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; ki o máṣe fi oróro si i, bẹ̃ni ki o máṣe fi turari sori rẹ̀: nitoripe ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni.

12. Nigbana ni ki o mú u tọ̀ alufa wá, ki alufa ki o si bù ikunwọ rẹ̀ kan ninu rẹ̀, ani ẹbọ-iranti rẹ̀, ki o si sun u lori pẹpẹ na, gẹgẹ bi ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni.

13. Ki alufa ki o si ṣètutu fun u nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀ li ọkan ninu wọnyi, a o si dari rẹ̀ jì i: iyokù si jẹ́ ti alufa, bi ẹbọ ohunjijẹ.

14. OLUWA si sọ fun Mose pe,

15. Bi ẹnikan ba ṣìṣe, ti o ba si fi aimọ̀ ṣẹ̀ ninu ohun mimọ́ OLUWA; nigbana ni ki o múwa fun OLUWA nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀, àgbo kan alailabùku lati inu agbo-ẹran wá, ni idiyele rẹ nipa ṣekeli fadakà, gẹgẹ bi ṣekeli ibi mimọ́ fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ.

16. Ki o si ṣe atunṣe nitori ibi ti o ti ṣe ninu ohun mimọ́, ki o si fi idamarun pẹlu rẹ̀, ki o si fi i fun alufa: alufa yio si fi àgbo ẹbọ ẹ̀ṣẹ na ṣètutu fun u, a o si dari rẹ̀ jì i.

17. Bi ẹnikan ba si ṣẹ̀, ti o ba si ṣe ọkan ninu nkan wọnyi, eyiti ofin OLUWA kọ̀ lati ṣe; bi kò tilẹ mọ̀, ṣugbọn o jẹbi, yio si rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀.

18. Ki o si mú àgbo kan alailabùku lati inu agbo-ẹran tọ̀ alufa wá ni idiyele rẹ, fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: ki alufa ki o si ṣètutu fun u nitori aimọ̀ rẹ̀ ninu eyiti o ṣìṣe ti kò si mọ̀, a o si dari rẹ̀ jì i.

19. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni: nitõtọ li o dẹ̀ṣẹ si OLUWA.

Ka pipe ipin Lef 5