Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 2:7-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Awọn ọkunrin na lepa wọn li ọ̀na ti o lọ dé iwọ̀do Jordani: bi awọn ti nlepa wọn si ti jade lọ, nwọn tì ilẹkun ẹnubode.

8. Ki nwọn ki o tó dubulẹ, o gòke tọ̀ wọn lọ loke àja;

9. O si wi fun awọn ọkunrin na pe, Emi mọ̀ pe OLUWA ti fun nyin ni ilẹ yi, ati pe ẹ̀ru nyin bà ni, ati pe ọkàn gbogbo awọn ara ilẹ yi di omi nitori nyin.

10. Nitoripe awa ti gbọ́ bi OLUWA ti mu omi Okun Pupa gbẹ niwaju nyin, nigbati ẹnyin jade ni Egipti; ati ohun ti ẹnyin ṣe si awọn ọba meji ti awọn Amori, ti mbẹ ni ìha keji Jordani, Sihoni ati Ogu, ti ẹnyin parun tútu.

11. Lọgán bi awa ti gbọ́ nkan wọnyi, àiya wa já, bẹ̃ni kò si sí agbara kan ninu ọkunrin kan mọ́ nitori nyin; nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin, on li Ọlọrun loke ọrun, ati nisalẹ aiye.

12. Njẹ nitorina, emi bẹ̀ nyin, ẹ fi OLUWA bura fun mi, bi mo ti ṣe nyin li ore, ẹnyin o ṣe ore pẹlu fun ile baba mi, ẹnyin o si fun mi li àmi otitọ:

13. Ati pe ẹnyin o pa baba mi mọ́ lãye, ati iya mi, ati awọn arakunrin mi, ati awọn arabinrin mi, ati ohun gbogbo ti nwọn ní, ki ẹnyin si gbà ẹmi wa lọwọ ikú.

14. Awọn ọkunrin na da a lohùn pe, Ẹmi wa ni yio dipò ti nyin, bi ẹnyin kò ba fi ọ̀ran wa yi hàn; yio si ṣe, nigbati OLUWA ba fun wa ni ilẹ na, awa o ṣe ore ati otitọ fun ọ.

15. Nigbana li o fi okùn sọ̀ wọn kalẹ li oju-ferese: nitoriti ile rẹ̀ wà lara odi ilu, on a si ma gbé ori odi na.

16. O si wi fun wọn pe, Ẹ bọ sori òke, ki awọn alepa ki o má ba le nyin bá; ki ẹnyin si fara nyin pamọ́ nibẹ̀ ni ijọ́ mẹta, titi awọn alepa yio fi pada: lẹhin na ẹ ma ba ọ̀na ti nyin lọ.

17. Awọn ọkunrin na wi fun u pe, Ara wa o dá niti ibura rẹ yi, ti iwọ mu wa bú.

18. Kiyesi i, nigbati awa ba dé inu ilẹ na, iwọ o so okùn owú ododó yi si oju-ferese ti iwọ fi sọ̀ wa kalẹ: iwọ o si mú baba rẹ, ati iya rẹ, ati awọn arakunrin rẹ, ati gbogbo ara ile baba rẹ, wá ile sọdọ rẹ.

19. Yio si ṣe, ẹnikẹni ti o ba jade lati inu ilẹkun ile rẹ lọ si ode, ẹ̀jẹ rẹ̀ yio wà li ori ara rẹ̀, awa o si wà li aijẹbi: ati ẹnikẹni ti o ba wà pẹlu rẹ ni ile, ẹ̀jẹ rẹ̀ yio wà li ori wa, bi ẹnikẹni ba fọwọkàn a.

20. Bi o ba si sọ ọ̀ran wa yi, nigbana ni ara wa o dá niti ibura rẹ ti iwọ mu wa bú yi.

21. O si wipe, Gẹgẹ bi ọ̀rọ nyin, bẹ̃ni ki o ri. O si rán wọn lọ, nwọn si lọ: o si so okùn ododó na si oju-ferese.

Ka pipe ipin Joṣ 2