Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 44:1-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá fun gbogbo awọn ara Juda ti ngbe ilẹ Egipti, ti ngbe Migdoli, ati Tafanesi, ati Nofu, ati ilẹ Patrosi, wipe,

2. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, ẹnyin ti ri gbogbo ibi ti emi ti mu wá sori Jerusalemu, ati sori gbogbo ilu Juda; si wò o, ahoro ni nwọn li oni yi, ẹnikan kò si gbe inu wọn.

3. Nitori ìwa-buburu wọn ti nwọn ti hú lati mu mi binu, ni lilọ lati sun turari ati lati sìn awọn ọlọrun miran, ti nwọn kò mọ̀, awọn, tabi ẹnyin, tabi awọn baba nyin.

4. Emi si ran gbogbo awọn iranṣẹ mi, awọn woli si nyin, emi dide ni kutukutu, mo rán wọn, wipe, A! ẹ máṣe ohun irira yi ti emi korira.

5. Ṣugbọn nwọn kò gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò tẹti wọn silẹ lati yipada kuro ninu ìwa-buburu wọn, ki nwọn ki o má sun turari fun ọlọrun miran.

6. Nitorina ni mo ṣe dà ìrunu mi ati ibinu mi jade, a si daná rẹ̀ ni ilu Juda, ati ni ita Jerusalemu: nwọn si di ofo ati ahoro, gẹgẹ bi ti oni yi.

7. Njẹ nisisiyi, bayi li Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi pe, nitori kini ẹ ṣe da ẹ̀ṣẹ nla yi si ọkàn nyin, lati ke ninu nyin ani ọkunrin ati obinrin, ati ọmọde ati ọmọ-ọmu, kuro lãrin Juda, lati má kù iyokú fun nyin;

8. Ninu eyiti ẹnyin fi iṣẹ ọwọ nyin mu mi binu, ni sisun turari fun ọlọrun miran ni ilẹ Egipti, nibiti ẹnyin lọ lati ṣatipo, ki ẹ le ke ara nyin kuro, ati ki ẹ le jẹ ẹni-ègun ati ẹsin, lãrin gbogbo orilẹ-ède ilẹ aiye?

9. Ẹnyin ha ti gbagbe ìwa-buburu awọn baba nyin, ati ìwa-buburu awọn ọba Juda, ati ìwa-buburu awọn aya wọn, ati ìwa-buburu ẹnyin tikara nyin, ati ìwa-buburu awọn aya nyin, ti nwọn ti hù ni ilẹ Juda, ati ni ita Jerusalemu.

10. Nwọn kò rẹ̀ ara wọn silẹ titi di oni yi, bẹ̃ni wọn kò bẹ̀ru, tabi ki nwọn ki o rìn ninu ofin mi, tabi ninu ilana mi ti emi gbe kalẹ niwaju nyin ati niwaju awọn baba nyin.

11. Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi pe, wò o emi doju mi kọ nyin fun ibi, ati lati ke gbogbo Juda kuro.

12. Emi o si mu gbogbo iyokù Juda, ti o ti gbe oju wọn si ati lọ si ilẹ Egipti, lati ṣatipo nibẹ, gbogbo wọn ni yio si run, nwọn o si ṣubu ni ilẹ Egipti; nwọn o si run nipa idà ati nipa ìyan, nwọn o kú lati ẹni-kekere wọn titi de ẹni-nla wọn, nipa idà, ati nipa ìyan: nwọn o si di ẹni-ègun, ẹni-iyanu, ati ẹni-ẹ̀gan, ati ẹsin.

13. Nitori emi o bẹ̀ awọn ti ngbe Egipti wò, gẹgẹ bi emi ti jẹ Jerusalemu niya, nipa idà, nipa ìyan, ati nipa àjakalẹ-arun;

14. Kì o si si ẹniti o sala, ati ẹniti o kù, fun awọn iyokù Juda, ti o wọ ilẹ Egipti lati ma ṣatipo nibẹ, ti yio pada si ilẹ Juda, si eyiti nwọn ni ifẹ ati pada lọ igbe ibẹ: nitori kò si ọkan ti yio pada bikoṣe iru awọn ti o sala.

15. Nigbana ni gbogbo awọn ọkunrin ti nwọn mọ̀ daju pe, awọn aya wọn ti sun turari fun ọlọrun miran, ati gbogbo awọn obinrin ti o duro nibẹ, apejọ nla, ati gbogbo awọn enia ti ngbe ilẹ Egipti ani ni Patrosi, da Jeremiah lohùn, wipe,

Ka pipe ipin Jer 44