Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 23:11-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Awọn agba ilu Keila yio fi mi le e lọwọ bi? Saulu yio ha sọkalẹ, gẹgẹ bi iranṣẹ rẹ ti gbọ́ bi? Oluwa Ọlọrun Israeli, emi bẹ̀ ọ, wi fun iranṣẹ rẹ. Oluwa si wipe, Yio sọkalẹ wá.

12. Dafidi si wipe, Awọn agbà ilu Keila yio fi emi ati awọn ọmọkunrin mi le Saulu lọwọ bi? Oluwa si wipe, Nwọn o fi ọ le wọn lọwọ.

13. Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ ti wọn to ẹgbẹta enia si dide, nwọn lọ kuro ni Keila, nwọn si lọ si ibikibi ti nwọn le lọ. A si wi fun Saulu pe, Dafidi ti sa kuro ni Keila; ko si lọ si Keila mọ.

14. Dafidi si ngbe ni aginju, nibiti o ti sa pamọ si, o si ngbe nibi oke-nla kan li aginju Sifi. Saulu si nwá a lojojumọ, ṣugbọn Ọlọrun ko fi le e lọwọ.

15. Dafidi si ri pe, Saulu ti jade lati wá ẹmi on kiri: Dafidi si wà li aginju Sifi ninu igbo kan.

16. Jonatani ọmọ Saulu si dide, o si tọ Dafidi lọ ninu igbo na, o si gba a ni iyanju nipa ti Ọlọrun.

17. On si wi fun u pe, Máṣe bẹru: nitori ọwọ́ Saulu baba mi kì yio tẹ̀ ọ: iwọ ni yio jọba lori Israeli, emi ni yio si ṣe ibikeji rẹ; Saulu baba mi mọ̀ bẹ̃ pẹlu.

18. Awọn mejeji si ṣe adehun niwaju Oluwa; Dafidi si joko ninu igbo na. Jonatani si lọ si ile rẹ̀.

19. Awọn ara Sifi si goke tọ Saulu wá si Gibea, nwọn si wipe, Ṣe Dafidi ti fi ara rẹ̀ pamọ sọdọ wa ni ibi ti o to sa pamọ si ni igbo, ni oke Hakila, ti o wà niha gusu ti Jeṣimoni?

20. Njẹ nisisiyi, Ọba, sọkalẹ wá gẹgẹ bi gbogbo ifẹ ti o wà li ọkàn rẹ lati sọkalẹ; ipa ti awa ni lati fi i le ọba lọwọ.

21. Saulu si wipe, Alabukun fun li ẹnyin nipa ti Oluwa; nitoripe ẹnyin ti kãnu fun mi.

22. Lọ, emi bẹ̀ nyin, ẹ tun mura, ki ẹ si mọ̀, ki ẹ si ri ibi ti ẹsẹ rẹ̀ gbe wà, ati ẹniti o ri i nibẹ: nitoriti ati sọ fun mi pe, ọgbọ́n li o nlò jọjọ.

23. Ẹ si wò, ki ẹ si mọ̀ ibi isapamọ ti ima sapamọ si, ki ẹ si tun pada tọ mi wá, nitori ki emi ki o le mọ̀ daju; emi o si ba nyin lọ: yio si ṣe, bi o ba wà ni ilẹ Israeli, emi o si wá a li awari ninu gbogbo ẹgbẹrun Juda.

24. Nwọn si dide, nwọn si ṣaju Saulu lọ si Sifi: ṣugbọn Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ wà li aginju Maoni, ni pẹtẹlẹ niha gusu ti Jeṣimoni.

25. Saulu ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si lọ iwá a. Nwọn si sọ fun Dafidi: o si sọkalẹ wá si ibi okuta kan, o si joko li aginju ti Maoni. Saulu si gbọ́, o si lepa Dafidi li aginju Maoni.

26. Saulu si nrin li apakan oke kan, Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ li apa keji oke na: Dafidi si yara lati sa kuro niwaju Saulu; nitoripe Saulu ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ ti rọ̀gba yi Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ ka lati mu wọn.

27. Ṣugbọn onṣẹ kan si tọ Saulu wá, o si wipe, iwọ yara ki o si wá, nitoriti awọn Filistini ti gbe ogun tì ilẹ wa.

28. Saulu si pada kuro ni lilepa Dafidi, o si lọ ipade awọn Filistini: nitorina ni nwọn si se npe ibẹ̀ na ni Selahammalekoti. (ni itumọ rẹ̀, okuta ipinyà.)

29. Dafidi ti goke lati ibẹ lọ, o si joko nibi ti o sapamọ si ni Engedi.

Ka pipe ipin 1. Sam 23