Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 14:6-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Jonatani wi fun ọdọmọdekunrin ti o rù ihamọra rẹ̀ pe, Wá, si jẹ ki a lọ si budo-ogun awọn alaikọla yi: bọya Oluwa yio ṣiṣẹ fun wa: nitoripe kò si idiwọ fun Oluwa lati fi pipọ tabi diẹ gba là.

7. Ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ na wi fun u pe, Ṣe gbogbo eyi ti o mbẹ li ọkàn rẹ: ṣe bi o ti tọ́ li ọkàn rẹ; wõ, emi wà pẹlu rẹ gẹgẹ bi ti ọkàn rẹ.

8. Jonatani si wi pe, Kiye si i, awa o rekọja sọdọ awọn ọkunrin wọnyi, a o si fi ara wa hàn fun wọn.

9. Bi nwọn ba wi fun wa pe, Ẹ duro titi awa o fi tọ̀ nyin wá; awa o si duro, awa kì yio si goke tọ̀ wọn lọ.

10. Ṣugbọn bi nwọn ba wi pe, Goke tọ̀ wa wá; a o si goke lọ: nitori pe Oluwa ti fi wọn le wa lọwọ́; eyi ni o si jẹ àmi fun wa.

11. Awọn mejeji fi ara wọn hàn fun ogun Filistini: awọn Filistini si wipe, Wõ, awọn Heberu ti inu iho wọn jade wá, nibiti nwọn ti fi ara pamọ si.

12. Awọn ọkunrin ile olodi na si da Jonatani ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ lohùn, nwọn si wipe, Goke tọ̀ wa wá, awa o si fi nkan hàn nyin; Jonatani si wi fun ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ pe, Ma tọ̀ mi lẹhìn; nitoripe Oluwa ti fi wọn le awọn enia Israeli lọwọ.

13. Jonatani rakò goke, ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ lẹhin rẹ̀; awọn Filistini si subu niwaju Jonatani; ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ npa lẹhin rẹ̀.

14. Pipa ikini, eyi ti Jonatani ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ ṣe, o jasi iwọn ogún ọkunrin ninu abọ iṣẹko kan ti malu meji iba tú.

15. Ibẹ̀ru si wà ninu ogun na, ni pápá, ati ninu gbogbo awọn enia na; ile ọmọ-ogun olodi, ati awọn ti iko ikogun, awọn pẹlu bẹ̀ru; ilẹ sì mi: bẹ̃li o si jasi ọwáriri nlanla.

16. Awọn ọkunrin ti nṣọ́na fun Saulu ni Gibea ti Benjamini wò; nwọn si ri ọpọlọpọ awọn enia na tuka, nwọn si npa ara wọn bi nwọn ti nlọ.

17. Saulu si wi fun awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ pe, Njẹ ẹ kà awọn enia na ki ẹ si mọ̀ ẹniti o jade kuro ninu wa. Nwọn si kà, si kiye si i, Jonatani ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ kò si si.

18. Saulu si wi fun Ahia pe, Gbe apoti Ọlọrun na wá nihinyi. Nitoripe apoti Ọlọrun wà lọdọ awọn ọmọ Israeli li akokò na.

19. O si ṣe, bi Saulu ti mba alufa na sọ̀rọ, ariwo ti o wà ni budo awọn Filistini si npọ̀ si i: Saulu si wi fun alufa na pe, dawọ́ duro.

20. Saulu ati gbogbo enia ti o wà lọdọ rẹ̀ ko ara wọn jọ pọ̀, nwọn wá si oju ija: kiye si i, ida olukuluku si wà li ara ọmọnikeji rẹ̀, rudurudu na si pọ̀ gidigidi.

Ka pipe ipin 1. Sam 14