Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 14:26-39 Yorùbá Bibeli (YCE)

26. Nigbati awọn enia si wọ inu igbo na, si kiye si i oyin na nkán; ṣugbọn kò si ẹnikan ti o mu ọwọ́ rẹ̀ re ẹnu rẹ̀: nitoripe awọn enia bẹ̀ru ifibu na.

27. Ṣugbọn Jonatani kò gbọ́ nigbati baba rẹ̀ fi ifibu kilọ fun awọn enia na: o si tẹ ori ọpa ti mbẹ lọwọ rẹ̀ bọ afara oyin na, o si fi i si ẹnu rẹ̀, oju rẹ̀ mejeji si walẹ.

28. Nigbana li ọkan ninu awọn enia na dahùn wipe, baba rẹ ti fi ifibu kilọ fun awọn enia na, pe, ifibu li ọkunrin na ti o jẹ onjẹ li oni. Arẹ̀ si mu awọn enia na.

29. Nigbana ni Jonatani wipe, baba mi yọ ilu li ẹnu, sa wo bi oju mi ti walẹ, nitori ti emi tọ diẹ wò ninu oyin yi.

30. A! nitotọ, ibaṣepe awọn enia na ti jẹ ninu ikogun awọn ọta wọn ti nwọn ri, pipa awọn Filistini iba ti pọ to?

31. Nwọn pa ninu awọn Filistini li ọjọ na, lati Mikmaṣi de Aijaloni: o si rẹ̀ awọn enia na gidigidi.

32. Awọn enia sare si ikogun na, nwọn si mu agutan, ati malu, ati ọmọ-malu, nwọn si pa wọn sori ilẹ: awọn enia na si jẹ wọn t'ẹjẹ t'ẹjẹ.

33. Nigbana ni nwọn wi fun Saulu pe, kiye si i, awọn enia na dẹ̀ṣẹ si Oluwa, li eyi ti nwọn jẹ ẹjẹ. On si wipe, Ẹnyin ṣẹ̀ kọja: yi okuta nla fun mi wá loni.

34. Saulu si wipe, Ẹ tu ara nyin ka sarin awọn enia na ki ẹ si wi fun wọn pe, Ki olukuluku ọkunrin mu malu tirẹ̀ tọ̀ mi wá, ati olukuluku ọkunrin agutan rẹ̀, ki ẹ si pa wọn nihin, ki ẹ si jẹ, ki ẹ má si ṣẹ̀ si Oluwa, ni jijẹ ẹjẹ. Gbogbo enia olukuluku ọkunrin mu malu rẹ̀ wá li alẹ na, nwọn si pa wọn ni ibẹ̀.

35. Saulu si tẹ pẹpẹ kan fun Oluwa; eyi ni pẹpẹ ti o kọ ṣe fun Oluwa.

36. Saulu wipe, Ẹ jẹ ki a sọkalẹ tọ̀ awọn Filistini lọ li oru, ki a ba wọn ja titi di imọlẹ owurọ̀, ẹ má jẹ ki a fi ọkunrin kan silẹ ninu wọn. Nwọn si wipe, Ṣe gbogbo eyi ti o tọ loju rẹ. Nigbana ni alufa ni si wipe, Ẹ jẹ ki a sunmọ ihinyi si Ọlọrun.

37. Saulu si bere lọdọ Ọlọrun pe, ki emi ki o sọkalẹ tọ̀ awọn Filistini lọ bi? Iwọ o fi wọn lé Israeli lọwọ́ bi? ṣugbọn kò da a lohùn li ọjọ na.

38. Saulu si wipe Mu gbogbo awọn àgba enia sunmọ ihinyi, ki ẹ mọ̀, ki ẹ si ri ibiti ẹ̀ṣẹ yi wà loni.

39. Nitoripe gẹgẹ bi Oluwa ti wà ti o ti gbà Israeli là bi o tilẹ ṣepe a ri i lara Jonatani ọmọ mi, nitõtọ yio kú. Ṣugbọn ninu gbogbo enia na, kò si ẹniti o da a lohùn.

Ka pipe ipin 1. Sam 14