orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esr 9 Yorùbá Bibeli (YCE)

Ẹsra gbọ́ pé Àwọn Ọmọ Israẹli ń fẹ́ Àwọn Ọmọbinrin tí wọn kì í ṣe Juu

1. NIGBATI a si ti ṣe nkan wọnyi tan, awọn ijoye wá si ọdọ mi, wipe, Awọn enia Israeli, ati awọn alufa, pẹlu awọn ọmọ Lefi kò ya ara wọn si ọ̀tọ kuro ninu awọn enia ilẹ wọnni, gẹgẹ bi irira wọn, ti awọn ara Kenaani, awọn ara Hitti, awọn ara Perisi, awọn ara Jebusi, awọn ara Ammoni, awọn ara Moabu, awọn ara Egipti, ati ti awọn ara Amori.

2. Nitoripe nwọn mu awọn ọmọ wọn obinrin fun aya wọn, ati fun awọn ọmọ wọn ọkunrin: tobẹ̃ ti a da iru-ọmọ mimọ́ pọ̀ mọ awọn enia ilẹ wọnni: ọwọ awọn ijoye, ati awọn olori si ni pataki ninu irekọja yi.

3. Nigbati mo si gbọ́ nkan wọnyi, mo fa aṣọ mi ati agbáda mi ya, mo si fà irun ori mi ati ti àgbọn mi tu kuro, mo si joko ni ijaya.

4. Nigbana ni olukuluku awọn ti o warìri si ọ̀rọ Ọlọrun Israeli ko ara wọn jọ si ọdọ mi, nitori irekọja awọn wọnni ti a ti ko lọ; mo si joko ni ijaya titi di igba ẹbọ aṣalẹ.

5. Ni igba ẹbọ aṣalẹ ni mo si dide kuro ninu ikãnu mi; pẹlu aṣọ ati agbáda mi yiya, mo si wolẹ lori ẽkun mi, mo si nà ọwọ mi si Oluwa Ọlọrun mi.

6. Mo si wipe, Ọlọrun mi, oju tì mi, iṣãju si ṣe mi lati gbe oju mi soke si ọdọ rẹ, Ọlọrun mi, nitoriti ẹ̀ṣẹ wa di pupọ li ori wa, ẹbi wa si tobi titi de awọn ọrun.

7. Lati ọjọ awọn baba wa li awa ti wà ninu ẹbi nla titi di oni; ati nitori ẹ̀ṣẹ wa li a fi awa, awọn ọba wa, ati awọn alufa wa, le awọn ọba ilẹ wọnni lọwọ fun idà, fun igbèkun, ati fun ikogun, ati fun idamu oju, gẹgẹ bi o ti ri li oni oloni.

8. Njẹ nisisiyi fun igba diẹ, li a si fi ore-ọfẹ fun wa lati ọdọ Oluwa Ọlọrun wa wá lati salà, ati lati fi ẽkàn fun wa ni ibi mimọ́ rẹ̀, ki Ọlọrun wa ki o le mu oju wa mọlẹ, ki o si tun wa gbe dide diẹ ninu oko-ẹrú wa.

9. Nitoripe ẹrú li awa iṣe; ṣugbọn Ọlọrun wa kò kọ̀ wa silẹ li oko ẹrú wa, ṣugbọn o ti nawọ́ ãnu rẹ̀ si wa li oju awọn ọba Persia, lati tun mu wa yè, lati gbe ile Ọlọrun wa duro, ati lati tun ahoro rẹ̀ ṣe, ati lati fi odi kan fun wa ni Juda, ati ni Jerusalemu.

10. Njẹ nisisiyi, Ọlọrun wa, kili awa o wi lẹhin eyi? nitoriti awa ti kọ̀ aṣẹ rẹ silẹ,

11. Ti iwọ ti pa lati ẹnu awọn woli iranṣẹ rẹ wá, wipe, Ilẹ na ti ẹnyin nlọ igbà nì, ilẹ alaimọ́ ni, fun ẹgbin awọn enia ilẹ na, fun irira wọn, pẹlu ìwa-ẽri ti nwọn fi kun lati ikangun kan de ekeji.

12. Njẹ nitorina ki ẹnyin ki o máṣe fi ọmọ nyin obinrin fun ọmọ wọn ọkunrin, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe mu ọmọ wọn obinrin fun ọmọ nyin ọkunrin, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe wá alafia wọn tabi irọra wọn titi lai: ki ẹnyin ki o le ni agbara, ki ẹ si le ma jẹ ire ilẹ na, ki ẹ si le fi i silẹ fun awọn ọmọ nyin ni ini titi lai.

13. Ati lẹhin gbogbo eyi ti o de si wa nitori iṣe buburu wa, ati nitori ẹbi wa nla, nitoripe iwọ Ọlọrun wa ti dá wa si ju bi o ti yẹ lọ fun aiṣedede wa, o si fi iru igbala bi eyi fun wa;

14. Awa iba ha tun ru ofin rẹ? ki awa ki o si ma ba awọn enia irira wọnyi dá ana? iwọ kì o ha binu si wa titi iwọ o fi pa wa run tan, tobẹ̃ ti ẹnikan kò si ni kù, tabi ẹnikan ti o sala?

15. Olododo ni iwọ Oluwa Ọlọrun Israeli: awa ni iyokù ati asala gẹgẹ bi o ti ri li oni yi: wò o, awa duro niwaju rẹ ninu ẹbi wa, nitoripe awa ki o le duro niwaju rẹ nitori eyi.