Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 43:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si mu mi wá si ẹnu-ọ̀na, ẹnu-ọ̀na ti o kọjusi ọ̀na ila-õrun:

2. Si kiyesi i, ogo Ọlọrun Israeli wá lati ọ̀na ila-õrun: ati ohùn rẹ̀ ri bi ariwo omi pupọ̀: aiye si ràn fun ogo rẹ̀.

3. O si dabi irí iran ti mo ri, gẹgẹ bi iran ti mo ri nigbati mo wá lati pa ilu na run: iran na si dabi iran ti mo ri lẹba odò Kebari, mo si doju mi bolẹ.

4. Ogo Oluwa si wá si ile na lati ọ̀na ilẹkùn ti o kọjusi ọ̀na ila-õrun.

5. Ẹmi si gbe mi soke, o si mu mi wá si àgbala tinu: si kiye si i, ogo Oluwa kún ile na.

6. Mo si gbọ́ o mba mi sọ̀rọ lati inu ile wá; ọkunrin na si duro tì mi.

7. O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, ibi itẹ mi, ati ibi atẹlẹṣẹ mi, nibiti emi o gbe lãrin awọn ọmọ Israeli lailai, ati orukọ mimọ́ mi, ni ki ile Israeli má bajẹ mọ, awọn, tabi ọba wọn, nipa panṣaga wọn, tabi nipa okú ọba wọn ni ibi giga wọn.

8. Ni titẹ́ iloro wọn nibi iloro mi, ati opó wọn nibi opó mi, ogiri si wà lãrin emi ati awọn, nwọn si ti ba orukọ mimọ́ mi jẹ nipa ohun irira wọn ti nwọn ti ṣe: mo si run wọn ni ibinu mi.

9. Njẹ ki nwọn mu panṣaga wọn, ati okú awọn ọba wọn jina kuro lọdọ mi, emi o si ma gbe ãrin wọn lailai.

10. Iwọ ọmọ enia, fi ile na hàn ile Israeli, ki oju aiṣedede wọn ba le tì wọn: si jẹ ki nwọn wọ̀n apẹrẹ na.

11. Bi oju gbogbo ohun ti nwọn ba ṣe ba si tì wọn, fi irí ile na hàn wọn, ati kikọ́ rẹ̀, ati ijade rẹ̀, ati iwọle rẹ̀, ati gbogbo irí rẹ̀, ati gbogbo aṣẹ rẹ̀, ati gbogbo irí rẹ̀, ati gbogbo ofin rẹ̀; ki o si kọ ọ loju wọn, ki nwọn ki o lè pa gbogbo irí rẹ̀ mọ, ati gbogbo aṣẹ rẹ̀, ki nwọn si ṣe wọn.

12. Eyi ni ofin ile na; Lori oke giga, gbogbo ipinnu rẹ̀ yika ni mimọ́ julọ. Kiyesi i, eyi ni ofin ile na.

Ka pipe ipin Esek 43