Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dan 8:15-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. O si ṣe ti emi, ani emi Danieli si ti ri iran na, ti mo si nfẹ imọ̀ idi rẹ̀, si kiyesi i, ẹnikan duro niwaju mi, gẹgẹ bi aworan ọkunrin.

16. Emi si gbọ́ ohùn enia kan lãrin odò Ulai, ti o pè, ti o si wi pe, Gabrieli, mu ki eleyi moye iran na.

17. Bẹ̃li o si wá sibi ti mo duro: nigbati o si de, ẹ̀ru bà mi, mo si da oju mi bolẹ: ṣugbọn o wi fun mi pe, Kiyesi i, ọmọ enia: nitoripe ti akokò igba ikẹhin ni iran na iṣe.

18. Njẹ bi o ti mba mi sọ̀rọ, mo dãmu, mo si doju bolẹ: ṣugbọn o fi ọwọ kàn mi, o si gbé mi dide duro si ipò mi.

19. O si wipe, kiyesi i, emi o mu ọ mọ̀ ohun ti yio ṣe ni igba ikẹhin ibinu na: nitoripe, akokò igba ikẹhin ni eyi iṣe.

20. Agbò na ti iwọ ri ti o ni iwo meji nì, awọn ọba Media ati Persia ni nwọn.

21. Obukọ onirun nì li ọba Hellene: iwo nla ti o wà lãrin oju rẹ̀ mejeji li ọba ekini.

22. Njẹ bi eyini si ti ṣẹ́, ti iwo mẹrin miran si dide duro nipò rẹ̀, ijọba mẹrin ni yio dide ninu orilẹ-ède na, ṣugbọn kì yio ṣe ninu agbara rẹ̀.

23. Li akokò ikẹhin ijọba wọn, nigbati awọn oluṣe irekọja ba de ni kíkun, li ọba kan yio dide, ti oju rẹ̀ buru, ti o si moye ọ̀rọ arekereke.

24. Agbara rẹ̀ yio si le gidigidi, ṣugbọn kì iṣe agbara ti on tikararẹ̀: on o si ma ṣe iparun ti o yani lẹnu, yio si ma ri rere ninu iṣẹ, yio si pa awọn alagbara ati awọn enia ẹni-mimọ́ run.

25. Ati nipa arekereke rẹ̀ yio si mu ki iṣẹ ẹ̀tan ṣe dẽde lọwọ rẹ̀; on o si gbé ara rẹ̀ ga li ọkàn rẹ̀, lojiji ni yio si pa ọ̀pọlọpọ run, yio dide si olori awọn ọmọ-alade nì; ṣugbọn on o ṣẹ́ laisi ọwọ.

26. Ati iran ti alẹ ati ti owurọ ti a ti sọ, otitọ ni; sibẹ, iwọ sé iran na mọ, nitoripe fun ọjọ pipọ ni.

27. Arẹ̀ si mu emi Danieli, ara mi si ṣe alaida niwọn ọjọ melokan; lẹhin na, mo dide, mo si nṣe iṣẹ ọba; ẹ̀ru si bà mi, nitori iran na, ṣugbọn kò si ẹni ti o fi ye mi.

Ka pipe ipin Dan 8